O. Daf 106
106
Oore OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀
1Ẹ fi iyìn fun Oluwa! Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun: nitoriti ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
2Tali o le sọ̀rọ iṣẹ agbara Oluwa? tali o le fi gbogbo iyìn rẹ̀ hàn?
3Ibukún ni fun awọn ti npa idajọ mọ́, ati ẹniti nṣe ododo ni igbagbogbo.
4Oluwa, fi oju-rere ti iwọ ni si awọn enia rẹ ṣe iranti mi: fi igbala rẹ bẹ̀ mi wò.
5Ki emi ki o le ri ire awọn ayanfẹ rẹ, ki emi ki o le yọ̀ ninu ayọ̀ orilẹ-ède rẹ, ki emi ki o le ma ṣogo pẹlu awọn enia ilẹ-ini rẹ.
6Awa ti ṣẹ̀ pẹlu awọn baba wa, awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe buburu.
7Iṣẹ iyanu rẹ kò yé awọn baba wa ni Egipti; nwọn kò ranti ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ; ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si ọ nibi okun, ani nibi Okun pupa.
8Ṣugbọn o gbà wọn là nitori orukọ rẹ̀, ki o le mu agbara rẹ̀ nla di mimọ̀.
9O ba Okun pupa wi pẹlu, o si gbẹ: bẹ̃li o sìn wọn là ibu ja bi aginju.
10O si gbà wọn là li ọwọ ẹniti o korira wọn, o si rà wọn pada li ọwọ ọta nì.
11Omi si bò awọn ọta wọn: ẹnikan wọn kò si kù.
12Nigbana ni nwọn gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́: nwọn si kọrin iyìn rẹ̀.
13Nwọn kò pẹ igbagbe iṣẹ rẹ̀: nwọn kò si duro de imọ̀ rẹ̀.
14Nwọn si ṣe ifẹkufẹ li aginju, nwọn si dan Ọlọrun wò ninu aṣálẹ̀.
15O si fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn.
16Nwọn ṣe ilara Mose pẹlu ni ibudo, ati Aaroni, ẹni-mimọ́ Oluwa.
17Ilẹ là, o si gbé Datani mì, o si bò ẹgbẹ́ Abiramu mọlẹ.
18Iná si ràn li ẹgbẹ́ wọn; ọwọ́ iná na jó awọn enia buburu.
19Nwọn ṣe ẹgbọrọ malu ni Horebu, nwọn si foribalẹ fun ere didà.
20Bayi ni nwọn pa ogo wọn dà si àworan malu ti njẹ koriko.
21Nwọn gbagbe Ọlọrun, Olugbala wọn, ti o ti ṣe ohun nla ni ilẹ Egipti.
22Iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu, ati ohun ẹ̀ru lẹba Okun pupa.
23Nitorina li o ṣe wipe, on o run wọn, iba máṣe pe Mose, ayanfẹ rẹ̀, duro niwaju rẹ̀ li oju-ẹya na, lati yi ibinu rẹ̀ pada, ki o má ba run wọn.
24Nitõtọ, nwọn kò kà ilẹ didara nì si, nwọn kò gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́:
25Ṣugbọn nwọn nkùn ninu agọ wọn, nwọn kò si feti si ohùn Oluwa.
26Nitorina li o ṣe gbé ọwọ rẹ̀ soke si wọn, lati bì wọn ṣubu li aginju:
27Lati bì iru-ọmọ wọn ṣubu pẹlu lãrin awọn orilẹ-ède, ati lati fún wọn ka kiri ni ilẹ wọnni.
28Nwọn da ara wọn pọ̀ pẹlu mọ Baali-Peoru, nwọn si njẹ ẹbọ okú.
29Bayi ni nwọn fi iṣẹ wọn mu u binu: àrun nla si fó si arin wọn.
30Nigbana ni Finehasi dide duro, o si ṣe idajọ: bẹ̃li àrun nla na si dá.
31A si kà eyi na si fun u li ododo lati irandiran titi lai.
32Nwọn bi i ninu pẹlu nibi omi Ijà, bẹ̃li o buru fun Mose nitori wọn:
33Nitori ti nwọn mu ẹmi rẹ̀ binu, bẹ̃li o fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ aiyẹ.
34Nwọn kò run awọn orilẹ-ède na, niti ẹniti Oluwa paṣẹ fun wọn:
35Ṣugbọn nwọn da ara wọn pọ̀ mọ́ awọn keferi, nwọn si kọ́ iṣẹ wọn.
36Nwọn si sìn ere wọn: ti o di ikẹkun fun wọn.
37Nitõtọ nwọn fi ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn rubọ si oriṣa.
38Nwọn si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ, ani ẹ̀jẹ awọn ọmọkunrin wọn ati ti awọn ọmọbinrin wọn, ti nwọn fi rubọ si ere Kenaani: ilẹ na si di aimọ́ fun ẹ̀jẹ.
39Nwọn si fi iṣẹ ara wọn sọ ara wọn di alaimọ́, nwọn si ṣe panṣaga lọ pẹlu iṣẹ wọn.
40Nitorina ni ibinu Oluwa ṣe ràn si awọn enia rẹ̀, o si korira awọn enia ini rẹ̀.
41O si fi wọn le awọn keferi lọwọ; awọn ti o korira wọn si ṣe olori wọn.
42Awọn ọta wọn si ni wọn lara, nwọn si mu wọn sìn labẹ ọwọ wọn.
43Igba pupọ li o gbà wọn; sibẹ nwọn fi ìmọ wọn mu u binu, a si rẹ̀ wọn silẹ nitori ẹ̀ṣẹ wọn.
44Ṣugbọn ninu ipọnju o kiyesi wọn, nigbati o gbọ́ ẹkún wọn.
45O si ranti majẹmu rẹ̀ fun wọn, o si yi ọkàn pada gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀.
46O si mu wọn ri ãnu loju gbogbo awọn ti o kó wọn ni igbekun.
47Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa, ki o si ṣa wa jọ kuro lãrin awọn keferi, lati ma fi ọpẹ fun orukọ mimọ́ rẹ, ati lati ma ṣogo ninu iyìn rẹ.
48Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lati aiyeraiye: ki gbogbo enia ki o si ma wipe, Amin. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
Currently Selected:
O. Daf 106: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.