YouVersion Logo
Search Icon

Efe 6:10-20

Efe 6:10-20 YBCV

Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ̀. Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu. Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmí buburu ni oju ọrun. Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀ ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro. Ẹ duro nitorina lẹhin ti ẹ ti fi àmure otitọ di ẹgbẹ nyin, ti ẹ si ti di ìgbaiya ododo nì mọra; Ti ẹ si ti fi imura ihinrere alafia wọ̀ ẹsẹ nyin ni bàta; Léke gbogbo rẹ̀, ẹ mu apata igbagbọ́, nipa eyiti ẹnyin ó le mã fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi nì. Ki ẹ si mu aṣibori igbala, ati idà Ẹmí, ti iṣe ọ̀rọ Ọlọrun: Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ mã gbadura nigbagbogbo ninu Ẹmí, ki ẹ si mã ṣọra si i ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹ̀bẹ fun gbogbo enia mimọ́; Ati fun mi, ki a le fi ohùn fun mi, ki emi ki o le mã fi igboiya yà ẹnu mi, lati mã fi ohun ijinlẹ ihinrere hàn, Nitori eyiti emi jẹ ikọ̀ ninu ẹ̀wọn: ki emi ki o le mã fi igboiya sọ̀rọ ninu rẹ̀, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ.