Joh 10
10
Jesu Fi Aguntan Ṣe Àkàwé
1 LÕTỌ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti kò ba gbà ẹnu-ọ̀na wọ̀ inu agbo agutan, ṣugbọn ti o ba gbà ibomiran gùn oke, on na li olè ati ọlọṣà.
2 Ṣugbọn ẹniti o ba ba ti ẹnu-ọ̀na wọle, on ni iṣe oluṣọ awọn agutan.
3 On ni oludèna ṣilẹkun fun; awọn agutan si gbọ ohùn rẹ̀: o si pè awọn agutan tirẹ̀ li orukọ, o si ṣe amọ̀na wọn jade.
4 Nigbati o si mu awọn agutan tirẹ̀ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si ntọ̀ ọ lẹhin: nitoriti nwọn mọ̀ ohùn rẹ̀.
5 Nwọn kò jẹ tọ̀ alejò lẹhin, ṣugbọn nwọn a ma sá lọdọ rẹ̀: nitoriti nwọn kò mọ̀ ohùn alejò.
6Owe yi ni Jesu pa fun wọn: ṣugbọn òye ohun ti nkan wọnni jẹ ti o nsọ fun wọn kò yé wọn.
Jesu Ni Olùṣọ́-Aguntan Rere
7Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan.
8 Olè ati ọlọṣà ni gbogbo awọn ti o ti wá ṣiwaju mi: ṣugbọn awọn agutan kò gbọ́ ti wọn.
9 Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là, yio wọle, yio si jade, yio si ri koriko.
10 Olè kì iwá bikoṣe lati jale, ati lati pa, ati lati parun: emi wá ki nwọn le ni ìye, ani ki nwọn le ni i lọpọlọpọ.
11 Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn agutan.
12 Ṣugbọn alagbaṣe, ti kì iṣe oluṣọ-agutan, ẹniti awọn agutan kì iṣe tirẹ̀, o ri ikõkò mbọ̀, o si fi awọn agutan silẹ, o si sá lọ: ikõkò si mu awọn agutan, o si fọn wọn ká kiri.
13 Alagbaṣe sá lọ nitoriti iṣe alagbaṣe, kò si náni awọn agutan.
14 Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo si mọ̀ awọn temi, awọn temi si mọ̀ mi.
15 Gẹgẹ bi Baba ti mọ̀ mi, ti emi si mọ̀ Baba; mo si fi ẹmí mi lelẹ nitori awọn agutan.
16 Emi si ní awọn agutan miran, ti kì iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan.
17 Nitorina ni Baba mi ṣe fẹran mi, nitoriti mo fi ẹmí mi lelẹ, ki emi ki o le tún gbà a.
18 Ẹnikan kò gbà a lọwọ mi, ṣugbọn mo fi i lelẹ fun ara mi. Mo li agbara lati fi i lelẹ, mo si li agbara lati tún gbà a. Aṣẹ yi ni mo ti gbà lati ọdọ Baba mi wá.
19Nitorina iyapa tun wà larin awọn Ju nitori ọ̀rọ wọnyi.
20Ọpọ ninu wọn si wipe, O li ẹmi èṣu, ori rẹ̀ si bajẹ; ẽṣe ti ẹnyin ngbọ̀rọ rẹ̀?
21Awọn miran wipe, Wọnyi kì iṣe ọ̀rọ ẹniti o li ẹmi èsu. Ẹmi èsu le là oju awọn afọju bi?
Àwọn Juu Kọ Jesu
22O si jẹ ajọ ọdun iyasimimọ́ ni Jerusalemu, igba otutù ni.
23Jesu si nrìn ni tẹmpili, nì ìloro Solomoni.
24Nitorina awọn Ju wá duro yi i ká, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ó ti mu wa ṣe iyemeji pẹ to? Bi iwọ ni iṣe Kristi na, wi fun wa gbangba.
25Jesu da wọn lohùn wipe, Emi ti wi fun nyin, ẹnyin kò si gbagbọ́; iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni njẹri mi.
26 Ṣugbọn ẹnyin kò gbagbọ́, nitori ẹnyin kò si ninu awọn agutan mi, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin.
27 Awọn agutan mi ngbọ ohùn mi, emi si mọ̀ wọn, nwọn a si ma tọ̀ mi lẹhin:
28 Emi si fun wọn ni ìye ainipẹkun; nwọn kì o si ṣegbé lailai, kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ mi.
29 Baba mi, ẹniti o fi wọn fun mi, pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ Baba mi.
30 Ọ̀kan li emi ati Baba mi jasi.
31Awọn Ju si tún he okuta, lati sọ lù u.
32Jesu da wọn lohùn pe, Ọpọlọpọ iṣẹ rere ni mo fi hàn nyin lati ọdọ Baba mi wá; nitori ewo ninu iṣẹ wọnni li ẹnyin ṣe sọ mi li okuta?
33Awọn Ju si da a lohùn, wipe, Awa kò sọ ọ́ li okuta nitori iṣẹ rere, ṣugbọn nitori ọrọ-odi: ati nitori iwọ ti iṣe enia nfi ara rẹ ṣe Ọlọrun.
34Jesu da wọn lohùn pe, A kò ha ti kọ ọ ninu ofin nyin pe, Mo ti wipe, ọlọrun li ẹnyin iṣe?
35 Bi o ba pè wọn li ọlọrun, awọn ẹniti a fi ọ̀rọ Ọlọrun fun, a kò si le ba iwe-mimọ́ jẹ,
36 Ẹnyin ha nwi niti ẹniti Baba yà si mimọ́, ti o si rán si aiye pe, Iwọ nsọrọ-odi, nitoriti mo wipe Ọmọ Ọlọrun ni mi?
37 Bi emi kò ba ṣe iṣẹ Baba mi, ẹ máṣe gbà mi gbọ́.
38 Ṣugbọn bi emi ba ṣe wọn, bi ẹnyin kò tilẹ gbà mi gbọ́, ẹ gbà iṣẹ na gbọ́: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki o si le ye nyin pe, Baba wà ninu mi, emi si wà ninu rẹ̀.
39Nwọn si tun nwá ọ̀na lati mu u: o si bọ́ lọwọ wọn.
40O si tún kọja lọ si apakeji Jordani si ibiti Johanu ti kọ́ mbaptisi; nibẹ̀ li o si joko.
41Awọn enia pipọ si wá sọdọ rẹ̀, nwọn si wipe, Johanu ko ṣe iṣẹ àmi kan: ṣugbọn otitọ li ohun gbogbo ti Johanu sọ nipa ti ọkunrin yi.
42Awọn enia pipọ nibẹ̀ si gbà a gbọ́.
Pilihan Saat Ini:
Joh 10: YBCV
Sorotan
Berbagi
Salin
Ingin menyimpan sorotan di semua perangkat Anda? Daftar atau masuk
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.