Logo ya YouVersion
Elilingi ya Boluki

JẸNẸSISI 9

9
Ọlọrun Bá Noa Dá Majẹmu
1Ọlọrun súre fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.#Jẹn 1:28. 2Gbogbo ẹranko tí ó wà láyé, gbogbo ẹyẹ, gbogbo ẹja tí ń bẹ ninu omi, ati gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri ni yóo máa bẹ̀rù yín, ìkáwọ́ yín ni mo fi gbogbo wọn sí. 3Gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ni yóo jẹ́ oúnjẹ fún yín, bí mo ti fún yín ní gbogbo ewéko, bẹ́ẹ̀ náà ni mo fún yín ní ohun gbogbo. 4Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ti òun ti ẹ̀jẹ̀, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ìyè wà.#Lef 7:26-27; 17:10-14; 19:26; Diut 12:16, 23; 15:23. 5Dájúdájú n óo gbẹ̀san lára ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, kì báà jẹ́ ẹranko ni ó paniyan tabi eniyan ni ó pa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀. 6Ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, pípa ni a óo pa òun náà, nítorí pé ní àwòrán Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó dá eniyan.#Eks 20:13; Jẹn 1:26.
7“Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.”#Jẹn 1:28.
8Lẹ́yìn náà Ọlọrun sọ fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, 9“Wò ó! Mo bá ẹ̀yin ati atọmọdọmọ yín dá majẹmu, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà pẹlu yín: 10Gbogbo àwọn ẹyẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko tí wọ́n bá yín jáde ninu ọkọ̀, 11majẹmu náà ni pé, lae, n kò tún ní fi ìkún omi pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìkún omi tí yóo pa ayé rẹ́ mọ́. 12Ohun tí yóo jẹ́ àmì majẹmu tí mo ń bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá, tí yóo sì wà fún atọmọdọmọ yín ní ọjọ́ iwájú nìyí: 13mo fi òṣùmàrè mi sí ojú ọ̀run, òun ni yóo máa jẹ́ àmì majẹmu tí mo bá ayé dá. 14Nígbàkúùgbà tí mo bá mú kí òjò ṣú ní ojú ọ̀run, tí òṣùmàrè bá sì yọ jáde, 15n óo ranti majẹmu tí mo bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá pé, omi kò ní kún débi pé yóo pa ayé rẹ́ mọ́. 16Nígbà tí òṣùmàrè bá yọ, n óo wò ó, n óo sì ranti majẹmu ayérayé tí èmi Ọlọrun bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá. 17Èyí ni majẹmu tí mo bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.”
Noa ati Àwọn Ọmọkunrin Rẹ̀
18Àwọn ọmọ Noa tí wọ́n jáde ninu ọkọ̀ ni: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Hamu ni ó bí Kenaani. 19Àwọn ọmọ Noa mẹtẹẹta yìí ni baba ńlá gbogbo ayé.
20Noa ni ẹni kinni tí ó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, tí ó gbin ọgbà àjàrà. 21Noa mu àmupara ninu ọtí waini ọgbà rẹ̀, ó sì sùn sinu àgọ́ rẹ̀ ní ìhòòhò. 22Hamu, baba Kenaani, rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò, ó lọ sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ mejeeji lóde. 23Ṣemu ati Jafẹti bá mú aṣọ kan, wọ́n fà á kọ́ èjìká wọn, wọ́n fi ẹ̀yìn rìn lọ sí ibi tí baba wọn sùn sí, wọ́n sì dà á bò ó, wọ́n kọ ojú sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn. 24Nígbà tí ọtí dá lójú Noa, tí ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i, 25Ó ní,
“Ẹni ègún ni Kenaani,
ẹrú lásánlàsàn ni yóo jẹ́ fún àwọn arakunrin rẹ̀.”
26Ó tún fi kún un pé,
“Kí OLUWA Ọlọrun mi bukun Ṣemu,
ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.
27Kí Ọlọrun sọ ìdílé Jafẹti di pupọ,
kí ó máa gbé ninu àgọ́ Ṣemu,
ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.”
28Ọọdunrun ọdún ó lé aadọta (350) ni Noa tún gbé sí i lẹ́yìn ìkún omi. 29Noa kú nígbà tí ó di ẹni ẹgbẹrun ọdún ó dín aadọta (950).

Currently Selected:

JẸNẸSISI 9: YCE

Tya elembo

Share

Copy

None

Olingi kobomba makomi na yo wapi otye elembo na baapareyi na yo nyonso? Kota to mpe Komisa nkombo