YouVersion Logo
Search Icon

Isa 63

63
Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè
1TANI eleyi ti o ti Edomu wá, ti on ti aṣọ arẹpọ́n lati Bosra wá? eyi ti o li ogo ninu aṣọ rẹ̀, ti o nyan ninu titobi agbara rẹ̀? Emi ni ẹniti nsọ̀rọ li ododo, ti o ni ipá lati gbala.
2Nitori kini aṣọ rẹ fi pọ́n, ti aṣọ rẹ wọnni fi dabi ẹniti ntẹ̀ ohun-èlo ifunti waini?
3Emi nikan ti tẹ̀ ohun-elò ifunti waini; ati ninu awọn enia, ẹnikan kò pẹlu mi: nitori emi tẹ̀ wọn ninu ibinu mi, mo si tẹ̀ wọn mọlẹ ninu irunú mi; ẹ̀jẹ wọn si ta si aṣọ mi, mo si ṣe gbogbo ẹ̀wu mi ni abawọ́n.
4Nitori ọjọ ẹsan mbẹ li aiya mi, ọdun awọn ẹni-irapada mi ti de.
5Mo si wò, kò si si oluranlọwọ; ẹnu si yà mi pe kò si olugbéro; nitorina apa ti emi tikalami mu igbala wá sọdọ mi; ati irunú mi, on li o gbe mi ro.
6Emi si tẹ̀ awọn enia mọlẹ ninu ibinu mi, mo si mu wọn mu yó ninu irunú mi, mo si mu ipa wọn sọkalẹ si ilẹ.
Oore OLUWA sí Israẹli
7Emi o sọ ti iṣeun ifẹ Oluwa, iyìn Oluwa gẹgẹ bi gbogbo eyiti Oluwa ti fi fun wa, ati ti ore nla si ile Israeli, ti o ti fi fun wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀, ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ iṣeun ifẹ rẹ̀.
8On si wipe, Lõtọ enia mi ni nwọn, awọn ọmọ ti kì iṣeke: on si di Olugbala wọn.
9Ninu gbogbo ipọnju wọn, oju a pọn ọ, angeli iwaju rẹ̀ si gbà wọn: ninu ifẹ rẹ̀ ati suru rẹ̀ li o rà wọn pada; o si gbe wọn, o si rù wọn ni gbogbo ọjọ igbani.
10Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ, nwọn si bi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ ninu; nitorina li o ṣe pada di ọta wọn, on tikalarẹ̀ si ba wọn ja.
11Nigbana ni o ranti ọjọ atijọ, Mose, awọn enia rẹ̀, wipe, Nibo li ẹniti o mu wọn ti inu okun jade gbe wà, ti on ti olùṣọ agutan ọwọ́-ẹran rẹ̀? nibo li ẹniti o fi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ sinu rẹ̀ gbe wà?
12Ti o fi ọwọ́ ọtun Mose dà wọn, pẹlu apá rẹ̀ ti o logo, ti o npin omi meji niwaju wọn, lati ṣe orukọ aiyeraiye fun ara rẹ̀?
13Ti o mu wọn là ibú ja, bi ẹṣin li aginjù, ki nwọn ki o má ba kọsẹ?
14Gẹgẹ bi ẹran ti isọ̀kalẹ lọ si afonifoji, bẹ̃ni Ẹmi Oluwa mu u simi: bẹ̃ni iwọ tọ́ awọn enia rẹ, lati ṣe orukọ ti o li ogo fun ara rẹ.
Adura fún Àánú ati Ìrànlọ́wọ́
15Wò ilẹ lati ọrun wá, ki o si kiyesi lati ibugbe ìwa mimọ́ rẹ ati ogo rẹ wá: nibo ni itara rẹ ati agbara rẹ, ọ̀pọlọpọ iyanu rẹ, ati ãnu rẹ sọdọ mi gbe wà? a ha da wọn duro bi?
16Laiṣiyemeji iwọ ni baba wa, bi Abrahamu tilẹ ṣe alaimọ̀ wa, ti Israeli kò si jẹwọ wa: iwọ Oluwa, ni baba wa, Olurapada wa; lati aiyeraiye ni orukọ rẹ.
17Oluwa, nitori kili o ṣe mu wa ṣina kuro li ọ̀na rẹ, ti o si sọ ọkàn wa di lile kuro ninu ẹ̀ru rẹ? Yipada nitori awọn iranṣẹ rẹ, awọn ẹya ilẹ ini rẹ.
18Awọn enia mimọ́ rẹ ti ni i, ni igba diẹ: awọn ọta wa ti tẹ̀ ibi mimọ́ rẹ mọlẹ.
19Tirẹ li awa: lati lailai iwọ kò jọba lori wọn, a kò pè orukọ rẹ mọ wọn.

Currently Selected:

Isa 63: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy