YouVersion Logo
Search Icon

Ẹk. Jer 3

3
Ìjìyà, Ìrònúpìwàdà ati Ìrètí
1EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀.
2O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ.
3Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo.
4O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi.
5O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka.
6O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ.
7O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo.
8Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ.
9O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po.
10On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ.
11O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro.
12O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀.
13O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ.
14Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ.
15O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala.
16O ti fi ọta ṣẹ́ ehín mi, o tẹ̀ mi mọlẹ ninu ẽru.
17Iwọ si ti mu ọkàn mi jina réré si alafia; emi gbagbe rere.
18Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa.
19Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro.
20Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi.
21Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti.
22Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin.
23Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ.
24Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀.
25Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀.
26O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa.
27O dara fun ọkunrin, ki o gbe àjaga ni igba-ewe rẹ̀.
28Ki o joko on nikan, ki o si dakẹ, nitori Ọlọrun ti gbe e le ori rẹ̀.
29Ki o fi ẹnu rẹ̀ sinu ẽkuru; pe bọya ireti le wà:
30Ki o fi ẹ̀rẹkẹ fun ẹniti o lù u; ki o kún fun ẹ̀gan patapata.
31Nitoriti Oluwa kì yio ṣá ni tì lailai:
32Bi o tilẹ mu ibanujẹ wá, sibẹ on o ni irọnu gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀.
33Nitori on kì ifẹ ipọn-ni-loju lati ọkàn rẹ̀ wá, bẹ̃ni kì ibà ọmọ enia ninu jẹ.
34Lati tẹ̀ gbogbo ara-tubu ilẹ-aiye mọlẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀.
35Lati yi ẹ̀tọ enia sapakan niwaju Ọga-ogo julọ.
36Lati yi ọ̀ran idajọ enia pada, Oluwa kò fẹ ri i?
37Tali ẹniti iwi, ti isi iṣẹ, nigbati Oluwa kò paṣẹ rẹ̀.
38Ibi ati rere kò ha njade lati ẹnu Ọga-ogo-julọ wá?
39Ẽṣe ti enia alãye nkùn? ti o wà lãye, ki olukuluku ki o kùn nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀!
40Jẹ ki a wádi, ki a si dán ọ̀na wa wò, ki a si tun yipada si Oluwa.
41Jẹ ki a gbe ọkàn ati ọwọ wa soke si Ọlọrun li ọrun.
42Awa ti dẹṣẹ, a si ti ṣọtẹ: iwọ kò ti dariji.
43Iwọ ti fi ibinu bora, o si ṣe inunibini si wa: iwọ ti pa, o kò si ti dasi.
44Iwọ ti fi awọsanma bo ara rẹ, ki adura má le là kọja.
45Iwọ ti ṣe wa bi idarọ ati ohun alainilãri li ãrin awọn orilẹ-ède.
46Gbogbo awọn ọta wa ti ya ẹnu wọn si wa.
47Ẹ̀ru ati ọ̀fin wá sori wa, idahoro ati iparun.
48Oju mi fi odò omi ṣan silẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi.
49Oju mi dà silẹ ni omije, kò si dá, laiṣe isimi.
50Titi Oluwa fi wò ilẹ, ti o wò lati ọrun wá,
51Oju mi npọn ọkàn mi loju, nitori gbogbo awọn ọmọbinrin ilu mi.
52Awọn ọta mi dẹkùn fun mi gidigidi, gẹgẹ bi fun ẹiyẹ laini idi.
53Nwọn ti ke ẹmi mi kuro ninu iho, nwọn si yi okuta sori mi.
54Nwọn mu omi ṣan lori mi; emi wipe, Mo gbe!
55Emi kepe orukọ rẹ, Oluwa, lati iho jijin wá.
56Iwọ ti gbọ́ ohùn mi: máṣe se eti rẹ mọ si imikanlẹ mi, si igbe mi.
57Iwọ sunmọ itosi li ọjọ ti emi kigbe pè ọ: iwọ wipe: Má bẹ̀ru!
58Oluwa, iwọ ti gba ijà mi jà; iwọ ti rà ẹmi mi pada.
59Oluwa, iwọ ti ri inilara mi, ṣe idajọ ọran mi!
60Iwọ ti ri gbogbo igbẹsan wọn, gbogbo èro buburu wọn si mi.
61Iwọ ti gbọ́ ẹ̀gan wọn, Oluwa, gbogbo èro buburu wọn si mi.
62Ète awọn wọnni ti o dide si mi, ati ipinnu wọn si mi ni gbogbo ọjọ.
63Kiyesi ijoko wọn ati idide wọn! emi ni orin-ẹsin wọn.
64San ẹsan fun wọn, Oluwa, gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn!
65Fun wọn ni ifọju ọkàn, ègun rẹ lori wọn!
66Fi ibinu lepa wọn, ki o si pa wọn run kuro labẹ ọrun Oluwa!

Currently Selected:

Ẹk. Jer 3: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in