1
JẸNẸSISI 9:12-13
Yoruba Bible
Ohun tí yóo jẹ́ àmì majẹmu tí mo ń bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá, tí yóo sì wà fún atọmọdọmọ yín ní ọjọ́ iwájú nìyí: mo fi òṣùmàrè mi sí ojú ọ̀run, òun ni yóo máa jẹ́ àmì majẹmu tí mo bá ayé dá.
Kokisana
Luka JẸNẸSISI 9:12-13
2
JẸNẸSISI 9:16
Nígbà tí òṣùmàrè bá yọ, n óo wò ó, n óo sì ranti majẹmu ayérayé tí èmi Ọlọrun bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.
Luka JẸNẸSISI 9:16
3
JẸNẸSISI 9:6
Ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, pípa ni a óo pa òun náà, nítorí pé ní àwòrán Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó dá eniyan.
Luka JẸNẸSISI 9:6
4
JẸNẸSISI 9:1
Ọlọrun súre fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.
Luka JẸNẸSISI 9:1
5
JẸNẸSISI 9:3
Gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ni yóo jẹ́ oúnjẹ fún yín, bí mo ti fún yín ní gbogbo ewéko, bẹ́ẹ̀ náà ni mo fún yín ní ohun gbogbo.
Luka JẸNẸSISI 9:3
6
JẸNẸSISI 9:2
Gbogbo ẹranko tí ó wà láyé, gbogbo ẹyẹ, gbogbo ẹja tí ń bẹ ninu omi, ati gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri ni yóo máa bẹ̀rù yín, ìkáwọ́ yín ni mo fi gbogbo wọn sí.
Luka JẸNẸSISI 9:2
7
JẸNẸSISI 9:7
“Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.”
Luka JẸNẸSISI 9:7
Ndako
Biblia
Bibongiseli
Bavideo