JOHANU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìyìn Rere Johanu fi Jesu hàn gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ ayérayé Ọlọrun tí “ó di eniyan tí ó sì ń gbé ààrin wa.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà alára ti wí, ìdí tí a fi kọ ọ́ ni pé kí àwọn tí wọ́n bá kà á lè gbàgbọ́ pé Jesu ni Olùgbàlà tí Ọlọrun ṣe ìlérí, òun sì ni Ọmọ Ọlọrun; ati pé kí wọ́n lè ní ìyè nípasẹ̀ gbigbagbọ tí wọ́n bá gbà á gbọ́.
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ iṣaaju tí ó fihàn pé Jesu ni ọ̀rọ̀ ayérayé Ọlọrun, apá kinni ìyìn rere náà sọ nípa àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìyanu tí ó fihàn pé Jesu ni Olùgbàlà tí Ọlọrun ṣe ìlérí, òun ni Ọmọ Ọlọrun. Lẹ́yìn èyí, ẹni tí ó kọ ìwé náà ṣe àkójọ àwọn àlàyé tí ó ṣe nípa ohun tí àwọn iṣẹ́ ìyanu dúró fún. Ninu apá tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni ó ti sọ nípa àwọn mélòó kan tí wọ́n gba Jesu gbọ́ tí wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn mìíràn takò ó, wọ́n kọ̀, wọn kò gbà á gbọ́. Orí 13 dé 17 sọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa bí Jesu ti fara mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tímọ́tímọ́ ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú un. Ó tún sọ nípa ọ̀rọ̀ ìpalẹ̀mọ́ ati ìmúnilọ́kànle tí Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí ó kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ kí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu. Orí bíi mélòó kan tí ó parí ìwé náà sọ nípa bí wọ́n ṣe mú Jesu, tí wọ́n wá ẹ̀sùn sí i lẹ́sẹ̀, tí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu ati bí ó ṣe jinde. Ó tún sọ nípa bí ó ṣe fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ajinde rẹ̀.
Inú àmì àkámọ́ (brackets), ni wọ́n kọ ìtàn obinrin tí wọ́n mú níbi tí ó ti ń ṣe àgbèrè sí (8:1-11). Ìdí ni pé kò sí ìtàn yìí ninu ọpọlọpọ Bibeli àtijọ́. Ninu àwọn mìíràn tí ó sì wà, ọ̀tọ̀ ni ibi tí wọ́n kọ ọ́ sí.
Johanu tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀bùn ìyè ainipẹkun ninu Kristi. Láti ìsinsìnyìí lọ ni ẹ̀bùn tí àwọn tí wọ́n bá gba Jesu bí ọ̀nà, òtítọ́ ati ìyè yóo rí gbà ti bẹ̀rẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ohun tí ó gúnni lọ́kàn ninu ìwé Johanu ni bí ó ṣe ń mú àwọn nǹkan yẹpẹrẹ inú ìgbé-ayé wa ojoojumọ, tí ó sì ń lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe pataki láti tọ́ka sí àwọn nǹkan ti ẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ kókó; fún bíi àpẹẹrẹ: omi, oúnjẹ, ìmọ́lẹ̀, olùṣọ́ aguntan ati àwọn aguntan rẹ̀, ati igi àjàrà pẹlu èso rẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ 1:1-18
Johanu Onítẹ̀bọmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kinni 1:19-51
Àwọn iṣẹ́ tí Jesu ṣe ní gbangba 2:1–12:50
Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ní Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀ 13:1–19:42
Ajinde ati ìfarahàn Oluwa 20:1-31
Ọ̀rọ̀ ìparí: ìfarahàn mìíràn ní Galili 21:1-25
Voafantina amin'izao fotoana izao:
JOHANU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE
Asongadina
Hizara
Dika mitovy
Tianao hovoatahiry amin'ireo fitaovana ampiasainao rehetra ve ireo nasongadina? Hisoratra na Hiditra
Bible Society of Nigeria © 1900/2010