YouVersion Logo
Search Icon

Isa 62

62
1NITORI ti Sioni emi kì yio dakẹ, ati nitori ti Jerusalemu emi kì yio simi, titi ododo rẹ̀ yio fi jade bi titan imọlẹ, ati igbala rẹ̀ bi fitila ti njó.
2Ati awọn Keferi yio ri ododo rẹ, ati gbogbo ọba yio ri ogo rẹ: a o si fi orukọ titun pè ọ, eyiti ẹnu Oluwa yio darukọ.
3Iwọ o jẹ ade ogo pẹlu li ọwọ́ Oluwa, ati adé oyè ọba li ọwọ́ Ọlọrun rẹ.
4A ki yio pè ọ ni Ikọ̀silẹ mọ́, bẹ̃ni a ki yio pè ilẹ rẹ ni Ahoro mọ: ṣugbọn a o pè ọ ni Hefsiba: ati ilẹ rẹ ni Beula: nitori inu Oluwa dùn si ọ, a o si gbe ilẹ rẹ ni iyawo.
5Gẹgẹ bi ọdọmọkunrin ti igbé wundia ni iyawo, bẹ̃ni awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio gbe ọ ni iyawo: ati bi ọkọ iyawo ti iyọ̀ si iyawo, bẹ̃ni Ọlọrun rẹ yio yọ̀ si ọ.
6Emi ti fi awọn alore sori odi rẹ, iwọ Jerusalemu, ti kì yio pa ẹnu wọn mọ lọsan ati loru titilai: ẹnyin ti nṣe iranti Oluwa, ẹ máṣe dakẹ.
7Ẹ máṣe fun u ni isimi, titi yio fi fi idi Jerusalemu mulẹ, ti yio ṣe e ni iyìn li aiye.
8Oluwa ti fi apá ọtun rẹ̀, ati apá agbara rẹ̀ bura, Lõtọ emi kì yio fi ọkà rẹ ṣe onjẹ fun awọn ọta rẹ mọ, bẹ̃ni awọn ọmọ ajeji kì yio mu ọti-waini rẹ, eyi ti iwọ ti ṣíṣẹ fun.
9Ṣugbọn awọn ti o ṣà a jọ yio jẹ ẹ, nwọn o si yìn Oluwa; ati awọn ti nkó o jọ yio mu u, ninu ãfin mimọ́ mi.
10Ẹ kọja lọ, ẹ kọja li ẹnu bode; tun ọ̀na awọn enia ṣe; kọ bèbe, kọ bèbe opopo; ṣà okuta wọnni kuro, gbe ọpagun ró fun awọn enia.
11Kiyesi i, Oluwa ti kede titi de opin aiye: Ẹ wi fun ọmọbinrin Sioni pe, Wo o, igbala rẹ de; wo o, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ati ẹsan rẹ̀ niwaju rẹ̀.
12A o si ma pè wọn ni, Enia mimọ́, Ẹni-irapada Oluwa: a o si ma pè ọ ni, Iwári, Ilu aikọ̀silẹ.

Currently Selected:

Isa 62: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy