JOHANU 11

11
Ikú Lasaru
1Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Lasaru ń ṣàìsàn. Ní Bẹtani ni ó ń gbé, ní ìlú kan náà pẹlu Maria ati Mata arabinrin rẹ̀.#Luk 10:38-39 2Maria yìí ni obinrin tí ó tú òróró olóòórùn dídùn sára Oluwa ní ọjọ́ kan, tí ó fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jesu. Lasaru tí ó ń ṣàìsàn jẹ́ arakunrin Maria yìí.#Joh 12:3 3Àwọn arabinrin mejeeji yìí ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Jesu pé, “Oluwa, ẹni tí o fẹ́ràn ń ṣàìsàn.”
4Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àìsàn yìí kì í ṣe ti ikú, fún ògo Ọlọrun ni, kí á lè ṣe Ọmọ Ọlọrun lógo nípa rẹ̀ ni.”
5Jesu fẹ́ràn Mata ati arabinrin rẹ̀ ati Lasaru. 6Nígbà tí Jesu gbọ́ pé Lasaru ń ṣàìsàn, kò kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ́ meji. 7Lẹ́yìn náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á tún pada lọ sí Judia.”
8Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, láìpẹ́ yìí ni àwọn Juu ń fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, o tún fẹ́ lọ sibẹ?”
9Jesu ní, “Ṣebí wakati mejila ni ó wà ninu ọjọ́ kan? Bí ẹnikẹ́ni bá rìn ní ọ̀sán kò ní kọsẹ̀, nítorí ó ń fi ìmọ́lẹ̀ ayé yìí ríran. 10Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá ń rìn lálẹ́ níí kọsẹ̀, nítorí kò sí ìmọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.” 11Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó sọ fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti sùn, mò ń lọ jí i.”
12Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá sùn, yóo tún jí.”
13Ohun tí Jesu ń sọ̀rọ̀ bá ni ikú Lasaru, ṣugbọn wọ́n rò pé nípa oorun sísùn ni ó ń sọ. 14Nígbà náà ni Jesu wá wí fún wọn pàtó pé, “Lasaru ti kú. 15Ó dùn mọ́ mi nítorí yín pé n kò sí níbẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”
16Nígbà náà ni Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Ìbejì”) sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kí àwa náà lè bá a kú.”
Jesu Ni Ajinde ati Ìyè
17Nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé ó ti tó ọjọ́ mẹrin tí òkú náà ti wà ninu ibojì. 18Bẹtani kò jìnnà sí Jerusalẹmu, kò ju ibùsọ̀ meji lọ. 19Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ni wọ́n wá láti Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Mata ati Maria láti tù wọ́n ninu nítorí ikú arakunrin wọn.
20Nígbà tí Mata gbọ́ pé Jesu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀. Ṣugbọn Maria jókòó ninu ilé. 21Mata sọ fún Jesu pé, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú! 22Ṣugbọn nisinsinyii náà, mo mọ̀ pé ohunkohun tí o bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo ṣe é fún ọ.”
23Jesu wí fún un pé, “Arakunrin rẹ yóo jí dìde.”
24Mata dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé yóo jí dìde ní ajinde ọjọ́ ìkẹyìn.”#2 Makab 7:22-23; 12:44
25Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ajinde ati ìyè. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, sibẹ yóo yè. 26Gbogbo ẹni tí ó bá wà láàyè, tí ó bá gbà mí gbọ́, kò ní kú laelae. Ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́?”
27Ó dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, mo gbàgbọ́ pé ìwọ ni Mesaya Ọmọ Ọlọrun tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.”
Jesu Abánidárò
28Nígbà tí Mata ti sọ báyìí tán, ó lọ pe Maria arabinrin rẹ̀ sí ìkọ̀kọ̀. Ó ní, “Olùkọ́ni ti dé, ó ń pè ọ́.” 29Bí Maria ti gbọ́, ó dìde kíá, ó bá lọ sọ́dọ̀ Jesu. 30(Jesu kò tíì wọ ìlú, ó wà ní ibi tí Mata ti pàdé rẹ̀.) 31Nígbà tí àwọn Juu tí ó wà ninu ilé pẹlu Maria, tí wọn ń tù ú ninu, rí i pé ó sáré dìde, ó jáde, àwọn náà tẹ̀lé e, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti lọ sunkún ni.
32Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.”
33Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́. 34Ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?”
Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wá wò ó.”
35Ni Jesu bá bú sẹ́kún.
36Nígbà náà ni àwọn Juu sọ pé, “Ẹ ò rí i bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”
37Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?”
Lasaru Tún Di Alààyè
38Orí Jesu tún wú, ó bá lọ síbi ibojì. Ninu ihò òkúta ni ibojì náà wà, òkúta sì wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀. 39Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.”
Mata, arabinrin ẹni tí ó kú, sọ fún un pé, “Oluwa, ó ti ń rùn, nítorí ó ti di òkú ọjọ́ mẹrin!”
40Jesu wí fún un pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé bí o bá gbàgbọ́ ìwọ yóo rí ògo Ọlọrun.” 41Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi. 42Mo mọ̀ pé nígbà gbogbo ni ò ń gbọ́ tèmi, ṣugbọn nítorí ti àwọn eniyan tí ó dúró yíká ni mo ṣe sọ èyí kí wọ́n lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni o rán mi níṣẹ́.” 43Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó kígbe sókè pé, “Lasaru, jáde wá!” 44Ẹni tí ó ti kú náà bá jáde pẹlu aṣọ òkú tí wọ́n fi wé e lọ́wọ́ ati lẹ́sẹ̀ ati ọ̀já tí wọ́n fi dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, kí ẹ jẹ́ kí ó máa lọ.”
Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Jesu
(Mat 26:1-5; Mak 14:1-2; Luk 22:1-2)
45Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu tí ó wá sọ́dọ̀ Maria gba Jesu gbọ́ nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣe. 46Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi, wọ́n lọ sọ ohun gbogbo tí Jesu ṣe. 47Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi bá pe ìgbìmọ̀, wọ́n ní, “Kí ni a óo ṣe o, nítorí ọkunrin yìí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ? 48Bí a bá fi í sílẹ̀ báyìí, gbogbo eniyan ni yóo gbà á gbọ́, àwọn ará Romu yóo bá wá, wọn yóo wo Tẹmpili yìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo pa orílẹ̀-èdè wa run.”
49Nígbà náà ni ọ̀kan ninu wọn, Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà, sọ fún wọn pé, “Ẹ kò mọ nǹkankan! 50Ẹ kò rí i pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún àwọn eniyan jù pé kí gbogbo orílẹ̀-èdè ṣègbé!” 51Kì í ṣe àròsọ ti ara rẹ̀ ni ó fi sọ gbolohun yìí, ṣugbọn nítorí ó jẹ́ olórí alufaa ní ọdún náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ni, pé Jesu yóo kú fún orílẹ̀-èdè wọn. 52Kì í wá ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn nìkan, ṣugbọn kí àwọn ọmọ Ọlọrun tí ó fọ́nká lè papọ̀ di ọ̀kan.
53Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń gbèrò ọ̀nà tí wọn yóo fi pa Jesu. 54Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
55Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ti àwọn Juu, ọ̀pọ̀ eniyan gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti ìgbèríko, kí ó tó tó àkókò àjọ̀dún, kí wọ́n lè ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àjọ̀dún náà. 56Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá Jesu, wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti dúró ninu Tẹmpili pé, “Kí ni ẹ rò? Ǹjẹ́ ó jẹ́ wá sí àjọ̀dún yìí?” 57Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ ibi tí Jesu wà, kí ó wá sọ, kí wọ́n lè mú un.

હાલમાં પસંદ કરેલ:

JOHANU 11: YCE

Highlight

શેર કરો

નકલ કરો

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in