YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 73

73
IWE KẸTA
(O. Daf 73—89)
Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun
1NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́.
2Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan.
3Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu.
4Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀.
5Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran.
6Nitorina ni igberaga ṣe ká wọn lọrun bi ẹ̀wọn ọṣọ́; ìwa-ipa bò wọn mọlẹ bi aṣọ.
7Oju wọn yọ jade fun isanra: nwọn ní jù bi ọkàn wọn ti nfẹ lọ.
8Nwọn nṣẹsin, nwọn si nsọ̀rọ buburu niti inilara: nwọn nsọ̀rọ lati ibi giga.
9Nwọn gbé ẹnu wọn le ọrun, ahọn wọn si nrìn ilẹ já.
10Nitorina li awọn enia rẹ̀ ṣe yipada si ihin: ọ̀pọlọpọ omi li a si npọn jade fun wọn.
11Nwọn si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀? ìmọ ha wà ninu Ọga-ogo?
12Kiyesi i, awọn wọnyi li alaìwa-bi-ọlọrun, ẹniti aiye nsan, nwọn npọ̀ li ọrọ̀.
13Nitõtọ li asan ni mo wẹ̀ aiya mi mọ́, ti mo si wẹ̀ ọwọ mi li ailẹ̀ṣẹ.
14Nitoripe ni gbogbo ọjọ li a nyọ mi lẹnu, a si nnà mi li orowurọ.
15Bi emi ba pe, emi o fọ̀ bayi: kiyesi i, emi o ṣẹ̀ si iran awọn ọmọ rẹ.
16Nigbati mo rò lati mọ̀ eyi, o ṣoro li oju mi.
17Titi mo fi lọ sinu ibi-mimọ́ Ọlọrun; nigbana ni mo mọ̀ igbẹhin wọn.
18Nitõtọ iwọ gbé wọn ka ibi yiyọ́: iwọ tì wọn ṣubu sinu iparun.
19Bawo li a ti mu wọn lọ sinu idahoro yi, bi ẹnipe ni iṣẹju kan! ibẹru li a fi nrun wọn patapata.
20Bi igbati ẹnikan ba ji li oju alá; bẹ̃ni Oluwa, nigbati iwọ ba ji, iwọ o ṣe àbuku àworan wọn.
21Bayi ni inu mi bajẹ, ẹgún si gun mi li ọkàn mi.
22Bẹ̃ni mo ṣiwere, ti emi kò si mọ̀ nkan; mo dabi ẹranko niwaju rẹ.
23Ṣugbọn emi wà pẹlu rẹ nigbagbogbo: iwọ li o ti di ọwọ ọtún mi mu.
24Iwọ o fi ìmọ rẹ tọ́ mi li ọ̀na, ati nigbẹhin iwọ o gbà mi sinu ogo.
25Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ.
26Ẹran-ara mi ati aiya mi di ãrẹ̀ tan: ṣugbọn Ọlọrun ni apata aiya mi, ati ipin mi lailai.
27Sa wò o, awọn ti o jina si ọ yio ṣegbe: iwọ ti pa gbogbo wọn run ti nṣe àgbere kiri kuro lọdọ rẹ.
28Ṣugbọn o dara fun mi lati sunmọ Ọlọrun: emi ti gbẹkẹ mi le Oluwa Ọlọrun, ki emi ki o le ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ gbogbo.

Currently Selected:

O. Daf 73: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in