YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 2

2
Àyànfẹ́ Ọlọrun
1ẼṢE ti awọn orilẹ-ède fi nbinu fùfu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan?
2Awọn ọba aiye kẹsẹ jọ, ati awọn ijoye ngbimọ pọ̀ si Oluwa ati si Ẹni-ororo rẹ̀ pe,
3Ẹ jẹ ki a fa ìde wọn já, ki a si mu okùn wọn kuro li ọdọ wa.
4Ẹniti o joko li ọrun yio rẹrin: Oluwa yio yọ ṣùti si wọn.
5Nigbana ni yio sọ̀rọ si wọn ni ibinu rẹ̀, yio si yọ wọn lẹnu ninu ibinujẹ rẹ̀ kikan.
6Ṣugbọn mo ti fi Ọba mi jẹ lori Sioni, òke mimọ́ mi.
7Emi o si rohin ipinnu Oluwa: O ti wi fun mi pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bi ọ.
8Bère lọwọ mi, emi o si fi awọn orilẹ-ède fun ọ ni ini rẹ, ati iha opin ilẹ li ọrọ̀-ilẹ rẹ.
9Ọpá irin ni iwọ o fi fọ́ wọn; iwọ o si rún wọn womuwomu, bi ohun èlo amọ̀.
10Njẹ nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n, ẹnyin ọba: ki a si kọ́ nyin, ẹnyin onidajọ aiye.
11Ẹ fi ìbẹru sìn Oluwa, ẹ si ma yọ̀ ti ẹnyin ti iwarìri.
12Fi ẹnu kò Ọmọ na lẹnu, ki o máṣe binu, ẹnyin a si ṣegbe li ọ̀na na, bi inu rẹ̀ ba ru diẹ kiun. Ibukún ni fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.

Currently Selected:

O. Daf 2: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in