JẸNẸSISI 17

17
Ilà Abẹ́ Kíkọ, Àmì Majẹmu Ọlọrun
1Nígbà tí Abramu di ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un, OLUWA farahàn án, ó sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa gbọ́ tèmi, kí o sì jẹ́ pípé. 2N óo bá ọ dá majẹmu kan, tí yóo wà láàrin èmi pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ lọpọlọpọ.” 3Abramu bá dojúbolẹ̀, Ọlọrun tún wí fún un pé, 4“Majẹmu tí mo bá ọ dá kò yẹ̀ rárá: O óo jẹ́ baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè. 5Orúkọ rẹ kò ní jẹ́ Abramu mọ́, Abrahamu ni o óo máa jẹ́, nítorí mo ti sọ ọ́ di baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.#Rom 4:17 6N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo sì ti ara rẹ jáde.”
7“N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ. Majẹmu náà yóo wà títí ayérayé pé, èmi ni n óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ ati ti atọmọdọmọ rẹ.#Luk 1:55 8N óo fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ náà tí o ti jẹ́ àlejò yìí yóo di ìní rẹ títí ayérayé ati ti atọmọdọmọ rẹ, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn!”#A. Apo 7:5.
9Ọlọrun tún sọ fún Abrahamu pé, “Ìwọ pàápàá gbọdọ̀ pa majẹmu mi mọ́, ìwọ ati atọmọdọmọ rẹ láti ìrandíran wọn. 10Majẹmu náà tí ó wà láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ, tí ẹ gbọdọ̀ pamọ́ nìyí, gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́.#A. Apo 7:8; Rom 4:11 11Ilà abẹ́ tí ẹ gbọdọ̀ kọ yìí ni yóo jẹ́ àmì majẹmu tí ó wà láàrin mi pẹlu yín. 12Gbogbo ọmọkunrin tí ó bá ti pé ọmọ ọjọ́ mẹjọ láàrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́, gbogbo ọmọkunrin ninu ìran yín, kì báà ṣe èyí tí a bí ninu ilé yín, tabi ẹrú tí ẹ rà lọ́wọ́ àjèjì, tí kì í ṣe ìran yín, 13gbogbo ọmọ tí ẹ bí ninu ilé yín, ati ẹrú tí ẹ fi owó yín rà gbọdọ̀ kọlà abẹ́. Èyí yóo jẹ́ kí majẹmu mi wà lára yín, yóo sì jẹ́ majẹmu ayérayé. 14Gbogbo ọkunrin tí kò bá kọlà abẹ́ ni a óo yọ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ó ti ba majẹmu mi jẹ́.”
15Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai aya rẹ, má ṣe pè é ní Sarai mọ́, Sara ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́. 16N óo bukun un, n óo sì fún ọ ní ọmọkunrin kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, n óo bukun un, yóo sì di ìyá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo wà lára atọmọdọmọ rẹ̀.”
17Nígbà náà ni Abrahamu dojúbolẹ̀, ó búsẹ́rìn-ín, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Ọkunrin tí ó ti di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ha tún lè bímọ bí? Sara, tí ó ti di ẹni aadọrun-un ọdún ha tún lè bímọ bí?” 18Abrahamu bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣá ti bá mi dá Iṣimaeli yìí sí.”
19Ọlọrun dá a lóhùn, pé, “Rárá o, àní, Sara, aya rẹ, yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo sọ ọmọ náà ní Isaaki. N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé fún atọmọdọmọ rẹ̀. 20Ní ti Iṣimaeli, mo ti gbọ́ ìbéèrè rẹ, wò ó, n óo bukun òun náà, n óo sì fún un ní ọpọlọpọ ọmọ ati ọmọ ọmọ, yóo jẹ́ baba fún àwọn ọba mejila, n óo sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá. 21Ṣugbọn n óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu Isaaki, tí Sara yóo bí fún ọ ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀.” 22Nígbà tí Ọlọrun bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
23Abrahamu bá mú Iṣimaeli ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ẹrukunrin tí wọ́n bí ninu ilé rẹ̀ ati àwọn tí ó fi owó rẹ̀ rà, àní gbogbo ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé Abrahamu, ó sì kọ gbogbo wọn ní ilà abẹ́ ní ọjọ́ náà, bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un. 24Abrahamu jẹ́ ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un nígbà tí ó kọ ilà abẹ́. 25Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọdún mẹtala nígbà tí òun náà kọlà abẹ́. 26Ní ọjọ́ náà gan-an ni Abrahamu ati Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ kọlà abẹ́, 27ati gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n fi owó rà, gbogbo wọn ni wọ́n kọ nílà abẹ́ pẹlu rẹ̀.

હાલમાં પસંદ કરેલ:

JẸNẸSISI 17: YCE

Highlight

શેર કરો

નકલ કરો

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in