YouVersion Logo
Search Icon

Owe 1

1
Anfaani Àwọn Owe
1OWE Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli;
2Lati mọ̀ ọgbọ́n ati ẹkọ́; lati mọ̀ ọ̀rọ oye;
3Lati gbà ẹkọ́ ọgbọ́n, ododo, ati idajọ, ati aiṣègbe;
4Lati fi oye fun alaimọ̀kan, lati fun ọdọmọkunrin ni ìmọ ati ironu.
5Ọlọgbọ́n yio gbọ́, yio si ma pọ̀ si i li ẹkọ́; ati ẹni oye yio gba igbimọ̀ ọgbọ́n:
6Lati mọ̀ owe, ati ìtumọ; ọ̀rọ ọgbọ́n, ati ọ̀rọ ikọkọ wọn.
Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́
7Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ; ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọ́n ati ẹkọ́.
8Ọmọ mi, gbọ́ ẹkọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ̀ ofin iya rẹ silẹ:
9Nitoripe awọn ni yio ṣe ade ẹwà fun ori rẹ, ati ọṣọ́ yi ọrùn rẹ ka.
10Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ̀ ba tàn ọ, iwọ má ṣe gbà.
11Bi nwọn wipe, Wá pẹlu wa, jẹ ki a ba fun ẹ̀jẹ, jẹ ki a lugọ ni ikọkọ de alaiṣẹ̀ lainidi.
12Jẹ ki a gbe wọn mì lãye bi isà-okú; ati awọn ẹni-diduroṣinṣin bi awọn ti nlọ sinu iho:
13Awa o ri onirũru ọrọ̀ iyebiye, awa o fi ikogun kún ile wa:
14Dà ipin rẹ pọ̀ mọ arin wa; jẹ ki gbogbo wa ki a jọ ni àpo kan:
15Ọmọ mi, máṣe rìn li ọ̀na pẹlu wọn: fà ẹsẹ rẹ sẹhin kuro ni ipa-ọ̀na wọn.
16Nitori ti ẹsẹ wọn sure si ibi, nwọn si yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ.
17Nitõtọ, lasan li a nà àwọn silẹ li oju ẹiyẹkẹiyẹ.
18Awọn wọnyi si ba fun ẹ̀jẹ ara wọn; nwọn lumọ nikọkọ fun ẹmi ara wọn.
19Bẹ̃ni ọ̀na gbogbo awọn ti nṣe ojukokoro ère; ti ngba ẹmi awọn oluwa ohun na.
Ọgbọ́n Ń pè
20Ọgbọ́n nkigbe lode; o nfọhùn rẹ̀ ni igboro:
21O nke ni ibi pataki apejọ, ni gbangba ẹnubode ilu, o sọ ọ̀rọ rẹ̀ wipe,
22Yio ti pẹ tó, ẹnyin alaimọ̀kan ti ẹnyin o fi ma fẹ aimọ̀kan? ati ti awọn ẹlẹgàn yio fi ma ṣe inudidùn ninu ẹ̀gan wọn, ati ti awọn aṣiwere yio fi ma korira ìmọ?
23Ẹ yipada ni ibawi mi; kiyesi i, emi o dà ẹmi mi sinu nyin, emi o fi ọ̀rọ mi hàn fun nyin.
24Nitori ti emi pè, ti ẹnyin si kọ̀; ti emi nà ọwọ mi, ti ẹnikan kò si kà a si:
25Ṣugbọn ẹnyin ti ṣá gbogbo ìgbimọ mi tì, ẹnyin kò si fẹ ibawi mi:
26Emi pẹlu o rẹrin idãmu nyin; emi o ṣe ẹ̀fẹ nigbati ibẹ̀ru nyin ba de;
27Nigbati ibẹ̀ru nyin ba de bi ìji, ati idãmu nyin bi afẹyika-ìji; nigbati wahala ati àrodun ba de si nyin.
28Nigbana ni ẹnyin o kepè mi, ṣugbọn emi kì yio dahùn; nwọn o ṣafẹri mi ni kùtukùtu, ṣugbọn nwọn kì yio ri mi:
29Nitori ti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa.
30Nwọn kò fẹ ìgbimọ mi: nwọn gàn gbogbo ibawi mi.
31Nitorina ni nwọn o ṣe ma jẹ ninu ère ìwa ara wọn, nwọn o si kún fun ìmọkimọ wọn.
32Nitoripe irọra awọn alaimọ̀kan ni yio pa wọn, ati alafia awọn aṣiwere ni yio pa wọn run.
33Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fetisi mi yio ma gbe lailewu, yio si farabalẹ kuro ninu ibẹ̀ru ibi.

Currently Selected:

Owe 1: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy