YouVersion Logo
Search Icon

Job 33

33
1NJẸ nitorina, Jobu, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ mi, ki o si fetisi ọ̀rọ mi!
2Kiyesi i nisisiyi, emi ya ẹnu mi, ahọn mi si sọ̀rọ li ẹnu mi.
3Ọ̀rọ mi yio si jasi iduroṣinṣin ọkàn mi, ete mi yio si sọ ìmọ mi jade dajudaju.
4Ẹmi Ọlọrun li o ti da mi, ati imisi Olodumare li o ti fun mi ni ìye.
5Bi iwọ ba le da mi lohùn, tò ọ̀rọ rẹ lẹsẹsẹ niwaju mi, dide duro!
6Kiyesi i, bi iwọ jẹ ti Ọlọrun, bẹ̃li emi na; lati erupẹ wá ni a si ti dá mi pẹlu.
7Kiyesi i, ẹ̀ru nla mi kì yio bà ọ, bẹ̃li ọwọ mi kì yio wuwo si ọ lara.
8Nitõtọ iwọ sọ li eti mi, emi si gbọ́ ọ̀rọ rẹ wipe,
9Emi mọ́, laini irekọja, alaiṣẹ li emi, bẹ̃li aiṣedede kò si li ọwọ mi.
10Kiyesi i, ẹ̀fẹ li o fẹ si mi, o kà mi si ọ̀ta rẹ̀.
11O kàn ẹsẹ mi sinu àba, o kiyesi ipa-irin mi gbogbo.
12Kiyesi i, ninu eyi iwọ ṣìna! emi o da ọ lohùn pe: Ọlọrun tobi jù enia lọ!
13Nitori kini iwọ ṣe mba a jà pe: on kì isọrọ̀kọrọ kan nitori iṣẹ rẹ̀?
14Nitoripe Ọlọrun sọ̀rọ lẹkan, ani lẹkeji ṣugbọn enia kò roye rẹ̀.
15Ninu àla, li ojuran oru, nigbati orun ìjika ba kùn enia lọ, ni isunyẹ lori bùsun.
16Nigbana ni iṣi eti enia, a si fi èdidi di ẹkọ wọn.
17Ki o lè ifa enia sẹhin kuro ninu ete rẹ̀, ki o si pa igberaga mọ́ kuro lọdọ enia.
18O si fa ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu iho, ati ẹmi rẹ̀ lati ṣègbe lọwọ idà.
19A si fi irora nà a lori ibùsun rẹ̀, pẹlupẹlu a fi ijà egungun rẹ̀ ti o duro pẹ́, nà a.
20Bẹ̃li ẹmi rẹ̀ kọ̀ onjẹ, ati ọkàn rẹ̀ kọ̀ onjẹ didùn.
21Ẹran ara rẹ̀ rùn, titi a kò si fi lè ri i mọ́; egungun rẹ̀ ti a kò ri, si ta jade.
22Ani ọkàn rẹ̀ sunmọ isa-okú, ati ẹmi rẹ̀ sunmọ ọdọ awọn iranṣẹ ikú.
23Bi onṣẹ kan ba wà lọdọ rẹ̀, ẹniti nṣe alagbawi, ọkan ninu ẹgbẹrun lati fi ọ̀na pipé han ni:
24Nigbana ni o ṣore-ọfẹ fun u, o si wipe, Gbà a kuro ninu ilọ sinu ihò, emi ti ri irapada!
25Ara rẹ̀ yio si já yọ̀yọ̀ jù ti ọmọ kekere, yio si tún pada si ọjọ igba ewe rẹ̀.
26O gbadura sọdọ Ọlọrun, on o si ṣe oju rere si i, o si mu enia ri oju rẹ̀ pẹlu ayọ̀, on o san ododo rẹ̀ pada fun enia.
27O bojuwo enia, bi ẹnikan ba si wipe, Emi ṣẹ̀, mo si ti yi eyi ti o tọ́ po, a kò si sẹsan rẹ̀ fun mi;
28O ti gba ọkàn mi kuro ninu ilọ sinu ihò, ẹmi mi yio si ri imọlẹ!
29Wò o! nkan wọnyi li Ọlọrun imaṣe fun enia nigba meji, ati nigba mẹta,
30Lati mu ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu ihò, lati fi imọlẹ alãyè mọ́ si i.
31Jobu! kiyesi i gidigidi, ki o si fetisilẹ si mi; pa ẹnu rẹ mọ́, emi o si ma sọ!
32Bi iwọ ba si ni ohun iwi, da mi lohùn, mã sọ, nitoripe emi nfẹ da ọ lare.
33Bi bẹ̃ kọ̀, gbọ temi, pa ẹnu rẹ mọ́; emi o si kọ́ ọ li ọgbọ́n.

Currently Selected:

Job 33: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in