II. A. Ọba 1
1
Elija ati Ọba Ahasaya
1NIGBANA ni Moabu ṣọ̀tẹ si Israeli lẹhin ikú Ahabu.
2Ahasiah si ṣubu lãrin fèrese ọlọnà kan ni iyara òke rẹ̀ ti o wà ni Samaria, o si ṣàisan: o si rán awọn onṣẹ o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Baalsebubu, oriṣa Ekroni, bi emi o là ninu aisan yi.
3Ṣugbọn angeli Oluwa wi fun Elijah, ara Tiṣbi pe, Dide, gòke lọ ipade awọn onṣẹ ọba Samaria, ki o si wi fun wọn pe, Kò ṣe pe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni ẹnyin fi nlọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni?
4Njẹ nitorina bayi li Oluwa wi, Iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì lori eyiti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú. Elijah si lọ kuro.
5Nigbati awọn onṣẹ si pada si ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi pada sẹhin?
6Nwọn si wi fun u pe, Ọkunrin kan li o gòke lati pade wa, o si wi fun wa pe, Ẹ lọ, ẹ pada tọ̀ ọba ti o rán nyin, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni iwọ fi ranṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni? nitorina, iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú.
7On si wi fun wọn pe, Iru ọkunrin wo li ẹniti o gòke lati pade nyin, ti o si sọ̀rọ wọnyi fun nyin?
8Nwọn si da a li ohùn pe, Ọkunrin Onirum li ara ni; o si dì àmure awọ mọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. On si wipe, Elijah ara Tiṣbi ni.
9Nigbana ni ọba rán olori-ogun ãdọta kan pẹlu ãdọta rẹ̀. O si gòke tọ̀ ọ lọ: si kiyesi i, o joko lori òke kan. On si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, ọba wipe, Sọ̀kalẹ.
10Elijah si dahùn, o si wi fun olori-ogun ãdọta na pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o run ọ ati ãdọta rẹ. Iná si sọ̀kalẹ ti ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀.
11On si tun rán olori-ogun ãdọta miran pẹlu ãdọta rẹ̀. On si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, Bayi li ọba wi, yara sọ̀kalẹ.
12Elijah si dahùn, o si wi fun wọn pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o si run ọ ati ãdọta rẹ. Iná Ọlọrun si sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀.
13O si tun rán olori-ogun ãdọta ekẹta pẹlu ãdọta rẹ̀. Olori-ogun ãdọta kẹta si gòke, o si wá, o si wolẹ lori ẽkún rẹ̀ niwaju Elijah, o si bẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Iwọ, enia Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ́, jẹ ki ẹmi mi ati ẹmi awọn ãdọta ọmọ-ọdọ rẹ wọnyi, ki o ṣọwọn li oju rẹ.
14Kiyesi i, iná sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run olori-ogun meji arãdọta iṣãju pẹlu arãdọta wọn: njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹmi mi ki o ṣọwọn li oju rẹ.
15Angeli Oluwa si wi fun Elijah pe, Ba a sọ̀kalẹ lọ: máṣe bẹ̀ru rẹ̀. On si dide, o si ba a sọ̀kalẹ lọ sọdọ ọba.
16On si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, nitoriti iwọ ran onṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli lati bère ọ̀rọ rẹ̀? nitorina iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú;
17Bẹ̃ni o kú gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti Elijah ti sọ. Jehoramu si jọba ni ipò rẹ̀, li ọdun keji Jehoramu ọmọ Jehoṣafati, ọba Juda, nitoriti kò ni ọmọkunrin.
18Ati iyokù iṣe Ahasiah ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
Currently Selected:
II. A. Ọba 1: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.