YouVersion Logo
Search Icon

Efe 6

6
Ọmọ ati Òbí
1ẸNYIN ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ́.
2Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ (eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri),
3Ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wà pẹ li aiye.
4Ati ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu: ṣugbọn ẹ mã tọ́ wọn ninu ẹkọ́ ati ikilọ Oluwa.
Ẹrú ati Ọ̀gá
5Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ mã gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara, pẹlu ibẹru ati iwarìri, ni otitọ ọkàn nyin, bi ẹnipe si Kristi;
6Ki iṣe ti arojuṣe bi awọn ti nwù enia; ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ẹrú Kristi, ẹ mã ṣe ifẹ Ọlọrun lati inu wá;
7Ẹ mã fi inu rere sin bi si Oluwa, kì si iṣe si enia:
8Bi ẹnyin ti mọ pe ohun rere kohunrere ti olukuluku ba ṣe, on na ni yio si gbà pada lọdọ Oluwa, ibã ṣe ẹrú, tabi omnira.
9Ati ẹnyin oluwa, ẹ mã ṣe ohun kanna si wọn, ẹ mã din ibẹru nyin kù; bi ẹnyin ti mọ pe Oluwa ẹnyin tikaranyin si mbẹ li ọrun; kò si si ojuṣãju enia lọdọ rẹ̀.
Ìjàkadì pẹlu Ibi
10Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ̀.
11Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu.
12Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmí buburu ni oju ọrun.
13Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀ ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro.
14Ẹ duro nitorina lẹhin ti ẹ ti fi àmure otitọ di ẹgbẹ nyin, ti ẹ si ti di ìgbaiya ododo nì mọra;
15Ti ẹ si ti fi imura ihinrere alafia wọ̀ ẹsẹ nyin ni bàta;
16Léke gbogbo rẹ̀, ẹ mu apata igbagbọ́, nipa eyiti ẹnyin ó le mã fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi nì.
17Ki ẹ si mu aṣibori igbala, ati idà Ẹmí, ti iṣe ọ̀rọ Ọlọrun:
18Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ mã gbadura nigbagbogbo ninu Ẹmí, ki ẹ si mã ṣọra si i ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹ̀bẹ fun gbogbo enia mimọ́;
19Ati fun mi, ki a le fi ohùn fun mi, ki emi ki o le mã fi igboiya yà ẹnu mi, lati mã fi ohun ijinlẹ ihinrere hàn,
20Nitori eyiti emi jẹ ikọ̀ ninu ẹ̀wọn: ki emi ki o le mã fi igboiya sọ̀rọ ninu rẹ̀, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ.
Gbolohun Ìparí
21Ṣugbọn ki ẹnyin pẹlu ki o le mọ̀ bi nkan ti ri fun mi, bi mo ti nṣe si, Tikiku arakunrin olufẹ ati iranṣẹ olõtọ ninu Oluwa, yio sọ ohun gbogbo di mimọ̀ fun nyin:
22Ẹniti mo rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹ le mọ bi a ti wà, ki on ki o le tu ọkàn nyin ninu.
23Alafia fun awọn ará, ati ifẹ pẹlu igbagbọ́, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Oluwa Jesu Kristi.
24Ki ore-ọfẹ wà pẹlu gbogbo awọn ti o fẹ Oluwa wa Jesu Kristi li aiṣẹ̀tan.

Currently Selected:

Efe 6: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in