II. Sam 19
19
Joabu bínú sí Dafidi
1A si rò fun Joabu pe, Wõ, ọba nsọkun, o si ngbawẹ fun Absalomu.
2Iṣẹgun ijọ na si di awẹ̀ fun gbogbo awọn enia na, nitori awọn enia na gbọ́ ni ijọ na bi inu ọba ti bajẹ nitori ọmọ rẹ̀.
3Awọn enia na si yọ́ lọ si ilu ni ijọ na gẹgẹ bi awọn enia ti a dojuti a ma yọ́ lọ nigbati nwọn nsá loju ijà.
4Ọba si bo oju rẹ̀, ọba si kigbe li ohùn rara pe, A! ọmọ mi Absalomu, Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!
5Joabu si wọ inu ile tọ ọba lọ, o si wipe, Iwọ dojuti gbogbo awọn iranṣẹ rẹ loni, awọn ti o gbà ẹmi rẹ là loni, ati ẹmi awọn ọmọkunrin rẹ, ati ti awọn ọmọbinrin rẹ, ati ẹmi awọn aya rẹ, ati ẹmi awọn obinrin rẹ.
6Nitoripe iwọ fẹ awọn ọta rẹ, iwọ si korira awọn ọrẹ rẹ. Nitoriti iwọ wi loni pe, Iwọ kò nani awọn ọmọ ọba, tabi awọn iranṣẹ: emi si ri loni pe, ibaṣepe Absalomu wà lãye, ki gbogbo wa si kú loni, njẹ iba dùnmọ ọ gidigidi.
7Si dide nisisiyi, lọ, ki o si sọ̀rọ itùnú fun awọn iranṣẹ rẹ: nitoripe emi fi Oluwa bura, bi iwọ kò ba lọ, ẹnikan kì yio ba ọ duro li alẹ yi: ati eyini yio si buru fun ọ jù gbogbo ibi ti oju rẹ ti nri lati igbà ewe rẹ wá titi o fi di isisiyi.
8Ọba si dide, o si joko li ẹnu ọ̀na. Nwọn si wi fun gbogbo awọn enia na pe, Wõ, ọba joko li ẹnu ọ̀na. Gbogbo enia si wá si iwaju ọba: nitoripe, Israeli ti sa, olukuluku si àgọ́ rẹ̀.
Dafidi bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu
9Gbogbo awọn enia na si mba ara wọn jà ninu gbogbo ẹya Israeli, pe, Ọba ti gbà wa là lọwọ awọn ọta wa, o si ti gbà wa kuro lọwọ awọn Filistini; on si wa sa kuro ni ilu nitori Absalomu.
10Absalomu, ti awa fi jọba lori wa si kú li ogun: njẹ ẽṣe ti ẹnyin fi dakẹ ti ẹnyin kò si sọ̀rọ kan lati mu ọba pada wá?
11Dafidi ọba si ranṣẹ si Sadoku, ati si Abiatari awọn alufa pe, Sọ fun awọn agbà Juda, pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi kẹhin lati mu ọba pada wá si ile rẹ̀? ọ̀rọ gbogbo Israeli si ti de ọdọ ọba ani ni ile rẹ̀.
12Ẹnyin li ará mi, ẹnyin li egungun mi, ati ẹran ara mi: ẹ̃si ti ṣe ti ẹnyin fi kẹhìn lati mu ọba pada wá?
13Ki ẹnyin ki o si wi fun Amasa pe, Egungun ati ẹran ara mi ki iwọ iṣe bi? ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si mi ati ju bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ kò ba ṣe olori ogun niwaju mi titi, ni ipò Joabu.
14On si yi ọkàn gbogbo awọn ọkunrin Juda, ani bi ọkàn enia kan; nwọn si ranṣẹ si ọba, pe, Iwọ pada ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ.
15Ọba si pada, o si wá si odo Jordani. Juda si wá si Gilgali, lati lọ ipade ọba, ati lati mu ọba kọja odo Jordani.
16Ṣimei ọmọ Gera, ara Benjamini ti Bahurimu, o yara o si ba awọn ọkunrin Juda sọkalẹ lati pade Dafidi ọba.
17Ẹgbẹrun ọmọkunrin si wà lọdọ rẹ̀ ninu awọn ọmọkunrin Benjamini, Siba iranṣẹ ile Saulu, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹ si pẹlu rẹ̀; nwọn si goke odo Jordani ṣaju ọba.
18Ọkọ̀ èro kan ti rekọja lati kó awọn enia ile ọba si oke, ati lati ṣe eyiti o tọ li oju rẹ̀. Ṣimei ọmọ Gera wolẹ, o si dojubolẹ niwaju ọba, bi o ti goke odo Jordani.
Dafidi Ṣàánú Ṣimei
19O si wi fun ọba pe, Ki oluwa mi ki o máṣe ka ẹ̀ṣẹ si mi li ọrùn, má si ṣe ranti afojudi ti iranṣẹ rẹ ṣe li ọjọ ti oluwa mi ọba jade ni Jerusalemu, ki ọba ki o má si fi si inu.
20Nitoripe iranṣẹ rẹ mọ̀ pe on ti ṣẹ̀; si wõ, ni gbogbo idile Josefu emi li o kọ́ wá loni lati sọkalẹ wá pade oluwa mi ọba.
21Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia dahùn o si wipe, Kò ha tọ́ ki a pa Ṣimei nitori eyi? nitoripe on ti bú ẹni-àmi-ororo Oluwa.
22Dafidi si wipe, Ki li o wà lãrin emi ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Seruia, ti ẹ fi di ọta si mi loni? a ha le pa enia kan loni ni Israeli? o le ṣe pe emi kò mọ̀ pe, loni emi li ọba Israeli?
23Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ kì yio kú. Ọba si bura fun u.
Dafidi Ṣàánú Mẹfiboṣẹti
24Mefiboṣeti ọmọ Saulu si sọkalẹ lati wá pade ọba, kò wẹ ẹsẹ rẹ̀, kò si fá irungbọ̀n rẹ̀, bẹ̃ni kò si fọ aṣọ rẹ̀ lati ọjọ ti ọba ti jade titi o fi di ọjọ ti o fi pada li alafia.
25O si ṣe, nigbati on si wá si Jerusalemu lati pade ọba, ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ kò fi ba mi lọ, Mefiboṣeti?
26On si dahùn wipe, Oluwa mi, ọba, iranṣẹ mi li o tàn mi jẹ; nitoriti iranṣẹ rẹ ti wipe, Emi o di kẹtẹkẹtẹ ni gãri, emi o gùn u, emi o si tọ̀ ọba lọ, nitoriti iranṣẹ rẹ yarọ.
27O si sọ̀rọ ibajẹ si iranṣẹ rẹ, fun oluwa mi ọba, ṣugbọn bi angeli Ọlọrun li oluwa mi ọba ri: nitorina ṣe eyi ti o dara loju rẹ.
28Nitoripe gbogbo ile baba mi bi okú enia ni nwọn sa ri niwaju oluwa mi ọba: iwọ si fi ipò fun iranṣẹ rẹ larin awọn ti o njẹun ni ibi onjẹ rẹ. Nitorina are kili emi ni ti emi o fi ma ke pe ọba sibẹ.
29Ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi nsọ ọràn rẹ siwaju mọ? emi sa ti wipe, Ki iwọ ati Siba pin ilẹ na.
30Mefiboṣeti si wi fun ọba pe, Si jẹ ki o mu gbogbo rẹ̀, bi oluwa mi ọba ba ti pada bọ̀ wá ile rẹ̀ li alafia.
Dafidi Ṣàánú Basilai
31Barsillai ara Gileadi si sọkalẹ lati Rogelimu wá, o si ba ọba goke odo Jordani, lati ṣe ikẹ́ rẹ̀ si ikọja odo Jordani.
32Barsillai si jẹ arugbo ọkunrin gidigidi, ẹni ogbó ọgọrin ọdun si ni: o si pese ohun jijẹ fun ọba nigbati o ti wà ni Mahanaimu; nitoripe ọkunrin ọlọla li on iṣe.
33Ọba si wi fun Barsillai pe, Iwọ wá ba mi goke odo, emi o si ma bọ́ ọ ni Jerusalemu.
34Barsillai si wi fun ọba pe, Ọjọ melo ni ọdun ẹmi mi kù, ti emi o fi ba ọba goke lọ si Jerusalemu?
35Ẹni ogbó ọgọrin ọdun sa li emi loni: emi le mọ̀ iyatọ ninu rere ati buburu? iranṣẹ rẹ le mọ̀ adùn ohun ti emi njẹ tabi ohun ti emi nmu bi? emi tun le mọ̀ adùn ohùn awọn ọkunrin ti nkọrin, ati awọn obinrin ti nkọrin bi? njẹ nitori kili iranṣẹ rẹ yio ṣe jẹ́ iyọnu sibẹ fun oluwa mi ọba?
36Iranṣẹ rẹ yio si sin ọba lọ diẹ goke odo Jordani; ẽsi ṣe ti ọba yio fi san ẹsan yi fun mi?
37Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ pada, emi o si kú ni ilu mi, a o si sin mi ni iboji baba ati iya mi. Si wo Kimhamu iranṣẹ rẹ, yio ba oluwa mi ọba goke; iwọ o si ṣe ohun ti o ba tọ li oju rẹ fun u.
38Ọba si dahùn wipe, Kimhamu yio ba mi goke, emi o si ṣe eyi ti o tọ loju rẹ fun u; ohunkohun ti iwọ ba si bere lọwọ mi, emi o ṣe fun ọ.
39Gbogbo awọn enia si goke odo Jordani. Ọba si goke; ọba si fi ẹnu kò Barsillai li ẹnu, o si sure fun u; on si pada si ile rẹ̀.
Juda ati Israẹli ń Jiyàn lórí ẹni tí ó ni Ọba
40Ọba si nlọ si Gilgali, Kimhamu si mba a lọ, gbogbo awọn enia Juda si nṣe ikẹ ọba, ati ãbọ awọn enia Israeli.
41Si wõ, gbogbo awọn ọkunrin Israeli si tọ ọba wá, nwọn si wi fun ọba pe, Ẽṣe ti awọn arakunrin wa awọn ọkunrin Juda fi ji ọ kuro, ti nwọn si fi mu ọba ati awọn ara ile rẹ̀ goke odo Jordani, ati gbogbo awọn enia Dafidi pẹlu rẹ̀.
42Gbogbo ọkunrin Juda si da awọn ọkunrin Israeli li ohùn pe, Nitoripe ọba bá wa tan ni; ẽṣe ti ẹnyin fi binu nitori ọran yi? awa jẹ ninu onjẹ ọba rara bi? tabi o fi ẹ̀bun kan fun wa bi?
43Awọn ọkunrin Israeli si da awọn ọkunrin Juda li ohùn pe, Awa ni ipa mẹwa ninu ọba, awa si ni ninu Dafidi jù nyin lọ, ẽṣe ti ẹnyin kò fi kà wa si, ti ìmọ wa kò fi ṣaju lati mu ọba wa pada? ọ̀rọ awọn ọkunrin Juda si le jù ọ̀rọ awọn ọkunrin Israeli lọ.
Currently Selected:
II. Sam 19: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.