II. Sam 3
3
1OGUN na si pẹ titi larin idile Saulu ati idile Dafidi: agbara Dafidi si npọ̀ si i, ṣugbọn idile Saulu nrẹ̀hin si i.
2Dafidi si bi ọmọkunrin ni Hebroni: Ammoni li akọbi rẹ̀ ti Ahinoamu ara Jesreeli bi fun u.
3Ekeji rẹ̀ si ni Kileabu, ti Abigaili aya Nabali ara Karmeli nì bi fun u; ẹkẹta si ni Absalomu ọmọ ti Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Geṣuri bi fun u.
4Ẹkẹrin si ni Adonija ọmọ Haggiti; ati ikarun ni Ṣefatia ọmọ Abitali;
5Ẹkẹfa si ni Itreamu, ti Egla aya Dafidi bi fun u. Wọnyi li a bi fun Dafidi ni Hebroni.
Abineri darapọ̀ mọ́ Dafidi
6O si ṣe, nigbati ogun wà larin idile Saulu ati idile Dafidi, Abneri si di alagbara ni idile Saulu.
7Saulu ti ni àle kan, orukọ rẹ̀ si njẹ Rispa, ọmọbinrin Aia: Iṣboṣeti si bi Abneri lere pe, Ẽṣe ti iwọ fi wọle tọ àle baba mi lọ?
8Abneri si binu gidigidi nitori ọ̀rọ wọnyi ti Iṣboṣeti sọ fun u, o si wipe, Emi iṣe ori aja bi? emi ti mo mba Juda jà, ti mo si ṣanu loni fun idile Saulu baba rẹ, ati fun ará rẹ̀, ati awọn ọrẹ rẹ̀, ti emi kò si fi iwọ le Dafidi lọwọ, iwọ si ka ẹ̀ṣẹ si mi lọrùn nitori obinrin yi loni?
9Bẹ̃ni ki Ọlọrun ki o ṣe si Abneri, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi Oluwa ti bura fun Dafidi, bi emi kò ni ṣe bẹ fun u.
10Lati mu ijọba na kuro ni idile Saulu, ati lati gbe itẹ Dafidi kalẹ lori Israeli, ati lori Juda, lati Dani titi o fi de Beerṣeba.
11On kò si le da Abneri lohùn kan nitoriti o bẹ̀ru rẹ̀.
12Abneri si ran awọn oniṣẹ si Dafidi nitori rẹ̀, wipe, Ti tani ilẹ na iṣe? ati pe, Ba mi ṣe adehun, si wõ, ọwọ́ mi o wà pẹlu rẹ, lati yi gbogbo Israeli sọdọ rẹ.
13On si wi pe, O dara, emi o ba ọ ṣe adehun: ṣugbọn nkan kan li emi o bere lọwọ rẹ, eyini ni, Iwọ ki yio ri oju mi, afi bi iwọ ba mu Mikali ọmọbinrin Saulu wá, nigbati iwọ ba mbọ, lati ri oju mi.
14Dafidi si ran awọn iranṣẹ si Iṣboṣeti ọmọ Saulu pe, Fi Mikali obinrin mi le mi lọwọ, ẹniti emi ti fi ọgọrun ẹfa abẹ awọn Filistini fẹ.
15Iṣboṣeti si ranṣẹ, o si gbà a lọwọ ọkunrin ti a npè ni Faltieli ọmọ Laiṣi.
16Ọkọ rẹ̀ si mba a lọ, o nrin, o si nsọkun lẹhin rẹ̀ titi o fi de Bahurimu. Abneri si wi fun u pe, Pada lọ. On si pada.
17Abneri si ba awọn agbà Israeli sọ̀rọ, pe, Ẹnyin ti nṣe afẹri Dafidi ni igbà atijọ́, lati jọba lori nyin.
18Njẹ, ẹ ṣe e: nitoriti Oluwa ti sọ fun Dafidi pe, Lati ọwọ́ Dafidi iranṣẹ mi li emi o gbà Israeli enia mi là kuro lọwọ awọn Filistini ati lọwọ gbogbo awọn ọta wọn.
19Abneri si wi leti Benjamini: Abneri si lọ isọ leti Dafidi ni Hebroni gbogbo eyiti o dara loju Israeli, ati loju gbogbo ile Benjamini.
20Abneri si tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, ogún ọmọkunrin si pẹlu rẹ̀. Dafidi si se ase fun Abneri ati fun awọn ọmọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀.
21Abneri si wi fun Dafidi pe, Emi o dide, emi o si lọ, emi o si ko gbogbo Israeli jọ sọdọ ọba oluwa mi, nwọn o si ba ọ ṣe adehun, iwọ o si jọba gbogbo wọn bi ọkàn rẹ ti nfẹ. Dafidi si rán Abneri lọ; on si lọ li alafia.
Wọ́n pa Abineri
22Si wõ, awọn iranṣẹ Dafidi ati Joabu si ti ibi ilepa ẹgbẹ ogun kan bọ̀, nwọn si mu ikogun pupọ bọ̀; ṣugbọn Abneri ko si lọdọ Dafidi ni Hebroni; nitoriti on ti rán a lọ: on si ti lọ li alafia.
23Nigbati Joabu ati gbogbo ogun ti o pẹlu rẹ̀ si de, nwọn si sọ fun Joabu pe, Abneri, ọmọ Neri ti tọ̀ ọba wá, on si ti rán a lọ, o si ti lọ li alafia.
24Joabu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Kini iwọ ṣe nì? wõ, Abneri tọ̀ ọ wá; ehatiṣe ti iwọ si fi rán a lọ? on si ti lọ.
25Iwọ mọ̀ Abneri ọmọ Neri, pe, o wá lati tàn ọ jẹ, ati lati mọ̀ ijadelọ rẹ, ati ibọsile rẹ, ati lati mọ̀ gbogbo eyi ti iwọ nṣe.
26Nigbati Joabu si jade kuro lọdọ Dafidi, o si ran awọn iranṣẹ lepa Abneri, nwọn si pè e pada lati ibi kanga Sira: Dafidi kò si mọ̀.
27Abneri si pada si Hebroni, Joabu si ba a tẹ̀ larin oju ọ̀na lati ba a sọ̀rọ li alafia, o si gún u nibẹ labẹ inu, o si kú, nitori ẹjẹ Asaheli arakunrin rẹ̀.
28Lẹhin igbati Dafidi si gbọ́ ọ, o si wipe, emi ati ijọba mi si jẹ alaiṣẹ niwaju Oluwa titi lai ni ẹjẹ Abneri ọmọ Neri:
29Jẹ ki o wà li ori Joabu, ati li ori gbogbo idile baba rẹ̀; ki a má si fẹ ẹni ti o li arùn isun, tabi adẹtẹ, tabi ẹni ti ntẹ̀ ọpá, tabi, ẹniti a o fi idà pa, tabi ẹniti o ṣe alaili onjẹ kù ni ile Joabu.
30Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ si pa Abneri, nitoripe on ti pa Asaheli arakunrin wọn ni Gibeoni li ogun.
Wọ́n Sin Òkú Abineri
31Dafidi si wi fun Joabu ati fun gbogbo enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Ẹ fa aṣọ nyin ya, ki ẹnyin ki o si mu aṣọ-ọ̀fọ, ki ẹnyin ki o si sọkun niwaju Abneri. Dafidi ọba tikararẹ̀ si tẹle posi rẹ̀.
32Nwọn si sin Abneri ni Hebroni: ọba si gbe ohùn rẹ̀ soke, o si sọkun ni iboji Abneri; gbogbo awọn enia na si sọkun.
33Ọba si sọkun lori Abneri, o si wipe, Abneri iba ku iku aṣiwere?
34A kò sa dè ọ li ọwọ́, bẹ̃ li a kò si kàn ẹsẹ rẹ li abà: gẹgẹ bi enia iti ṣubu niwaju awọn ikà enia, bẹ̃ni iwọ ṣubu. Gbogbo awọn enia na si tun sọkun lori rẹ̀.
35Nigbati gbogbo enia si wá lati gbà Dafidi ni iyanju ki o jẹun nigbati ọjọ si mbẹ, Dafidi si bura wipe, Bẹ̃ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati ju bẹ̃ lọ, bi emi ba tọ onjẹ wò, tabi nkan miran, titi õrun yio fi wọ̀.
36Gbogbo awọn enia si kiyesi i, o si dara loju wọn: gbogbo eyi ti ọba ṣe si dara loju gbogbo awọn enia na.
37Gbogbo awọn enia na ati gbogbo Israeli si mọ̀ lọjọ na pe, ki iṣe ifẹ ọba lati pa Abneri ọmọ Neri.
38Ọba si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin kò mọ̀ pe olori ati ẹni-nla kan li o ṣubu li oni ni Israeli?
39Emi si ṣe alailagbara loni, bi o tilẹ jẹ pe a fi emi jọba; awọn ọkunrin wọnyi ọmọ Seruia si le jù mi lọ: Oluwa ni yio san a fun ẹni ti o ṣe ibi gẹgẹ bi ìwa buburu rẹ̀.
Currently Selected:
II. Sam 3: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.