II. A. Ọba Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú
Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú
Àwọn Ìtàn inú ìwé yìí jẹ́ àfikún ti inú Ìwé Àwọn Ọba Kinni , nípa ìjọba ìpínlẹ̀ àwọn ẹ̀yà Israẹli, ti àríwá ati ti gúsù. Ọ̀nà meji pataki ni a lè pín ìtàn inú ìwé yìí sí: (1) Ìtàn ìjọba ìpínlẹ̀ mejeeji láti nǹkan bíi ààrin sẹntiuri kẹsàn-án (9th Century B.C.), kí á tó bí OLUWA wa títí di àkókò ìṣubú Samaria ati òpin ìjọba ìpínlẹ̀ àríwá ní ẹẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mejilelogun ọdún (722 B.C.) kí á tó bí OLUWA wa. (2) Ìtàn ìjọba ìpínlẹ̀ Juda láti àkókò ìṣubú ìjọba ìpínlẹ̀ Israẹli títí di ìgbà tí Nebukadinesari ọba Babilonii kó Jerusalẹmu nígbèkùn, tí ó sì pa á run ní ọrinlelẹẹdẹgbẹta ó lé mẹfa ọdún (586 B.C.) kí á tó bí OLUWA wa. Ní òpin ìtàn inú ìwé náà, a rí ìtàn Gedalaya gomina Juda lábẹ́ àṣẹ àwọn ará Babilonii ati àkọsílẹ̀ bí wọ́n ṣe dá Jehoiakimu ọba Juda sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n ní Babilonii.
Àwọn ìdàrúdàpọ̀ wọnyi dé bá àwọn ọba ati àwọn ọmọ Israẹli ati Juda nítorí aiṣododo wọn. Ohun ìyanu ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi jẹ́ ninu ìtàn àwọn ọmọ Israẹli.
Ipa pataki ni Wolii Eliṣa tí ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Wolii Elija kó ninu àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Àwọn Ọba Keji.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Orílẹ̀-èdè Israẹli pín sí meji 1:1—17:41
a. Wolii Eliṣa 1:1—8:15
b. Àwọn Ọba Juda ati Àwọn Ọba Israẹli 8:16—17:4
d. Ìṣubú Samaria 17:5-41
Ìjọba ìpínlẹ̀ Juda 18:1—25:30
a. Láti orí Hesekaya dé Josaya 18:1—21:26
b. Ìjọba Josaya 22:1—23:30
d. Àwọn ọba tí wọ́n jẹ kẹ́yìn ní Juda 23:31—24:20
e. Ìṣubú Jerusalẹmu 25:1-30
Currently Selected:
II. A. Ọba Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.