JẸNẸSISI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìtumọ̀ Jẹnẹsisi ni “Ìpìlẹ̀” tabi “Ìṣẹ̀dálẹ̀.” Inú ìwé Jẹnẹsisi ni ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé wà; bí a ti ṣẹ̀dá ọmọ eniyan, ìpìlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ati bí ìnira ṣe bẹ̀rẹ̀ láyé, ati ìhà tí Ọlọrun kọ sí eniyan. Ọ̀nà meji pataki ni a lè pín ìtàn inú ìwé Jẹnẹsisi sí:
(1) Orí 1-11: Ìtàn nípa ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ati ìtàn ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀yà eniyan. Bákan náà, ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ a óo rí kà nípa Adamu ati Efa, Kaini ati Abeli, Noa ati ìkún omi, ati nípa ilé ìṣọ́ Babiloni.
(2) Orí 12-50: Ìtàn àwọn Baba ńlá àwọn ọmọ Israẹli. Abrahamu ni ẹni àkọ́kọ́, ó jẹ́ olókìkí eniyan nípa ẹ̀mí igbagbọ tí ó ní, ati ìgbọràn sí Ọlọrun. Ìtàn ọmọ rẹ̀, Isaaki, ni ó tẹ̀lé e, lẹ́yìn náà ni ti ọmọ ọmọ rẹ̀, Jakọbu, (tí ó tún ń jẹ́ Israẹli), ati ti àwọn ọmọ Jakọbu mejeejila, àwọn ni wọ́n pilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Ní pataki, ìtàn Josẹfu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli jẹyọ ati ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe okùnfà bí Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu àwọn ẹbí wọn ṣe di èrò Ijipti, (ní ilẹ̀ tí wọ́n ti ṣe àtìpó).
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé yìí sọ ọpọlọpọ ìtàn nípa eniyan, sibẹ ohun tí Ọlọrun ṣe ni ó pilẹ̀ rẹ̀, tí ó sì jẹ́ kókó pataki. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé náà, a rí ẹ̀rí ìdánilójú pé Ọlọrun ni ó dá ayé, ní ìkẹyìn, Ọlọrun ṣèlérí pé òun yóo máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn eniyan òun. Láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ìwé náà, Ọlọrun ni ẹ̀dá ìtàn tí ó súyọ jùlọ, òun ni onídàájọ́, a sì máa fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, a máa darí àwọn eniyan rẹ̀, a sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́, bákan náà ni ó máa ń ṣàkóso ìgbésí ayé wọn. A kọ ìwé àtayébáyé yìí láti ṣe àgbékalẹ̀ ìtàn nípa igbagbọ àwọn eniyan kan ati pé kí iná irú igbagbọ bẹ́ẹ̀ baà lè máa jó àjóròkè sí i.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ati ti ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀yà eniyan 1:1–2:25
Ìpìlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ati ìjìyà 3:1-24
Ìtàn láti orí Adamu títí dé ti Noa 4:1–5:32
Noa ati ìkún omi 6:1–10:32
Ilé ìṣọ́ Babiloni 11:1-9
Ìtàn láti orí Ṣemu títí dé ti Abramu 11:10-32
Àwọn Baba ńlá àwọn ọmọ Israẹli: Abrahamu, Isaaki, Jakọbu 12:1–35:29
Àwọn arọmọdọmọ Esau 36:1-43
Josẹfu ati àwọn arakunrin rẹ̀ 37:1–45:28
Àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ Ijipti 46:1–50:26

اکنون انتخاب شده:

JẸNẸSISI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

های‌لایت

به اشتراک گذاشتن

کپی

None

می خواهید نکات برجسته خود را در همه دستگاه های خود ذخیره کنید؟ برای ورودثبت نام کنید یا اگر ثبت نام کرده اید وارد شوید