YouVersion Logo
Search Icon

Owe 2

2
Èrè Tó Wà ninu Ọgbọ́n
1ỌMỌ mi, bi iwọ ba fẹ igba ọ̀rọ mi, ki iwọ si pa ofin mi mọ́ pẹlu rẹ.
2Ti iwọ dẹti rẹ silẹ si ọgbọ́n, ti iwọ si fi ọkàn si oye;
3Ani bi iwọ ba nke tọ̀ ìmọ lẹhin, ti iwọ si gbé ohùn rẹ soke fun oye;
4Bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀ bi fadaka, ti iwọ si nwá a kiri bi iṣura ti a pamọ́;
5Nigbana ni iwọ o mọ̀ ibẹ̀ru Oluwa, iwọ o si ri ìmọ Ọlọrun.
6Nitori Oluwa ni ifi ọgbọ́n funni: lati ẹnu rẹ̀ jade ni ìmọ ati oye ti iwá.
7O to igbala jọ fun awọn olododo: on li asà fun awọn ti nrìn dede.
8O pa ipa-ọ̀na idajọ mọ́, o si pa ọ̀na awọn ayanfẹ rẹ̀ mọ́.
9Nigbana ni iwọ o mọ̀ ododo, ati idajọ, ati aiṣegbe; ani, gbogbo ipa-ọ̀na rere.
10Nigbati ọgbọ́n bá wọ̀ inu rẹ lọ, ti ìmọ si dùn mọ ọkàn rẹ;
11Imoye yio pa ọ mọ́, oye yio si ma ṣọ́ ọ:
12Lati gbà ọ li ọwọ ẹni-ibi, li ọwọ ọkunrin ti nsọrọ ayidayida;
13Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun;
14Ẹniti o yọ̀ ni buburu iṣe, ti o ṣe inu-didùn si ayidàyidà awọn enia buburu;
15Ọ̀na ẹniti o wọ́, nwọn si ṣe arekereke ni ipa-ọ̀na wọn:
16Lati gbà ọ li ọwọ ajeji obinrin, ani li ọwọ ajeji obinrin ti nfi ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ pọnni;
17Ẹniti o kọ̀ ọrẹ́ igbà-ewe rẹ̀ silẹ, ti o si gbagbe majẹmu Ọlọrun rẹ̀.
18Nitoripe ile rẹ̀ tẹ̀ sinu ikú, ati ipa-ọ̀na rẹ̀ sọdọ awọn okú.
19Kò si ẹniti o tọ̀ ọ lọ ti o si tun pada sẹhin, bẹ̃ni nwọn kì idé ipa-ọ̀na ìye.
20Ki iwọ ki o le ma rin li ọ̀na enia rere, ki iwọ ki o si pa ọ̀na awọn olododo mọ́.
21Nitoripe ẹni-iduroṣinṣin ni yio joko ni ilẹ na, awọn ti o pé yio si ma wà ninu rẹ̀.
22Ṣugbọn awọn enia buburu li a o ke kuro ni ilẹ aiye, ati awọn olurekọja li a o si fàtu kuro ninu rẹ̀.

Currently Selected:

Owe 2: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy