YouVersion Logo
Search Icon

Ẹk. Jer 3:22-33

Ẹk. Jer 3:22-33 YBCV

Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀. Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀. O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa. O dara fun ọkunrin, ki o gbe àjaga ni igba-ewe rẹ̀. Ki o joko on nikan, ki o si dakẹ, nitori Ọlọrun ti gbe e le ori rẹ̀. Ki o fi ẹnu rẹ̀ sinu ẽkuru; pe bọya ireti le wà: Ki o fi ẹ̀rẹkẹ fun ẹniti o lù u; ki o kún fun ẹ̀gan patapata. Nitoriti Oluwa kì yio ṣá ni tì lailai: Bi o tilẹ mu ibanujẹ wá, sibẹ on o ni irọnu gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. Nitori on kì ifẹ ipọn-ni-loju lati ọkàn rẹ̀ wá, bẹ̃ni kì ibà ọmọ enia ninu jẹ.