Esek 16
16
1Ọ̀RỌ Oluwa tún tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, jẹ ki Jerusalemu mọ̀ ohun irira rẹ̀.
3Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi si Jerusalemu; Ibi rẹ ati ilẹ ibi rẹ ni ati ilẹ Kenaani wá; ará Amori ni baba rẹ, ará Hiti si ni iyá rẹ.
4Ati niti ìbi rẹ, a kò da ọ ni iwọ́ ni ijọ ti a bi ọ, bẹ̃ni a kò wẹ̀ ọ ninu omi lati mu ọ mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ lara rara, bẹ̃ni a kò fi ọja wé ọ rara.
5Kò si oju ti o kãnu fun ọ, lati ṣe ọkan ninu nkan wọnyi fun ọ, lati ṣe iyọnu si ọ; ṣugbọn ninu igbẹ li a gbe ọ sọ si, fun ikorira ara rẹ, ni ijọ ti a bi ọ.
6Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si ri ọ, ti a tẹ̀ ọ mọlẹ ninu ẹjẹ ara rẹ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè: nitõtọ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè.
7Emi ti mu ọ bi si i bi irudi itàna ìgbẹ; iwọ si ti pọ̀ si i, o si ti di nla, iwọ si gbà ohun ọṣọ́ ti o ti inu ọṣọ́ wá: a ṣe ọmú rẹ yọ, irun rẹ si dagba, nigbati o jẹ pe iwọ ti wà nihoho ti o si wà goloto.
8Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si wò ọ; kiye si i, ìgba rẹ jẹ ìgba ifẹ; mo si nà aṣọ mi bò ọ, mo si bo ihoho rẹ: nitõtọ, mo bura fun ọ, mo si ba ọ da majẹmu, ni Oluwa Ọlọrun wi, iwọ si di temi.
9Nigbana ni mo fi omi wẹ̀ ọ; nitõtọ, mo wẹ ẹjẹ rẹ kuro lara rẹ patapata, mo si fi ororo kùn ọ lara.
10Mo wọ̀ ọ laṣọ oniṣẹ-ọnà pẹlu, mo si fi awọ̀ badgeri wọ̀ ọ ni bàta, mo si fi aṣọ ọ̀gbọ daradara di ọ ni amure yika, mo si fi aṣọ ṣẹ́dà bò ọ.
11Mo fi ohun-ọṣọ ṣe ọ lọṣọ pẹlu, mo si fi júfu bọ̀ ọ lọwọ, mo si fi ẹ̀wọn kọ́ ọ li ọrùn.
12Mo si fi oruka si ọ ni imú, mo si fi oruka bọ̀ ọ leti, mo si fi ade daradara de ọ lori.
13Bayi ni a fi wura ati fadaka ṣe ọ lọṣọ; aṣọ rẹ si jẹ ọgbọ̀ daradara, ati ṣẹ́dà, ati aṣọ oniṣẹ-ọnà; iwọ jẹ iyẹfun daradara ati oyin, ati ororo: iwọ si ni ẹwà gidigidi, iwọ si gbilẹ di ijọba kan.
14Okiki rẹ si kan lãrin awọn keferi nitori ẹwà rẹ: nitori iwọ pé nipa ẹwà mi, ti mo fi si ọ lara, ni Oluwa Ọlọrun wi.
15Ṣugbọn iwọ gbẹkẹle ẹwà ara rẹ, o si huwa panṣaga nitori okìki rẹ, o si dà gbogbo agbere rẹ sori olukuluku ẹniti nkọja: tirẹ̀ ni.
16Iwọ si mu ninu ẹwù rẹ, iwọ si fi aṣọ alaràbarà ṣe ibi giga rẹ lọṣọ, o si hùwa panṣaga nibẹ: iru nkan bẹ̃ kì yio de, bẹ̃ni kì yio ri bẹ̃.
17Iwọ si mu ohun ọṣọ́ ẹlẹwà rẹ ninu wura mi, ati ninu fadaka mi, ti mo ti fun ọ, iwọ si ṣe àworán ọkunrin fun ara rẹ, o si fi wọn ṣe panṣaga,
18Iwọ si mu ẹwù oniṣẹ-ọnà rẹ, o si fi bò wọn: iwọ si gbe ororo mi ati turari mi kalẹ niwaju wọn.
19Onjẹ mi pẹlu ti mo ti fun ọ, iyẹfun daradara, ati ororo, ati oyin, ti mo fi bọ́ ọ, iwọ tilẹ gbe e kalẹ niwaju wọn fun õrùn didùn: bayi li o si ri, ni Oluwa Ọlọrun wi.
20Pẹlupẹlu iwọ ti mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ti iwọ ti bi fun mi, awọn wọnyi ni iwọ si ti fi rubọ si wọn lati jẹ. Ohun kekere ha ni eyi ninu ìwa panṣaga rẹ,
21Ti iwọ ti pa awọn ọmọ mi, ti o si fi wọn fun ni lati mu wọn kọja lãrin iná fun wọn?
22Ati ni gbogbo ohun irira rẹ, ati panṣaga rẹ, iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, nigbati iwọ wà nihoho ti o si wà goloto, ti a si bà ọ jẹ ninu ẹjẹ rẹ.
23O si ṣe lẹhin gbogbo ìwa buburu rẹ, (Egbe, egbe ni fun ọ! ni Oluwa Ọlọrun wi;)
24Ti iwọ si kọ́ ile giga fun ara rẹ, ti iwọ si ṣe ibi giga ni gbogbo ita fun ara rẹ.
25Iwọ ti kọ́ ibi giga rẹ ni gbogbo ikórita, o si ti sọ ẹwà rẹ di ikorira, o si ti ya ẹsẹ rẹ si gbogbo awọn ti nkọja, o si sọ panṣaga rẹ di pupọ.
26Iwọ ti ba awọn ara Egipti aladugbo rẹ, ti o sanra ṣe agbere, o si ti sọ panṣaga rẹ di pupọ, lati mu mi binu.
27Kiye si i, emi si ti nawọ mi le ọ lori, mo si ti bu onjẹ rẹ kù, mo si fi ọ fun ifẹ awọn ti o korira rẹ, awọn ọmọbinrin Filistia, ti ìwa ifẹkufẹ rẹ tì loju.
28Iwọ ti ba awọn ara Assiria ṣe panṣaga pẹlu, nitori iwọ kò ni itẹlọrun; nitotọ, iwọ ti ba wọn ṣe panṣaga, sibẹsibẹ kò si le tẹ́ ọ lọrùn,
29Iwọ si ti sọ agbere rẹ di pupọ lati ilẹ Kenaani de Kaldea; sibẹsibẹ eyi kò si tẹ́ ọ lọrun nihinyi.
30Oluwa Ọlọrun wipe, aiyà rẹ ti ṣe alailera to, ti iwọ nṣe nkan wọnyi, iṣe agídi panṣaga obinrin;
31Nitipe iwọ kọ́ ile giga rẹ ni gbogbo ikoríta, ti o si ṣe ibi giga rẹ ni gbogbo ita; iwọ kò si wa dabi panṣaga obinrin, nitipe iwọ gan ọ̀ya.
32Ṣugbọn gẹgẹ bi aya ti o ṣe panṣaga, ti o gbà alejo dipo ọkọ rẹ̀!
33Nwọn nfi ẹbùn fun gbogbo awọn panṣaga, ṣugbọn iwọ fi ẹbùn rẹ fun gbogbo awọn olufẹ rẹ, iwọ si ta wọn lọrẹ, ki nwọn le tọ̀ ọ wá ni ihà gbogbo fun panṣaga rẹ.
34Eyiti o yatọ si ti awọn obinrin miran si mbẹ ninu rẹ, ninu panṣaga rẹ, ti ẹnikan kò tẹ̀le ọ lati ṣe panṣaga: ati nitipe iwọ ntọrẹ, ti a kò si tọrẹ fun ọ nitorina iwọ yatọ.
35Nitorina, iwọ panṣaga, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:
36Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti a dà ẹgbin rẹ jade, ti a si ri ihoho rẹ nipa panṣaga rẹ pẹlu awọn olufẹ rẹ, ati pẹlu gbogbo oriṣa irira rẹ, ati nipa ẹjẹ awọn ọmọ rẹ, ti iwọ fi fun wọn:
37Si kiye si i, Emi o kó gbogbo awọn olufẹ rẹ jọ, awọn ẹniti iwọ ti ba jaiye, ati gbogbo awọn ti iwọ ti fẹ, pẹlu gbogbo awọn ti iwọ ti korira; ani emi o gbá wọn jọ kakiri si ọ, emi o si fi ihoho rẹ hàn wọn, ki nwọn ki o le ri gbogbo ihoho rẹ.
38Emi o si dá ọ lẹjọ, gẹgẹ bi a ti da awọn obinrin lẹjọ ti o ba igbeyawo jẹ ti nwọn si ta ẹjẹ silẹ; emi o si fi ẹjẹ fun ọ, ni irúnu ati ni ijowu.
39Emi o si fi ọ le wọn lọwọ pẹlu, nwọn o si wo ibi giga rẹ, nwọn o si wo ibi giga rẹ palẹ: nwọn o si bọ aṣọ rẹ pẹlu, nwọn o si gbà ohun ọṣọ rẹ didara, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho, ati ni goloto.
40Nwọn o mu ẹgbẹ́ kan wá si ọ pẹlu, nwọn o si sọ ọ li okuta, nwọn o si fi idà wọn gún ọ yọ.
41Nwọn o si fi iná kun gbogbo ile rẹ; nwọn o si mu idajọ ṣẹ si ọ lara niwaju obinrin pupọ; emi o si jẹ ki o fi panṣaga rẹ mọ, iwọ pẹlu kì yio si funni ni ọ̀ya mọ.
42Bẹ̃ni emi o jẹ ki irúnu mi si ọ ki o dá, owú mi yio si kuro lọdọ rẹ, emi o si dakẹjẹ, emi kì yio binu mọ.
43Nitoripe iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, ṣugbọn o si mu mi kanra ninu gbogbo nkan wọnyi; si kiye si i, nitorina emi pẹlu o san ẹsan ọ̀na rẹ si ọ lori, ni Oluwa Ọlọrun wi: iwọ kì yio si ṣe ifẹkufẹ yi lori gbogbo ohun irira rẹ mọ.
44Kiyesi i, olukuluku ẹniti npowe ni yio powe yi si ọ, wipe, Bi iyá ti ri, bẹ̃ni ọmọ rẹ̀ obinrin.
45Iwọ ni ọmọ iyá rẹ ti o kọ̀ ọkọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀; iwọ ni arabinrin awọn arabinrin rẹ, ti o kọ̀ awọn ọkọ wọn ati awọn ọmọ wọn: ará Hiti ni iyá rẹ, ará Amori si ni baba rẹ.
46Ẹgbọn rẹ obinrin si ni Samaria, on ati awọn ọmọbinrin rẹ ti ngbe ọwọ́ osì rẹ: ati aburo rẹ obinrin ti ngbe ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.
47Ṣugbọn iwọ kò rin ni ọ̀na wọn, iwọ kò si ṣe gẹgẹ bi irira wọn: ṣugbọn, bi ẹnipe ohun kekere ni eyini, iwọ bajẹ jù wọn lọ ni gbogbo ọ̀na rẹ.
48Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, Sodomu arabinrin rẹ, on, tabi awọn ọmọ rẹ̀ obinrin kò ṣe gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin.
49Kiyesi i, ẹ̀ṣẹ Sodomu arabinrin rẹ niyi, irera, onjẹ ajẹyo, ati ọ̀pọlọpọ orayè wà ninu rẹ̀, ati ninu awọn ọmọ rẹ̀ obinrin; bẹ̃ni on kò mu ọwọ́ talaka ati alaini lokun.
50Nwọn si gberaga, nwọn si ṣe ohun irira niwaju mi: nitorina ni mo mu wọn kuro gẹgẹ bi mo ti ri pe o dara.
51Bẹ̃ni Samaria kò dá abọ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ: ṣugbọn iwọ sọ ohun irira rẹ di pupọ jù wọn lọ, o si ti da awọn arabinrin rẹ lare ninu gbogbo ohun irira rẹ ti iwọ ti ṣe.
52Iwọ pẹlu, ti o ti da awọn arabinrin rẹ lẹbi, ru itiju ara rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ ti iwọ ti ṣe ni iṣe irira jù wọn lọ: awọn ṣe olododo jù iwọ lọ; nitotọ, ki iwọ ki o dãmu pẹlu, si ru itiju rẹ, nitipe iwọ dá awọn arabinrin rẹ lare.
53Nigbati mo ba tun mu igbèkun wọn wá, igbèkun Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, pẹlu igbèkun Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nigbana li emi o tun mu igbèkun awọn onde rẹ wá lãrin wọn:
54Ki iwọ ki o le ru itiju ara rẹ, ki o si le dãmu ni gbogbo eyi ti o ti ṣe, nitipe iwọ jẹ itunu fun wọn.
55Nigbati awọn arabinrin rẹ Sodomu, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ba pada si ipò wọn iṣaju, ti Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin ba pada si ipò wọn iṣaju, nigbana ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin yio pada si ipò nyin iṣaju.
56Nitori ẹnu rẹ kò da orukọ Sodomu arabinrin rẹ li ọjọ irera rẹ,
57Ki a to ri ìwa buburu rẹ, bi akoko ti awọn ọmọbinrin Siria gàn ọ, ati gbogbo awọn ti o wà yi i ka, awọn ọmọbinrin Filistia ti o gàn ọ ka kiri.
58Iwọ ti ru ifẹkufẹ rẹ ati ohun irira rẹ, ni Oluwa wi.
59Nitori bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Emi o tilẹ ba ọ lò gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, ti iwọ ti gàn ibura nipa biba majẹmu jẹ.
60Ṣugbọn emi o ranti majẹmu mi pẹlu rẹ, ni ọjọ ewe rẹ, emi o si gbe majẹmu aiyeraiye kalẹ fun ọ.
61Iwọ o si ranti ọ̀na rẹ, oju o si tì ọ, nigbati iwọ ba gba awọn arabinrin rẹ, ẹgbọ́n rẹ ati aburò rẹ: emi o si fi wọn fun ọ bi ọmọbinrin, ṣugbọn ki iṣe nipa majẹmu rẹ.
62Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ pẹlu rẹ; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
63Ki iwọ ki o le ranti, ki o si le dãmu, ki iwọ ki o má si le yà ẹnu rẹ mọ nitori itiju rẹ, nigbati inu mi ba tutù si ọ, nitori ohun ti iwọ ti ṣe, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Currently Selected:
Esek 16: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.