Gẹn 13
13
Abramu ati Lọti Pínyà
1ABRAMU si goke lati Egipti wá, on, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ati Loti pẹlu rẹ̀, si ìha gusu.
2Abramu si là gidigidi, li ẹran-ọ̀sin, ni fadaka, ati ni wurà.
3O si nrìn ìrin rẹ̀ lati ìha gusu lọ titi o si fi de Beteli, de ibi ti agọ́ rẹ̀ ti wà ni iṣaju, lagbedemeji Beteli on Hai.
4Si ibi pẹpẹ ti o ti tẹ́ nibẹ̀ ni iṣaju: nibẹ̀ li Abramu si nkepè orukọ OLUWA.
5Ati Loti pẹlu, ti o ba Abramu lọ, ni agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran, ati agọ́.
6Ilẹ na kò si le igbà wọn, ki nwọn ki o le igbé pọ̀: nitori ini wọn pọ̀, bẹ̃nì nwọn kò si le gbé pọ̀.
7Bẹ̃ni gbolohùn asọ̀ si wà lãrin awọn darandaran Abramu, ati awọn darandaran Loti: ati awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi ngbé ilẹ na ni ìgba na.
8Abramu si wi fun Loti pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki gbolohùn asọ̀ ki o wà lãrin temi tirẹ, ati lãrin awọn darandaran mi, ati awọn darandaran rẹ; nitori pe ará li awa iṣe.
9Gbogbo ilẹ kọ́ eyi niwaju rẹ? emi bẹ̀ ọ, yà ara rẹ kuro lọdọ mi: bi iwọ ba pọ̀ si apa òsi, njẹ emi o pọ̀ si ọtún; tabi bi iwọ ba pọ̀ si apa ọtùn, njẹ emi o pọ̀ si òsi.
10Loti si gboju rẹ̀ si oke, o si wò gbogbo àgbegbe Jordani, pe o li omi nibi gbogbo, ki OLUWA ki o to pa Sodomu on Gomorra run, bi ọgbà OLUWA, bi ilẹ Egipti, bi iwọ ti mbọ̀wa si Soari.
11Nigbana ni Loti yàn gbogbo àgbegbe Jordani fun ara rẹ̀; Loti si nrìn lọ si ìha ìla-õrùn: bẹ̃ni nwọn yà ara wọn, ekini kuro lọdọ ekeji.
12Abramu si joko ni ilẹ Kenaani, Loti si joko ni ilu àgbegbe nì, o si pagọ́ rẹ̀ titi de Sodomu.
13Ṣugbọn awọn ọkunrin Sodomu ṣe enia buburu, ati ẹlẹṣẹ gidigidi niwaju OLUWA.
Abramu kó Lọ sí Heburoni
14OLUWA si wi fun Abramu, lẹhin igbati Loti yà kuro lọdọ rẹ̀ tan pe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò lati ibi ti o gbé wà nì lọ, si ìha ariwa, ati si ìha gusu, si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ìwọ-õrùn:
15Gbogbo ilẹ ti o ri nì, iwọ li emi o sa fi fun ati fun irú-ọmọ rẹ lailai.
16Emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi erupẹ ilẹ: tobẹ̃ bi o ba ṣepe enia kan ba le kà iye erupẹ ilẹ, on li a o to le kaye irú-ọmọ rẹ pẹlu.
17Dide, rìn ilẹ na já ni ìna rẹ̀, ati ni ibú rẹ̀; nitori iwọ li emi o fi fun.
18Nigbana ni Abramu ṣí agọ́ rẹ̀, o si wá o si joko ni igbo Mamre, ti o wà ni Hebroni, o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA.
Pilihan Saat Ini:
Gẹn 13: YBCV
Sorotan
Berbagi
Salin
Ingin menyimpan sorotan di semua perangkat Anda? Daftar atau masuk
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.