II. Kro 3
3
1SOLOMONI si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu li òke Moriah nibiti Ọlọrun farahàn Dafidi baba rẹ̀, ti Dafidi ti pèse, nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi.
2On si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile ni ọjọ keji oṣù keji, li ọdun kẹrin ijọba rẹ̀.
3Eyi si ni ìwọn ti Solomoni fi lelẹ fun kikọ́ ile Ọlọrun. Gigùn rẹ̀ ni igbọnwọ gẹgẹ bi ìwọn igbãni li ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ogún igbọnwọ.
4Ati iloro ti mbẹ niwaju ile na, gigùn rẹ̀ ri gẹgẹ bi ibu ile na, ogún igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgọfa; o si fi kiki wura bò o ninu.
5O si fi igi-firi bò ile ti o tobi, o si fi wura daradara bò o, o si gbẹ́ àworan igi-ọpẹ ati ẹ̀wọn si i.
6O si fi okuta iyebiye ṣe ile na li ọṣọ́ fun ẹwà: wura na si jasi wura Parfaimu.
7O si fi wura bò ile na pẹlu, ati ìti, opó, ati ogiri rẹ̀ wọnni, ati ilẹkun rẹ̀ mejeji; o si gbẹ́ àworan awọn kerubu si ara ogiri na.
8O si ṣe ile mimọ́-jùlọ na, gigùn eyiti o wà gẹgẹ bi ibu ile na, ogún igbọnwọ: ati ibu rẹ̀, ogún igbọnwọ: o si fi wura daradara bò o, ti o to ẹgbẹta talenti.
9Oṣuwọn iṣó si jasi ãdọta ṣekeli wura. On si fi wura bò iyara òke wọnni.
10Ati ninu ile mimọ́-jùlọ na, o ṣe kerubu meji ti iṣẹ ọnà finfin, o si fi wura bò wọn.
11Iyẹ awọn kerubu na si jẹ ogún igbọnwọ ni gigùn: iyẹ kan jẹ igbọnwọ marun, ti o kan ogiri ile na, iyẹ keji si jẹ igbọnwọ marun, ti o kan iyẹ kerubu keji.
12Ati iyẹ kerubu keji jẹ igbọnwọ marun ti o kan ogiri ile na: ati iyẹ keji jẹ igbọnwọ marun ti o kan iyẹ kerubu keji.
13Iyẹ kerubu wọnyi nà jade ni ogún igbọnwọ: nwọn si duro li ẹsẹ wọn, oju wọn si wà kọju si ile.
14O si ṣe iboju alaro, ati elése aluko ati òdodó, ati ọ̀gbọ daradara, o si ṣiṣẹ awọn kerubu lara wọn.
Àwọn Òpó Idẹ Meji
(I. A. Ọba 7:15-22)
15O si ṣe ọwọ̀n meji igbọnwọ marundilogoji ni giga niwaju ile na, ati ipari ti mbẹ lori ọkọkan wọn si jẹ igbọnwọ marun.
16O si ṣe ẹ̀wọn ninu ibi-idahùn na, o si fi wọn si ori awọn ọwọ̀n na: o si ṣe awọn pomegranate ọgọrun, o si fi wọn si ara ẹ̀wọn na.
17O si gbé awọn ọwọ̀n na ro niwaju ile Ọlọrun, ọkan li apa ọtún, ati ekeji li apa òsi, o si pe orukọ eyi ti mbẹ li apa ọtún ni Jakini, ati orukọ eyi ti mbẹ li apa òsi ni Boasi.
Currently Selected:
II. Kro 3: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.