JOHANU 15
15
Jesu Ni Igi Àjàrà
1“Èmi ni àjàrà tòótọ́. Baba mi ni àgbẹ̀ tí ń mójútó ọgbà àjàrà. 2Gígé ni yóo gé gbogbo ẹ̀ka ara mi tí kò bá so èso, ṣugbọn yóo re ọwọ́ gbogbo ẹ̀ka tí ó bá ń so èso, kí wọ́n lè mọ́, kí wọ́n sì lè máa so sí i lọpọlọpọ. 3Ẹ̀yin ti di mímọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín. 4Ẹ máa gbé inú mi, èmi óo máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ àfi bí ó bá wà lára igi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò lè so èso àfi bí ẹ bá ń gbé inú mi.
5“Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi. 6Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbé inú mi, a óo jù ú sóde bí ẹ̀ka, yóo sì gbẹ; wọn óo mú un, wọn óo sì fi dáná, yóo bá jóná. 7Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà. 8Báyìí ni ògo Baba mi yóo ṣe yọ, pé kí ẹ máa so ọpọlọpọ èso. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi. 9Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ràn mi, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ràn yín. Ẹ máa gbé inú ìfẹ́ mi. 10Bí ẹ bá pa òfin mi mọ́, ẹ óo máa gbé inú ìfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì ń gbé inú ìfẹ́ rẹ̀.
11“Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ayọ̀ mi lè wà ninu yín, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. 12Àṣẹ mi nìyí; ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín.#Joh 13:34; 15:17; 1 Joh 3:23; 2 Joh 5 13Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. 14Ọ̀rẹ́ mi ni yín bí ẹ bá ń ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. 15N kò pè yín ní ọmọ-ọ̀dọ̀ mọ́, nítorí ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣugbọn mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Baba mi ni mo ti fihàn yín. 16Kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ yàn mí. Èmi ni mo yàn yín, tí mo ran yín pé kí ẹ lọ máa so èso tí kò ní bàjẹ́, kí Baba lè fun yín ní ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi. 17Àṣẹ yìí ni mo pa fun yín: ẹ fẹ́ràn ara yín.
Ọmọ-Aráyé Yóo Kórìíra Yín
18“Bí aráyé bá kórìíra yín, kí ẹ mọ̀ pé èmi ni wọ́n kọ́ kórìíra ṣáájú yín. 19Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé ni yín, ayé ìbá fẹ́ràn yín bí àwọn ẹni tirẹ̀. Ṣugbọn ẹ kì í ṣe ti ayé nítorí mo ti yàn yín kúrò ninu ayé; ìdí rẹ̀ nìyí tí ayé fi kórìíra yín. 20Ẹ ranti ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín, pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ kò ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ṣe inúnibíni mi, wọn yóo ṣe inúnibíni yín. Bí wọ́n bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóo pa ti ẹ̀yin náà mọ́.#Mat 10:24; Luk 6:40; Joh 13:16 21Wọn yóo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi si yín nítorí tèmi, nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. 22Bí n kò bá wá láti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọn kò ní àwáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 23Ẹni tí ó bá kórìíra mi, kórìíra Baba mi. 24Bí n kò bá ṣe irú iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi, sibẹ wọ́n kórìíra èmi ati Baba mi. 25Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ ninu Òfin wọn lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’#O. Daf 35:19; 69:4
26“Nígbà tí Alátìlẹ́yìn tí n óo rán si yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, àní Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, yóo jẹ́rìí nípa mi. 27Ẹ̀yin náà yóo sì jẹ́rìí mi nítorí ẹ ti wà pẹlu mi láti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi.
હાલમાં પસંદ કરેલ:
JOHANU 15: YCE
Highlight
શેર કરો
નકલ કરો
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010