O. Daf 105
105
Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀
1Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa? ẹ pè orukọ rẹ̀: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.
2Ẹ kọrin si i, ẹ kọ orin mimọ́ si i: ẹ ma sọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ̀ gbogbo.
3Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki aiya awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀.
4Ẹ ma wá Oluwa ati ipá rẹ̀: ẹ ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo.
5Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe; iṣẹ àmi rẹ̀ ati idajọ ẹnu rẹ̀;
6Ẹnyin iru-ọmọ Abrahamu iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu, ayanfẹ rẹ̀.
7Oluwa, on li Ọlọrun wa: idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye.
8O ti ranti majẹmu rẹ̀ lailai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran.
9Majẹmu ti o ba Abrahamu dá, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki;
10O si gbé eyi na kalẹ li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye.
11Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.
12Nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitõtọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀.
13Nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran;
14On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: Nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn;
15Pe, Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi,
16Pẹlupẹlu o pè ìyan wá si ilẹ na: o ṣẹ́ gbogbo ọpá onjẹ.
17O rán ọkunrin kan lọ siwaju wọn; ani Josefu ti a tà li ẹrú:
18Ẹsẹ ẹniti nwọn fi ṣẹkẹṣẹkẹ pa lara: a dè e ninu irin:
19Titi igba ti ọ̀rọ rẹ̀ de: ọ̀rọ Oluwa dan a wò.
20Ọba ranṣẹ, nwọn si tú u silẹ; ani ijoye awọn enia, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.
21O fi jẹ oluwa ile rẹ̀, ati ijoye gbogbo ini rẹ̀.
22Lati ma ṣe akoso awọn ọmọ-alade rẹ̀ nipa ifẹ rẹ̀; ati lati ma kọ́ awọn igbimọ rẹ̀ li ọgbọ́n.
23Israeli si wá si Egipti pẹlu; Jakobu si ṣe atipo ni ilẹ Hamu.
24O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ.
25O yi wọn li aiya pada lati korira awọn enia rẹ̀, lati ṣe arekereke si awọn iranṣẹ rẹ̀.
26O rán Mose iranṣẹ rẹ̀; ati Aaroni, ẹniti o ti yàn.
27Nwọn fi ọ̀rọ àmi rẹ̀ hán ninu wọn, ati iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu.
28O rán òkunkun, o si mu u ṣú; nwọn kò si ṣaigbọran si ọ̀rọ rẹ̀.
29O sọ omi wọn di ẹ̀jẹ, o si pa ẹja wọn.
30Ilẹ wọn mu ọ̀pọlọ jade wá li ọ̀pọlọpọ, ni iyẹwu awọn ọba wọn.
31O sọ̀rọ, oniruru eṣinṣin si de, ati ina-aṣọ ni gbogbo agbegbe wọn.
32O fi yinyin fun wọn fun òjo, ati ọwọ iná ni ilẹ wọn.
33O si lu àjara wọn, ati igi ọ̀pọtọ wọn; o si dá igi àgbegbe wọn.
34O sọ̀rọ, eṣú si de ati kokoro li ainiye.
35Nwọn si jẹ gbogbo ewebẹ ilẹ wọn, nwọn si jẹ eso ilẹ wọn run.
36O kọlu gbogbo akọbi pẹlu ni ilẹ wọn, ãyo gbogbo ipa wọn.
37O si mu wọn jade, ti awọn ti fadaka ati wura: kò si si alailera kan ninu ẹ̀ya rẹ̀.
38Inu Egipti dùn nigbati nwọn lọ: nitoriti ẹ̀ru wọn bà wọn.
39O nà awọsanma kan fun ibori; ati iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru.
40Nwọn bère o si mu ẹiyẹ aparo wá, o si fi onjẹ ọrun tẹ wọn lọrun.
41O là apata, omi si tú jade; odò nṣan nibi gbigbẹ.
42Nitoriti o ranti ileri rẹ̀ mimọ́, ati Abrahamu iranṣẹ rẹ̀.
43O si fi ayọ̀ mu awọn enia rẹ̀ jade, ati awọn ayanfẹ rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀:
44O si fi ilẹ awọn keferi fun wọn: nwọn si jogun ère iṣẹ awọn enia na.
45Ki nwọn ki o le ma kiye si aṣẹ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma pa ofin rẹ̀ mọ́. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
Currently Selected:
O. Daf 105: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.