Job 34
34
1PẸLUPẸLU Elihu dahùn o si wipe,
2Ẹnyin ọlọgbọ́n, ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi, ki ẹ si dẹtisilẹ si mi, ẹnyin ti ẹ ni ìmoye.
3Nitoripe eti a ma dán ọ̀rọ wò, bi adùn ẹnu ti itọ onjẹ wò.
4Ẹ jẹ ki a ṣà idajọ yàn fun ara wa; ẹ jẹ ki a mọ̀ ohun ti o dara larin wa.
5Nitoripe Jobu wipe, Olododo li emi; Ọlọrun si ti gbà idajọ mi lọ.
6Emi ha lè ipurọ si itọsí mi bi, ọfa mi kò ni awọtan, laiṣẹ ni.
7Ọkunrin wo li o dabi Jobu, ti nmu ẹ̀gan bi ẹni mu omi.
8Ti mba awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ kẹgbẹ, ti o si mba awọn enia buburu rin.
9Nitori o sa ti wipe, Ère kan kò si fun enia, ti yio fi ma ṣe inu didun si Ọlọrun,
10Njẹ nitorina, ẹ fetisilẹ si mi, ẹnyin enia amoye: odõdi fun Ọlọrun ti iba fi huwa buburu, ati fun Olodumare, ti yio fi ṣe aiṣedede!
11Nitoripe ẹsan iṣẹ enia ni yio san fun u, yio si mu olukuluku ki o ri gẹgẹ bi ipa-ọ̀na rẹ̀.
12Nitõtọ Ọlọrun kì yio hùwakiwa, bẹ̃ni Olodumare kì yio yi idajọ po.
13Tani o fi itọju aiye lé e lọwọ, tabi tali o to gbogbo aiye lẹsẹlẹsẹ?
14Bi o ba gbe aiya rẹ̀ le kiki ara rẹ̀, ti o si gba ọkàn rẹ̀ ati ẹmi rẹ̀ sọdọ ara rẹ̀,
15Gbogbo enia ni yio parun pọ̀, enia a si tun pada di erupẹ.
16Njẹ nisisiyi, bi iwọ ba ni oye, gbọ́ eyi, fetisi ohùn ẹnu mi.
17Ẹniti o korira otitọ le iṣe olori bi? iwọ o ha si da olõtọ-ntọ̀ lẹbi?
18O ha tọ́ lati wi fun ọba pe, Enia buburu ni iwọ, tabi fun awọn ọmọ-alade pe, Alaimọ-lọrun li ẹnyin?
19Ambọtori fun ẹniti kì iṣojuṣaju awọn ọmọ-alade, tabi ti kò kà ọlọrọ̀ si jù talaka lọ, nitoripe iṣẹ ọwọ rẹ̀ ni gbogbo wọn iṣe.
20Ni iṣẹju kan ni nwọn o kú, awọn enia a si di yiyọ lẹnu larin ọganjọ, nwọn a si kọja lọ; a si mu awọn alagbara kuro laifi ọwọ́ ṣe.
21Nitoripe oju rẹ̀ mbẹ ni ipa-ọ̀na enia, on si ri irin rẹ̀ gbogbo.
22Kò si òkunkun, tabi ojiji ikú, nibiti awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio gbe sapamọ si.
23Nitoripe on kò pẹ ati kiyesi ẹnikan, ki on ki o si mu u lọ sinu idajọ niwaju Ọlọrun.
24On o fọ awọn alagbara tútu laini-iwadi, a si fi ẹlomiran dipo wọn,
25Nitoripe o mọ̀ iṣẹ wọn, o si yi wọn po di oru, bẹ̃ni nwọn di itẹrẹ́ pọ̀.
26O kọlu wọn bi enia buburu, nibiti awọn ẹlomiran ri i.
27Nitorina ni nwọn pada kẹhinda si i, nwọn kò si ti fiyesi ipa-ọ̀na rẹ̀ gbogbo.
28Ki nwọn ki o si mu igbe ẹkún awọn talaka lọ de ọdọ rẹ̀, on si gbọ́ igbe ẹkún olupọnju.
29Nigbati o ba fun ni ni irọra, tani yio da a lẹbi, nigbati o ba pa oju rẹ̀ mọ, tani yio le iri i? bẹ̃ni o ṣe e si orilẹ-ède tabi si enia kanṣoṣo.
30Ki agabagebe ki o má ba jọba, ki nwọn ki o má di idẹwo fun enia.
31Nitoripe ẹnikan ha le wi fun Ọlọrun pe, emi jiya laiṣẹ̀?
32Eyi ti emi kò ri, iwọ fi kọ́ mi, bi mo ba si dẹṣẹ, emi kì yio ṣe bẹ̃ mọ́.
33Iṣe bi ti inu rẹ pe, on o san ẹ̀san pada? njẹ on yio san a pada, iwọ iba kọ̀ ọ tabi iwọ iba fẹ ẹ, kì iṣe emi, pẹlupẹlu kili iwọ mọ̀, sọ ọ!
34Awọn enia amoye yio wi fun mi, ati pẹlupẹlu ẹnikẹni ti nṣe ọlọgbọ́n, ti o si gbọ́ mi.
35Jobu ti fi aimọ̀ sọ̀rọ, ọ̀rọ rẹ̀ si ṣe alaigbọ́n.
36Ifẹ mi ni ki a dán Jobu wò de opin, nitori idahùn rẹ̀ nipa ọ̀na enia buburu;
37Nitoripe o fi iṣọtẹ kún ẹ̀ṣẹ rẹ̀, o papẹ́ li awujọ wa, o si sọ ọ̀rọ pupọ si Ọlọrun.
Currently Selected:
Job 34: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.