YouVersion Logo
Search Icon

I. A. Ọba 3

3
Solomoni Bẹ̀bẹ̀ fún Ọgbọ́n
(II. Kro 1:3-12)
1SOLOMONI si ba Farao ọba Egipti da ana, o si gbe ọmọbinrin Farao ni iyawo, o si mu u wá si ilu Dafidi, titi o fi pari iṣẹ ile rẹ̀, ati ile Oluwa, ati odi Jerusalemu yika.
2Kiki pe, awọn enia nrubọ ni ibi giga, nitori a kò ti ikọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, titi di ọjọ wọnnì.
3Solomoni si fẹ Oluwa, o si nrin nipa aṣẹ Dafidi baba rẹ̀: ṣugbọn kiki pe, o nrubọ, o si nfi turari jona ni ibi-giga.
4Ọba si lọ si Gibeoni lati rubọ nibẹ; nitori ibẹ ni ibi-giga nlanla: ẹgbẹrun ọrẹ ẹbọ-sisun ni Solomoni ru lori pẹpẹ na.
5Ni Gibeoni ni Oluwa fi ara rẹ̀ hàn Solomoni loju alá li oru: Ọlọrun si wipe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ.
6Solomoni si wipe, Iwọ ti ṣe ore nla fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi, gẹgẹ bi o ti rin niwaju rẹ li otitọ ati li ododo, ati ni iduro-ṣinṣin ọkàn pẹlu rẹ, iwọ si pa ore nla yi mọ fun u lati fun u li ọmọkunrin ti o joko lori itẹ rẹ̀, gẹgẹ bi o ti ri loni yi.
7Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun mi, iwọ ti fi iranṣẹ rẹ jẹ ọba ni ipo Dafidi, baba mi: ati emi, ọmọ kekere ni mi, emi kò si mọ̀ jijade ati wiwọle.
8Iranṣẹ rẹ si mbẹ lãrin awọn enia rẹ ti iwọ ti yàn, enia pupọ, ti a kò le moye, ti a kò si lè kà fun ọ̀pọlọpọ.
9Nitorina, fi ọkàn imoye fun iranṣẹ rẹ lati ṣe idajọ awọn enia rẹ, lati mọ̀ iyatọ rere ati buburu; nitori tali o le ṣe idajọ awọn enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi?
10Ọ̀rọ na si dara loju Oluwa, nitoriti Solomoni bère nkan yi.
11Ọlọrun si wi fun u pe, Nitoriti iwọ bère nkan yi, ti iwọ kò si bère ẹmi gigun fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ọlá fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ẹmi awọn ọta rẹ; ṣugbọn iwọ bère oye fun ara rẹ lati mọ̀ ẹjọ-idá;
12Wò o, emi ti ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, wò o, emi fun ọ ni ọkàn ọgbọ́n ati imoye; tobẹ̃ ti kò ti isi ẹnikan ti o dabi rẹ ṣãju rẹ, bẹ̃ni lẹhin rẹ ẹnikan kì yio dide ti yio dabi rẹ.
13Ati eyiti iwọ kò bere, emi o fun ọ pẹlu ati ọrọ̀ ati ọlá: tobẹ̃ ti kì yio si ọkan ninu awọn ọba ti yio dabi rẹ.
14Bi iwọ o ba si rìn ni ọ̀na mi lati pa aṣẹ ati ofin mi mọ, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ ti rìn, emi o si sún ọjọ rẹ siwaju.
15Solomoni si jí; si wò o, alá ni. On si wá si Jerusalemu, o si duro niwaju apoti majẹmu Oluwa, o si rubọ ọrẹ sisun, o si ru ẹbọ-alafia, o si se àse fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀.
Solomoni dá ẹjọ́ kan tí Ó ta kókó
16Nigbana ni obinrin meji, ti iṣe àgbere, wá sọdọ ọba nwọn si duro niwaju rẹ̀.
17Ọkan ninu wọn si wipe, Jọwọ, oluwa mi, emi ati obinrin yi ngbe ile kan; emi si bi ọmọ ni ile pẹlu rẹ̀.
18O si ṣe ni ọjọ kẹta lẹhin igbati mo bimọ tan, obinrin yi si bimọ pẹlu: awa si jumọ ngbé pọ: kò si si alejo pẹlu wa ni ile bikoṣe awa mejeji ni ile.
19Ọmọ obinrin yi si kú li oru; nitoriti o sun le e.
20O si dide li ọ̀ganjọ, o si gbe ọmọ mi lati iha mi, nigbati iranṣẹ-birin rẹ sun, o si tẹ́ ẹ si aiya rẹ̀, o si tẹ́ okú ọmọ tirẹ̀ si aiya mi.
21Mo si dide li owurọ lati fi ọmú fun ọmọ mi, si wò o, o ti kú: ṣugbọn nigbati mo wò o fin li owurọ̀, si wò o, kì iṣe ọmọ mi ti mo bí.
22Obinrin keji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi alãye ni ọmọ mi, eyi okú li ọmọ rẹ, eyi si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye si li ọmọ mi. Bayi ni nwọn nsọ niwaju ọba.
23Ọba si wipe, Ọkan wipe, eyi li ọmọ mi ti o wà lãye, ati okú li ọmọ rẹ; ekeji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye li ọmọ mi.
24Ọba si wipe, Ẹ mu idà fun mi wá. Nwọn si mu idà wá siwaju ọba.
25Ọba si wipe, Ẹ là eyi alãye ọmọ si meji, ki ẹ si mu idaji fun ọkan ati idaji fun ekeji.
26Obinrin ti eyi alãye ọmọ iṣe tirẹ̀ si wi fun ọba, nitori ti inu rẹ̀ yọ́ si ọmọ rẹ̀, o si wipe, Jọwọ, oluwa mi, ẹ fun u ni eyi alãye ọmọ, ki a máṣe pa a rara. Ṣugbọn eyi ekeji si wipe, kì yio jẹ temi tabi tirẹ, ẹ là a.
27Ọba si dahùn o si wipe, ẹ fi alãye ọmọ fun u, ki ẹ má si ṣe pa a: on ni iya rẹ̀.
28Gbogbo Israeli si gbọ́ idajọ ti ọba ṣe; nwọn si bẹ̀ru niwaju ọba: nitoriti nwọn ri i pe, ọgbọ́n Ọlọrun wà ninu rẹ̀, lati ṣe idajọ.

Currently Selected:

I. A. Ọba 3: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in