YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 74

74
Ranti Wa, OLUWA
1ỌLỌRUN, ẽṣe ti iwọ fi ta wa nù titi lai! ẽṣe ti ibinu rẹ fi nrú si agutan papa rẹ?
2Ranti ijọ enia rẹ ti iwọ ti rà nigba atijọ; ilẹ-ini rẹ ti iwọ ti rà pada; òke Sioni yi, ninu eyi ti iwọ ngbe.
3Gbé ẹsẹ rẹ soke si ahoro lailai nì; ani si gbogbo eyiti ọta ti fi buburu ṣe ni ibi-mimọ́.
4Awọn ọta rẹ nke ramu-ramu lãrin ijọ enia rẹ; nwọn gbé asia wọn soke fun àmi.
5Nwọn dabi ọkunrin ti ngbé akeke rẹ̀ soke ninu igbo didi,
6Ṣugbọn nisisiyi iṣẹ ọnà finfin ni nwọn fi akeke ati òlu wó lulẹ pọ̀ li ẹ̃kan.
7Nwọn tinabọ ibi-mimọ́ rẹ, ni wiwo ibujoko orukọ rẹ lulẹ, nwọn sọ ọ di ẽri.
8Nwọn wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a run wọn pọ̀: nwọn ti kun gbogbo ile Ọlọrun ni ilẹ na.
9Awa kò ri àmi wa: kò si woli kan mọ́: bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi yio ti pẹ to.
10Ọlọrun, ọta yio ti kẹgan pẹ to? ki ọta ki o ha ma sọ̀rọ òdi si orukọ rẹ lailai?
11Ẽṣe ti iwọ fi fa ọwọ rẹ sẹhin, ani ọwọ ọtún rẹ? fà a yọ jade kuro li õkan aiya rẹ ki o si pa a run.
12Nitori Ọlọrun li Ọba mi li atijọ wá, ti nṣiṣẹ igbala lãrin aiye.
13Iwọ li o ti yà okun ni meji nipa agbara rẹ: iwọ ti fọ́ ori awọn erinmi ninu omi.
14Iwọ fọ́ ori Lefiatani tũtu, o si fi i ṣe onjẹ fun awọn ti ngbe inu ijù.
15Iwọ là orisun ati iṣan-omi: iwọ gbẹ awọn odò nla.
16Tirẹ li ọsán, tirẹ li oru pẹlu: iwọ li o ti pèse imọlẹ ati õrun.
17Iwọ li o ti pàla eti aiye: iwọ li o ṣe igba ẹ̀run ati igba otutu.
18Ranti eyi, Oluwa, pe ọta nkẹgàn, ati pe awọn enia buburu nsọ̀rọ odi si orukọ rẹ.
19Máṣe fi ọkàn àdaba rẹ le ẹranko igbẹ lọwọ: máṣe gbagbe ijọ awọn talaka rẹ lailai.
20Juba majẹmu nì: nitori ibi òkunkun aiye wọnni o kún fun ibugbe ìka.
21Máṣe jẹ ki ẹniti a ni lara ki o pada ni ìtiju; jẹ ki talaka ati alaini ki o yìn orukọ rẹ.
22Ọlọrun, dide, gbà ẹjọ ara rẹ rò: ranti bi aṣiwere enia ti ngàn ọ lojojumọ.
23Máṣe gbagbe ohùn awọn ọta rẹ: irọkẹ̀kẹ awọn ti o dide si ọ npọ̀ si i nigbagbogbo.

Currently Selected:

O. Daf 74: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in