II. Sam 18
18
Wọ́n ṣẹgun Absalomu, wọ́n sì Pa á
1DAFIDI si kà awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, o si mu wọn jẹ balogun ẹgbẹgbẹrun, ati balogun ọrọrun lori wọn.
2Dafidi si fi idamẹta awọn enia na le Joabu lọwọ, o si ran wọn lọ, ati idamẹta le Abiṣai ọmọ Seruia aburo Joabu lọwọ, ati idamẹta le Ittai ara Giti lọwọ. Ọba si wi fun awọn enia na pe, nitotọ emi tikara mi o si ba nyin lọ pẹlu.
3Awọn enia na si wipe, Iwọ ki yio ba wa lọ: nitoripe bi awa ba sa, nwọn kì yio nani wa, tabi bi o tilẹ ṣepe idajì wa kú, nwọn ki yio nani wa, nitoripe iwọ nikan to ẹgbãrun wa: nitorina, o si dara ki iwọ ki o ma ràn wa lọwọ lati ilu wá.
4Ọba si wi fun wọn pe, Eyi ti o ba tọ́ loju nyin li emi o ṣe. Ọba si duro li apakan ẹnu odi, gbogbo awọn enia na si jade ni ọ̀rọrún ati ni ẹgbẹgbẹrun.
5Ọba si paṣẹ fun Joabu ati Abiṣai ati Ittai pe, Ẹ tọju ọdọmọkunrin na Absalomu fun mi. Gbogbo awọn enia na si gbọ́ nigbati ọba paṣẹ fun gbogbo awọn balogun nitori Absalomu.
6Awọn enia na si jade lati pade Israeli ni pápá; ni igbó Efraimu ni nwọn gbe pade ijà na.
7Nibẹ li a gbe pa awọn enia Israeli niwaju awọn iranṣẹ Dafidi, ọ̀pọlọpọ enia lo ṣubu li ọjọ na, ani ẹgbãwa enia.
8Ogun na si fọ́n ka kiri lori gbogbo ilẹ na: igbógàn na si pa ọ̀pọ enia jù eyi ti idà pa lọ li ọjọ na.
9Absalomu si pade awọn iranṣẹ Dafidi. Absalomu si gun ori ibaka kan, ibaka na si gba abẹ ẹka nla igi pọ́nhan kan ti o tobi lọ, ori rẹ̀ si kọ́ igi pọ́nhan na, on si rọ̀ soke li agbedemeji ọrun on ilẹ; ibaka na ti o wà labẹ rẹ̀ si lọ kuro.
10Ọkunrin kan si ri i, o si wi fun Joabu pe, Wõ, emi ri Absalomu rọ̀ lãrin igi pọ́nhan kan.
11Joabu si wi fun ọkunrin na ti o sọ fun u pe, Sa wõ, iwọ ri i, eha ti ṣe ti iwọ kò fi lù u bolẹ nibẹ? emi iba si fun ọ ni ṣekeli fadaka mẹwa, ati amure kan.
12Ọkunrin na si wi fun Joabu pe, Biotilẹṣepe emi o gba ẹgbẹrun ṣekeli fadaka si ọwọ́ mi, emi kì yio fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba: nitoripe awa gbọ́ nigbati ọba kilọ fun iwọ ati Abiṣai, ati Ittai, pe, Ẹ kiye si i, ki ẹnikẹni ki o má fi ọwọ́ kan ọdọmọkunrin na Absalomu.
13Bi o ba ṣe bẹ̃ emi iba ṣe ibi si ara mi: nitoripe kò si ọran kan ti o pamọ fun ọba, iwọ tikararẹ iba si kọju ijà si mi pẹlu.
14Joabu si wipe, emi kì yio duro bẹ̃ niwaju rẹ. O si mu ọ̀kọ mẹta lọwọ rẹ̀, o si fi wọn gun Absalomu li ọkàn, nigbati o si wà lãye li agbedemeji igi pọ́nhan na.
15Awọn ọdọmọdekunrin mẹwa ti ima ru ihamọra Joabu si yi Absalomu ka, nwọn si kọlù u, nwọn si pa a.
16Joabu si fún ipè, awọn enia na si yipada ati mã lepa Israeli: nitori Joabu ti pe awọn enia na pada.
17Nwọn si gbe Absalomu, nwọn si sọ ọ sinu iho nla kan ni igbogàn na, nwọn si papó okuta pupọ jọ si i lori, gbogbo Israeli si sa, olukuluku si inu agọ rẹ̀.
18Absalomu li ọjọ aiye rẹ̀ si mu, o si mọ ọwọ̀n kan fun ara rẹ̀, ti mbẹ li afonifoji ọba: nitoriti o wipe, Emi kò ni ọmọkunrin ti yio pa orukọ mi mọ ni iranti: on si pe ọwọ̀n na nipa orukọ rẹ̀: a si npè e titi di oni, ni ọwọ̀n Absalomu.
Wọ́n túfọ̀ ikú Absalomu fún Dafidi
19Ahimaasi ọmọ Sadoku si wipe, Jẹ ki emi ki o sure nisisiyi, ki emi ki o si mu ihìn tọ̀ ọba lọ, bi Oluwa ti gbẹsan rẹ̀ li ara awọn ọta rẹ̀.
20Joabu si wi fun u pe, Iwọ ki yio mu ìhin lọ loni, ṣugbọn iwọ o mu ìhin lọ ni ijọ miran: ṣugbọn loni yi iwọ kì yio mu ìhin kan lọ, nitoriti ọmọ ọba ṣe alaisi.
21Joabu si wi fun Kuṣi pe, Lọ, ki iwọ ki o rò ohun ti iwọ ri fun ọba. Kuṣi si wolẹ fun Joabu, o si sare.
22Ahimaasi ọmọ Sadoku si tun wi fun Joabu pe, Jọwọ, bi o ti wu ki o ri, emi o sare tọ Kuṣi lẹhin. Joabu si bi i pe, Nitori kini iwọ o ṣe sare, ọmọ mi, iwọ kò ri pe kò si ihìn rere kan ti iwọ o mu lọ?
23O si wi pe, Bi o ti wu ki o ri, emi o sare. On si wi fun u pe, Sare. Ahimaasi si sare li ọ̀na pẹtẹlẹ, o si sare kọja Kuṣi.
24Dafidi si joko li ẹnu odi lãrin ilẹkun meji: alore si goke orule bode lori odi, o si gbe oju rẹ̀ soke, o si wò, wõ, ọkunrin kan nsare on nikan.
25Alore na si kigbe, o si wi fun ọba; ọba si wi pe, Bi o ba ṣe on nikan ni, ihìn rere mbẹ li ẹnu rẹ̀. On si nsunmọ tosi.
26Alore na si ri ọkunrin miran ti nsare: alore si kọ si ẹniti nṣọ bode, o si wi pe, Wõ, ọkunrin kan nsare on nikan, ọba si wipe, Eyi na pẹlu nmu ihìn rere wá.
27Alore na si wipe, Emi wo isare ẹniti o wà niwaju o dabi isare Ahimaasi ọmọ Sadoku. Ọba si wi pe, Enia rere ni, o si nmu ihìn rere wá.
28Ahimaasi si pè, o si wi fun ọba pe, Alafia. On si wolẹ fun ọba, o dojubolẹ o si wi pe, Alabukun fun li Oluwa Ọlọrun rẹ, ẹniti o fi awọn ọkunrin ti o gbe ọwọ́ wọn soke si oluwa mi ọba le ọ lọwọ.
29Ọba si bere pe, Alafia fun Absalomu ọmọdekunrin nì bi? Ahimaasi si dahun pe, Nigbati Joabu rán iranṣẹ ọba, ati emi iranṣẹ rẹ, mo ri ọ̀pọ enia, ṣugbọn emi kò mọ̀ idi rẹ̀.
30Ọba si wi fun u pe, Yipada ki o si duro nihin: On si yipada, o si duro jẹ.
31Si wõ, Kuṣi de; Kuṣi si wi pe, Ihin rere fun oluwa mi ọba: nitoriti Oluwa ti gbẹsan rẹ loni lara gbogbo awọn ti o dide si ọ.
32Ọba si bi Kuṣi pe, Alafia kọ Absalomu ọdọmọdekunrin na wà bi? Kuṣi si dahun pe, Ki awọn ọta oluwa mi ọba, ati gbogbo awọn ti o dide si ọ ni ibi, ri bi ọdọmọdekunrin na.
33Ọba si kẹdùn pupọ̀, o si goke lọ si iyẹwu ti o wà lori oke bode, o si sọkun; bayi li o si nwi bi o ti nlọ, ọmọ mi Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi Absalomu! Ã! Ibaṣepe emi li o kú ni ipò rẹ, Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!
Currently Selected:
II. Sam 18: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.