YouVersion Logo
Search Icon

I. A. Ọba 4

4
Àwọn Òṣìṣẹ́ Solomoni
1SOLOMONI ọba si jẹ ọba lori gbogbo Israeli.
2Awọn wọnyi ni awọn ijoye ti o ni; Asariah, ọmọ Sadoku alufa,
3Elihorefu ati Ahiah, awọn ọmọ Ṣiṣa li akọwe, Jehoṣafati ọmọ Ahiludi li akọwe ilu.
4Ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, li olori-ogun: ati Sadoku ati Abiatari ni awọn alufa:
5Ati Asariah, ọmọ Natani, li olori awọn ọgagun: Sabudu, ọmọ Natani, alufa, si ni ọrẹ ọba:
6Ati Ahiṣari li o ṣe olori agbo-ile: ati Adoniramu, ọmọ Abda li o nṣe olori iṣẹ-irú.
7Solomoni si ni ijoye mejila lori gbogbo Israeli, ti o npèse onjẹ fun ọba ati agbo-ile rẹ̀; olukuluku li oṣu tirẹ̀ li ọdun ni npese.
8Orukọ wọn si ni wọnyi: Benhuri li oke Efraimu.
9Bendekari ni Makasi, ati ni Ṣaalbimu ati Betṣemeṣi, ati Elonibethanani:
10Benhesedi, ni Aruboti; tirẹ̀ ni Soko iṣe ati gbogbo ilẹ Heferi:
11Ọmọ Abinadabu, ni gbogbo agbègbe Dori: ti o ni Tafati, ọmọbinrin Solomoni, li aya.
12Baana ọmọ Ahiludi, tirẹ̀ ni Taanaki iṣe, ati Megiddo, ati gbogbo Betṣeani ti mbẹ niha Sartana nisalẹ Jesreeli, lati Betṣeani de Abelmehola, ani titi de ibi ti mbẹ ni ikọja Jokneamu;
13Ọmọ Geberi ni Ramoti-Gileadi; tirẹ̀ ni awọn ileto Jairi, ọmọ Manasse, ti mbẹ ni Gileadi; tirẹ̀ si ni apa Argobu, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu ti o tobi, ti o li odi ati ọpa-idabu idẹ.
14Ahinadabu, ọmọ Iddo, li o ni Mahanaimu.
15Ahimaasi wà ni Naftali; on pẹlu li o ni Basmati, ọmọbinrin Solomoni, li aya.
16Baana, ọmọ Huṣai wà ni Aṣeri ati ni Aloti.
17Jehoṣafati, ọmọ Paruha, ni Issakari:
18Ṣimei, ọmọ Ela, ni Benjamini.
19Geberi, ọmọ Uri wà ni ilẹ Gileadi ni ilẹ Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani: ijoye kan li o si wà ni ilẹ na.
Ìjọba Solomoni ní ìtẹ̀síwájú ati alaafia
20Juda ati Israeli pọ̀ gẹgẹ bi iyanrin ti mbẹ li eti okun ni ọ̀pọlọpọ, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nwọn si nṣe ariya.
21Solomoni si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò titi de ilẹ awọn ara Filistia, ati titi de eti ilẹ Egipti: nwọn nmu ọrẹ wá, nwọn si nsìn Solomoni ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.
22Onjẹ Solomoni fun ijọ kan jasi ọgbọ̀n iyẹ̀fun kikunna ati ọgọta oṣuwọn iyẹ̀fun iru miran.
23Malu mẹwa ti o sanra, ati ogún malu lati inu papa wá, ati ọgọrun agutan, laika agbọ̀nrin, ati egbin, ati ogbúgbu, ati ẹiyẹ ti o sanra.
24Nitori on li o ṣe alaṣẹ lori gbogbo agbègbe ni iha ihin odò, lati Tifsa titi de Gasa, lori gbogbo awọn ọba ni iha ihin odò: o si ni alafia ni iha gbogbo yi i kakiri.
25Juda ati Israeli ngbe li alafia, olukuluku labẹ àjara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ́ rẹ̀, lati Dani titi de Beerṣeba, ni gbogbo ọjọ Solomoni.
26Solomoni si ni ẹgbãji ile-ẹṣin fun kẹkẹ́ rẹ̀, ati ẹgbãfa ẹlẹṣin.
27Awọn ijoye na si pesè onjẹ fun Solomoni ọba, ati fun gbogbo awọn ti o wá sibi tabili Solomoni ọba, olukuluku li oṣu tirẹ̀: nwọn kò fẹ nkankan kù.
28Ọkà barle pẹlu, ati koriko fun ẹṣin ati fun ẹṣin sisare ni nwọn mu wá sibiti o gbe wà, olukuluku gẹgẹ bi ilana tirẹ̀.
29Ọlọrun si fun Solomoni li ọgbọ́n ati oye li ọ̀pọlọpọ, ati oye gbigboro, gẹgẹ bi iyanrin ti o wà leti okun.
30Ọgbọ́n Solomoni si bori ọgbọ́n gbogbo awọn ọmọ ila-õrun, ati gbogbo ọgbọ́n Egipti.
31On si gbọ́n jù gbogbo enia; jù Etani, ara Esra, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara, awọn ọmọ Maholi: okiki rẹ̀ si kàn ni gbogbo orilẹ-ède yíka.
32O si pa ẹgbẹdọgbọn owe: orin rẹ̀ si jẹ ẹgbẹrun o le marun.
33O si sọ̀rọ ti igi, lati kedari ti mbẹ ni Lebanoni, ani titi de hissopu ti nhu lara ogiri: o si sọ̀ ti ẹranko pẹlu, ati ti ẹiyẹ, ati ohun ti nrako, ati ti ẹja.
34Ẹni pupọ si wá lati gbogbo orilẹ-ède lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni; ani lati ọdọ gbogbo awọn ọba aiye, ti o gburo ọgbọ́n rẹ̀.

Currently Selected:

I. A. Ọba 4: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in