Joh 6
6
Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan
(Mat 14:13-21; Mak 6:30-44; Luk 9:10-17)
1LẸHIN nkan wọnyi, Jesu kọja si apakeji okun Galili, ti iṣe okun Tiberia.
2Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, nitoriti nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀, ti o nṣe lara awọn alaisàn.
3Jesu si gùn ori òke lọ, nibẹ̀ li o si gbé joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
4Ajọ irekọja, ọdun awọn Ju, si sunmọ etile.
5Njẹ bi Jesu ti gbé oju rẹ̀ soke, ti o si ri ọ̀pọ enia wá sọdọ rẹ̀, o wi fun Filippi pe, Nibo li a o ti rà akara, ki awọn wọnyi le jẹ?
6O si sọ eyi lati dán a wò; nitoriti on tikararẹ̀ mọ̀ ohun ti on ó ṣe.
7Filippi da a lohùn pe, Akara igba owo idẹ ko to fun wọn, ti olukuluku wọn iba fi mu diẹ-diẹ.
8Ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Anderu, arakunrin Simoni Peteru wi fun u pe,
9Ọmọdekunrin kan mbẹ nihinyi, ti o ni iṣu akara barle marun, ati ẹja kékèké meji: ṣugbọn kini wọnyi jẹ lãrin ọ̀pọ enia wọnyi bi eyi?
10Jesu si wipe, Ẹ mu ki awọn enia na joko. Koriko pipọ si wà nibẹ̀. Bẹ̃li awọn ọkunrin na joko, ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia ni iye.
11Jesu si mu iṣu akara wọnni; nigbati o si ti dupẹ, o pin wọn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si pín wọn fun awọn ti o joko; bẹ̃ gẹgẹ si li ẹja ni ìwọn bi nwọn ti nfẹ.
12Nigbati nwọn si yó, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ kó ajẹkù ti o kù jọ, ki ohunkohun máṣe ṣegbé.
13Bẹ̃ni nwọn kó wọn jọ nwọn si fi ajẹkù ìṣu akara barle marun na kún agbọn mejila eyi ti o ṣikù, fun awọn ti o jẹun.
14Nitorina nigbati awọn ọkunrin na ri iṣẹ àmi ti Jesu ṣe, nwọn wipe, Lõtọ eyi ni woli na ti mbọ̀ wá aiye.
15Nigbati Jesu si woye pe, nwọn nfẹ wá ifi agbara mu on lọ ifi jọba, o tún pada lọ sori òke on nikan.
Jesu Rìn lórí Omi
(Mat 14:22-33; Mak 6:45-52)
16Nigbati alẹ si lẹ, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ sinu okun.
17Nwọn si bọ sinu ọkọ̀, nwọn si rekọja okun lọ si Kapernaumu. Okunkun si ti kùn, Jesu kò si ti ide ọdọ wọn.
18Okun si nru nitori ẹfufu lile ti nfẹ.
19Nigbati nwọn wà ọkọ̀ to bi ìwọn furlongi mẹdọgbọn tabi ọgbọ̀n, nwọn ri Jesu nrìn lori okun, o si sunmọ ọkọ̀; ẹ̀ru si bà wọn.
20Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi ni; ẹ má bẹ̀ru.
21Nitorina nwọn fi ayọ̀ gbà a sinu ọkọ̀: lojukanna ọkọ̀ na si de ilẹ ibiti nwọn gbé nlọ.
Àwọn Eniyan Wá Jesu Rí
22Ni ijọ keji, nigbati awọn enia ti o duro li apakeji okun ri pe, kò si ọkọ̀ miran nibẹ̀, bikoṣe ọkanna ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀, ati pe Jesu kò ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀ inu ọkọ̀ na, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nikan li o lọ;
23(Ṣugbọn awọn ọkọ̀ miran ti Tiberia wá, leti ibi ti nwọn gbe jẹ akara, lẹhin igbati Oluwa ti dupẹ:)
24Nitorina nigbati awọn enia ri pe, Jesu kò si nibẹ̀, tabi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn pẹlu wọ̀ ọkọ̀ lọ si Kapernaumu, nwọn nwá Jesu.
Jesu ni Oúnjẹ Ìyè
25Nigbati nwọn si ri i li apakeji okun nwọn wi fun u pe, Rabbi, nigbawo ni iwọ wá sihinyi?
26Jesu da wọn lohùn o si wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin nwá mi, ki iṣe nitoriti ẹnyin ri iṣẹ àmi, ṣugbọn nitori ẹnyin jẹ iṣu akara wọnni, ẹnyin si yó.
27 Ẹ máṣe ṣiṣẹ fun onjẹ ti iṣegbé, ṣugbọn fun onjẹ ti iwà ti di ìye ainipẹkun, eyiti Ọmọ-enia yio fifun nyin: nitoripe on ni, ani Ọlọrun Baba ti fi edidi dí.
28Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kili awa o ha ṣe, ki a le ṣe iṣẹ Ọlọrun?
29Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Eyi ni iṣẹ Ọlọrun pe, ki ẹnyin ki o gbà ẹniti o rán gbọ́.
30Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iṣẹ ami kini iwọ nṣe, ki awa le ri, ki a si gbà ọ gbọ́? Iṣẹ kini iwọ ṣe?
31Awọn baba wa jẹ manna li aginjù; gẹgẹ bi a ti kọ ọ́ pe, O fi onjẹ fun wọn jẹ lati ọrun wá.
32Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì iṣe Mose li o fi onjẹ nì fun nyin lati ọrun wá; ṣugbọn Baba mi li o fi onjẹ otitọ nì fun nyin lati ọrun wá.
33 Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi ìye fun araiye.
34Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Oluwa, mã fun wa li onjẹ yi titi lai.
35Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai.
36 Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́.
37 Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri.
38 Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi.
39 Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ.
40 Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.
41Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá.
42Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? Ẽtiṣe tí ó wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá?
43Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin.
44 Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.
45 A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá.
46 Koṣepe ẹnikan ti ri Baba bikoṣe ẹniti o ti ọdọ Ọlọrun wá, on li o ti ri Baba.
47 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun.
48 Emi li onjẹ ìye.
49 Awọn baba nyin jẹ manna li aginjù, nwọn si kú.
50 Eyi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ki enia le mã jẹ ninu rẹ̀ ki o má si kú.
51 Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye.
52Nitorina li awọn Ju ṣe mba ara wọn jiyàn, wipe, ọkunrin yi yio ti ṣe le fi ara rẹ̀ fun wa lati jẹ?
53Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe ẹnyin ba jẹ ara Ọmo-enia, ki ẹnyin si mu ẹ̀jẹ rẹ̀, ẹnyin kò ni ìye ninu nyin.
54 Ẹnikẹni ti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ni ìye ti kò nipẹkun; Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.
55 Nitori ara mi li ohun jijẹ nitõtọ, ati ẹ̀jẹ mi li ohun mimu nitõtọ.
56 Ẹniti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ngbé inu mi, emi si ngbé inu rẹ̀.
57 Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi.
58 Eyi si li onjẹ na ti o sọkalẹ lati ọrun wá: ki iṣe bi awọn baba nyin ti jẹ manna, ti nwọn si kú: ẹniti o ba jẹ onjẹ yi yio yè lailai.
59Nkan wọnyi li o sọ ninu sinagogu, bi o ti nkọni ni Kapernaumu.
Ọ̀rọ̀ Ìyè Ainipẹkun
60Nitorina nigbati ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọ̀rọ ti o le li eyi; tani le gbọ́ ọ?
61Nigbati Jesu si mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nkùn si ọ̀rọ na, o wi fun wọn pe, Eyi jẹ ikọsẹ̀ fun nyin bi?
62 Njẹ, bi ẹnyin ba si ri ti Ọmọ-enia ngòke lọ sibi ti o gbé ti wà ri nkọ́?
63 Ẹmí ni isọni di ãye; ara kò ni ère kan; ọ̀rọ wọnni ti mo sọ fun nyin, ẹmi ni, ìye si ni.
64 Ṣugbọn awọn kan wà ninu nyin ti kò gbagbọ́. Nitori Jesu mọ̀ lati ìbẹrẹ wá ẹniti nwọn iṣe ti ko gbagbọ́, ati ẹniti yio fi on hàn.
65O si wipe, Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, kò si ẹniti o le tọ̀ mi wá, bikoṣepe a fifun u lati ọdọ Baba mi wá.
66Nitori eyi ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pada sẹhin, nwọn kò si bá a rìn mọ́.
67Nitorina Jesu wi fun awọn mejila pe, Ẹnyin pẹlu nfẹ lọ bi?
68Nigbana ni Simoni Peteru da a lohùn wipe, Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? Iwọ li o ni ọ̀rọ ìye ainipẹkun.
69Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye.
70Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin mejila kọ́ ni mo yàn, ọkan ninu nyin kò ha si yà Èṣu?
71O nsọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni: nitoripe on li ẹniti yio fi i hàn, ọkan ninu awọn mejila.
Pilihan Saat Ini:
Joh 6: YBCV
Sorotan
Berbagi
Salin
Ingin menyimpan sorotan di semua perangkat Anda? Daftar atau masuk
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.