II. Kro 2
2
Ìpalẹ̀mọ́ fún Kíkọ́ Tẹmpili
(I. A. Ọba 5:1-18)
1SOLOMONI si pinnu rẹ̀ lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, ati ile kan fun ijọba rẹ̀.
2Solomoni si yàn ẹgbã marundilogoji ọkunrin lati ru ẹrù, ati ọkẹ mẹrin lati ké igi li ori òke, ati egbejidilogun lati bojuto wọn.
3Solomoni si ranṣẹ si Huramu, ọba Tire, wipe, Gẹgẹ bi iwọ ti ba Dafidi, baba mi lò, ti iwọ fi igi kedari ṣọwọ si i lati kọ́ ile kan fun u lati ma gbe inu rẹ̀, bẹni ki o ba mi lò.
4Kiyesi i, emi nkọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun mi, lati yà a si mimọ́ fun u, ati lati sun turari niwaju rẹ̀, ati fun àkara-ifihan igbakugba, ati fun ẹbọsisun li ọwurọ ati li alẹ, li ọjọjọ isimi ati li oṣoṣù titun, ati li apejọ Oluwa Ọlọrun wa; eyi ni aṣẹ fun Israeli titi lai.
5Ile ti emi nkọ́ yio si tobi; nitori titobi ni Ọlọrun wa jù gbogbo awọn ọlọrun lọ.
6Ṣugbọn tani to lati kọ́ ile fun u, nitori ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà a? tali emi ti emi iba kọ́le fun u, bikòṣe kiki ati sun ẹbọ niwaju rẹ̀?
7Njẹ nisisiyi rán ọkunrin kan si mi ti o gbọ́n lati ṣiṣẹ ni wura, fadakà, ati ni idẹ, ati ni irin, ati ni èse aluko, ati òdodó ati alaró, ti o si le gbọ́ngbọn ati gbẹgi pẹlu awọn ọkunrin ọlọgbọ́n ti o wà lọdọ mi ni Juda ati Jerusalemu, awọn ẹniti Dafidi baba mi ti pese silẹ.
8Fi ìti-igi kedari, ati firi, ati algumu ranṣẹ si mi pẹlu, lati Lebanoni wá: emi sa mọ̀ pe awọn iranṣẹ rẹ le gbọ́ngbọn ati ké igi ni Lebanoni; si kiyesi i, awọn ọmọ-ọdọ mi yio wà pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ:
9Ani lati pèse ìti-igi lọpọlọpọ silẹ fun mi: nitori ile na ti emi mura lati kọ́ tobi, o si ya ni lẹnu.
10Si wò o, emi o fi fun ilo awọn akégi, ti nké ìti-igi, lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ẹgbãwa òṣuwọn alikama fun onjẹ, ati ẹgbãwa òṣuwọn barli ati ẹgbãwa bati ọti-waini, ati ẹgbãwa bati ororo.
11Nigbana ni Huramu, ọba Tire, kọwe dahùn o si ranṣẹ si Solomoni pe, Nitori ti Oluwa fẹran awọn enia rẹ̀ li o ṣe fi ọ jọba lori wọn.
12Huramu si wipe, Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o da ọrun on aiye, ẹniti o fun Dafidi ọba ni ọlọgbọ́n ọmọ, ti o mọ̀ ọgbọ́n ati oye, ti o le kọ́ ile fun Oluwa, ati ile fun ijọba rẹ̀.
13Njẹ nisisiyi emi rán ọkunrin ọlọgbọ́n kan, ti o mọ̀ oye, ani Huramu-Abi,
14Ọmọ obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin Dani: baba rẹ̀ si ṣe ọkunrin ara Tire ti o gbọ́ngbọn ati ṣiṣẹ ni wura, ati ni fadakà, ni idẹ, ni irin, ni okuta, ati ni ìti-igi, ni èse-aluko, ni alaró, ati ni ọ̀gbọ daradara, ati òdodó, lati gbẹ́ oniruru ohun gbigbẹ́ pẹlu, ati lati ṣe awari ìmọ ẹrọ gbogbo ti a o fi fun u ṣe, pẹlu awọn ọlọgbọ́n rẹ, ati pẹlu awọn ọlọgbọ́n oluwa mi Dafidi, baba rẹ.
15Njẹ nitorina alikama ati ọkà barli, ororo, ati ọti-waini na ti oluwa mi ti sọ, jẹ ki o fi ranṣẹ si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.
16Awa o si ké igi lati Lebanoni wá, iyekiye ti iwọ o fẹ; awa o si mu wọn fun ọ wá ni fifó li okun si Joppa; iwọ o si rù wọn gòke lọ si Jerusalemu.
Kíkọ́ Tẹmpili Bẹ̀rẹ̀
(I. A. Ọba 6:1-38)
17Solomoni si kaye gbogbo awọn ajeji ọkunrin ti o wà ni ilẹ Israeli, gẹgẹ bi kikà ti Dafidi, baba rẹ̀ ti kà wọn; a si ri pe, nwọn jẹ ọkẹ-mẹjọ o di-egbejilelọgbọ̀n.
18O si yàn ẹgbã marundilogoji ninu wọn lati ru ẹrù, ati ọkẹ mẹrin lati ṣe aké-okuta li ori òke, ati egbejidilogun alabojuto lati kó awọn enia ṣiṣẹ.
Currently Selected:
II. Kro 2: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.