YouVersion Logo
Search Icon

II. Sam 4

4
Wọ́n pa Iṣiboṣẹti
1NIGBATI ọmọ Saulu si gbọ́ pe Abneri kú ni Hebroni, ọwọ́ rẹ̀ si rọ, gbogbo Israeli si rẹ̀wẹsi.
2Ọmọ Saulu si ni ọkunrin meji ti iṣe olori ẹgbẹ ogun: a npe orukọ ọkan ni Baana, ati orukọ keji ni Rekabu, awọn ọmọ Rimmoni ara Beeroti ti awọn ọmọ Benjamini: (nitoripe a si ka Beeroti pẹlu Benjamini:
3Awọn ara Beeroti si ti sa lọ si Gittaimu, nwọn si ṣe atipo nibẹ titi o fi di ọjọ oni yi.)
4Jonatani ọmọ Saulu si ti bi ọmọkunrin kan ti ẹsẹ rẹ̀ rọ. On si jẹ ọdun marun, nigbati ihìn de niti Saulu ati Jonatani lati Jesreeli wá, olutọ́ rẹ̀ si gbe e, o si sa lọ: o si ṣe, bi o si ti nyara lati sa lọ, on si ṣubu, o si ya arọ. Orukọ rẹ̀ a ma jẹ Mefiboṣeti.
5Awọn ọmọ Rimmoni, ara Beeroti, Rekabu ati Baana si lọ, nwọn si wá si ile Iṣboṣeti li ọsangangan, on si dubulẹ lori ibusun kan li ọjọkanri.
6Si wõ, nwọn si wá si arin ile na, nwọn si ṣe bi ẹnipe nwọn nfẹ mu alikama; nwọn si gun u labẹ inu: Rekabu ati Baana arakunrin rẹ̀ si sa lọ.
7Nigbati nwọn wọ ile na lọ, on si dubulẹ lori ibusun rẹ̀ ninu iyẹwu rẹ̀, nwọn si lu u pa, nwọn si bẹ ẹ li ori, nwọn gbe ori rẹ̀, nwọn si fi gbogbo oru rìn ni pẹtẹlẹ na.
8Nwọn si gbe ori Iṣboṣeti tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wi fun ọba pe, Wõ, ori Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọta rẹ, ti o ti nwá ẹmi rẹ kiri; Oluwa ti gbẹ̀san fun ọba oluwa mi loni lara Saulu ati lara iru-ọmọ rẹ̀.
9Dafidi si da Rekabu ati Baana arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Rimmoni ara Beeroti lohùn, o si wi fun wọn pe, Bi Oluwa ti mbẹ, ẹniti o gbà ẹmi mi lọwọ gbogbo ipọnju,
10Nigbati ẹnikan rò fun mi pe, Wõ, Saulu ti kú, li oju ara rẹ̀ on si jasi ẹni ti o mu ihin rere wá, emi si mu u, mo si pa a ni Siklagi, ẹniti o ṣebi on o ri nkan gbà nitori ihin rere rẹ̀.
11Melomelo ni, nigbati awọn ikà enia pa olododo enia kan ni ile rẹ̀ lori ibusun rẹ̀? njẹ emi ha si le ṣe alaibere ẹjẹ rẹ̀ lọwọ nyin bi? ki emi si mu nyin kuro laiye?
12Dafidi si fi aṣẹ fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, nwọn si pa wọn, nwọn si ke ọwọ́ ati ẹṣẹ wọn, a si fi wọn ha lori igi ni Hebroni. Ṣugbọn nwọn mu ori Iṣboṣeti, nwọn si sin i ni iboji Abneri ni Hebroni.

Currently Selected:

II. Sam 4: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in