YouVersion Logo
Search Icon

Esek 17

17
1Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, pa alọ́ kan, si pa owe kan fun ile Israeli;
3Si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Idì nla kan, pẹlu apá nla, alapá gigùn, o kún fun iyẹ́; ti o ni àwọ alaràbarà wá si Lebanoni, o si mu ẹka igi Kedari ti o ga julọ.
4O ke ori ọ̀munú ẹka rẹ̀ kuro, o si mu u lọ si ilẹ òwo kan; o gbe e kalẹ ni ilu awọn oniṣòwo.
5O mu ninu irugbìn ilẹ na pẹlu, o si gbìn i sinu oko daradara kan; o fi si ibi omi nla, o si gbe e kalẹ bi igi willo.
6O si dagba, o si di igi àjara ti o bò ti o kuru, ẹka ẹniti o tẹ̀ sọdọ rẹ̀, gbòngbo rẹ̀ si wà labẹ rẹ̀; bẹ̃ni o di ajara, o si pa ẹka, o si yọ ọ̀munú jade.
7Idì nla miran si wà pẹlu apá nla ati iyẹ́ pupọ: si kiye si i, àjara yi tẹ̀ gbòngbo rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si yọ ẹka rẹ̀ sọdọ rẹ̀, ki o le ma b'omi si i ninu aporo ọgbà rẹ̀.
8Ilẹ rere lẹba omi nla ni a gbìn i si, ki o le bà yọ ẹka jade, ki o si le so eso, ki o le jẹ́ àjara rere.
9Wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; yio ha gbà? on kì yio hú gbòngbo rẹ̀, kì yio si ka eso rẹ̀ kuro, ki o le rọ? yio rọ ninu gbogbo ewe rirú rẹ̀, ani laisi agbara nla tabi enia pupọ̀ lati fà a tu pẹlu gbòngbo rẹ̀.
10Nitõtọ, kiye si i, bi a ti gbìn i yi, yio ha gbà? kì yio ha rẹ̀ patapata? nigbati afẹfẹ ilà-õrun ba kàn a? yio rẹ̀ ninu aporo ti o ti hù.
11Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
12Sọ nisisiyi fun ọlọ̀tẹ ile na pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohun ti nkan wọnyi jasi? Sọ fun wọn, kiyesi i, ọba Babiloni de Jerusalemu, o si ti mu ọba ibẹ ati awọn ọmọ-alade ibẹ, o si mu wọn pẹlu rẹ̀ lọ si Babiloni:
13O si ti mu ninu iru-ọmọ ọba, o si bá a dá majẹmu, o si ti mu u bura: o si mu awọn alagbara ilẹ na pẹlu:
14Ki ijọba na le jẹ alailọla, ki o má le gbe ara rẹ̀ soke, ki o le duro nipa pipa majẹmu rẹ̀ mọ.
15Ṣugbọn on ṣọ̀tẹ si i ni rirán awọn ikọ̀ rẹ̀ lọ si Egipti, ki nwọn ki o le fi ẹṣin fun u ati enia pupọ. Yio ha sàn a? ẹniti nṣe iru nkan wọnyi yio ha bọ́? tabi yio dalẹ tan ki o si bọ́?
16Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nitotọ ibi ti ọba ngbe ti o fi i jọba, ibura ẹniti o gàn, majẹmu ẹniti o si bajẹ, ani lọdọ rẹ̀ lãrin Babiloni ni yio kú.
17Bẹ̃ni Farao ti on ti ogun rẹ̀ ti o li agbara ati ẹgbẹ́ nla kì yio ṣe fun u ninu ogun, nipa mimọ odi, ati kikọle iṣọ́ ti o li agbara, lati ke enia pupọ̀ kuro:
18Nitoriti o gàn ibura nipa didalẹ, kiye si i, o ti fi ọwọ́ rẹ̀ fun ni, o si ti ṣe gbogbo nkan wọnyi, kì yio bọ́.
19Nitorina bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi mo ti wà, dajudaju ibura mi ti o ti gàn, ati majẹmu mi ti o ti dà, ani on li emi o san si ori on tikalarẹ̀.
20Emi o si nà àwọn mi si i lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi; emi o si mu u de Babiloni, emi o si ba a rojọ nibẹ, nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti da si mi.
21Ati gbogbo awọn isánsa rẹ̀ pẹlu gbogbo awọn ẹgbẹ́-ogun rẹ̀, ni yio ti oju idà ṣubu; awọn ti o si kù ni a o tuka si gbogbo ẹfũfu: ẹnyin o si mọ̀ pe emi Oluwa li o ti sọ ọ.
22Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ninu ẹka ti o ga jùlọ, ninu igi Kedari giga; emi o si lọ́ ọ, emi o ke ọ̀munú ẹka kan kuro ninu ọ̀munú ẹka rẹ̀; emi o si gbìn i sori oke giga kan ti o si hàn:
23Lori oke giga ti Israeli ni emi o gbìn i si, yio si yọ ẹka; yio si so eso, yio si jẹ igi Kedari daradara; labẹ rẹ̀ ni gbogbo ẹiyẹ oniruru iyẹ́ o si gbe; ninu ojiji ẹka rẹ̀ ni nwọn o gbe.
24Gbogbo igi inu igbẹ ni yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti mu igi giga walẹ, ti mo ti gbe igi rirẹlẹ soke, ti mo ti mu igi tutù gbẹ, ti mo si ti mu igi gbigbẹ ruwé: emi Oluwa li o ti sọ ti mo si ti ṣe e.

Currently Selected:

Esek 17: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in