YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 1

1
Ayọ̀ Tòótọ́
IWE KINNI
(O. Daf 1—41)
1IBUKÚN ni fun ọkunrin na ti kò rìn ni ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ati ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn.
2Ṣugbọn didùn-inu rẹ̀ wà li ofin Oluwa; ati ninu ofin rẹ̀ li o nṣe aṣaro li ọsan ati li oru.
3Yio si dabi igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rẹ̀ jade li akokò rẹ̀; ewe rẹ̀ kì yio si rẹ̀; ati ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede.
4Awọn enia buburu kò ri bẹ̃: ṣugbọn nwọn dabi iyangbo ti afẹfẹ nfẹ lọ.
5Nitorina awọn enia buburu kì yio dide duro ni idajọ, bẹ̃li awọn ẹlẹṣẹ kì yio le duro li awujọ awọn olododo.
6Nitori Oluwa mọ̀ ọ̀na awọn olododo: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio ṣegbe.

Currently Selected:

O. Daf 1: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in