YouVersion Logo
Search Icon

ROMU 14

14
Má Ṣe Dá Ẹnìkejì Rẹ lẹ́jọ́
1Ẹ fa àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́ra, kì í ṣe láti máa bá wọn jiyàn lórí ohun tí kò tó iyàn. 2Ẹnìkan ní igbagbọ pé kò sí ohun tí òun kò lè jẹ, ṣugbọn ẹni tí igbagbọ rẹ̀ kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ rọra ń jẹ ẹ̀fọ́ ní tirẹ̀. 3Kí ẹni tí ń jẹran má fi ojú tẹmbẹlu ẹni tí kì í jẹ. Kí ẹni tí kì í jẹ má sì ṣe dá ẹni tí ó ń jẹ lẹ́bi, nítorí Ọlọrun ti gbà á. 4Ta ni ìwọ tí ò ń dá ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Kì báà dúró, kì báà sì ṣubú, ọ̀gá rẹ̀ nìkan ni ìdájọ́ tọ́ sí. Yóo tilẹ̀ dúró ni, nítorí Oluwa lè gbé e ró.#Kol 2:16
5Ẹnìkan ka ọjọ́ kan sí ọjọ́ pataki ju ọjọ́ mìíràn lọ, ẹlòmíràn ka gbogbo ọjọ́ sí bákan náà. Ẹ jẹ́ kí olukuluku pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ nípa irú ọ̀ràn báwọ̀nyí. 6Ẹni tí ó gbé ọjọ́ kan ga ju ọjọ́ mìíràn lọ, ti Oluwa ni ó ń rò. Ẹni tí ó ń jẹ oríṣìíríṣìí oúnjẹ, ó ń jẹ ẹ́ nítorí Oluwa. Ọpẹ́ ni ó ń fi fún Ọlọrun. Ẹni tí kò jẹ, kò jẹ ẹ́ nítorí Oluwa, ọpẹ́ ni òun náà ń fi fún Ọlọrun. 7Kò sí ẹni tí ó lè wà láàyè fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni, kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, òun nìkan ni ikú òun kàn. 8Bí a bá wà láàyè, Oluwa ni a wà láàyè fún. Bí a bá sì kú, Oluwa ni a kú fún. Nítorí náà, ààyè wa ni o, òkú wa ni o, ti Oluwa ni wá. 9Ìdí tí Kristi fi kú nìyí, tí ó sì tún jí, kí ó lè jẹ́ Oluwa àwọn òkú ati ti àwọn alààyè. 10Kí ni ìdí tí o fi ń dá arakunrin rẹ lẹ́jọ́? Sọ ọ́ kí á gbọ́! Tabi kí ló dé tí ò ń fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ? Gbogbo wa mà ni a óo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun!#2 Kọr 5:10 11Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,#Ais 45:23
“Oluwa fi ara rẹ̀ búra, ó ní,
‘Èmi ni gbogbo orúnkún yóo kúnlẹ̀ fún,
Èmi ni gbogbo ẹnu yóo pè ní Ọlọrun.’ ”
12Nítorí náà, olukuluku wa ni yóo sọ ti ẹnu ara rẹ̀ níwájú Ọlọrun.
Ẹ Má Mú Arakunrin Yín Kọsẹ̀
13Ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ìpinnu kan tí à bá ṣe ni pé, kí á má ṣe fi ohun ìkọsẹ̀ kan, tabi ohunkohun tí yóo ṣi arakunrin wa lọ́nà, sí ojú ọ̀nà rẹ̀. 14Mo mọ èyí, ó sì dá mi lójú nípa àṣẹ Oluwa Jesu pé kò sí ohunkohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ ní jíjẹ fún ara rẹ̀. Ṣugbọn tí ẹnìkan bá ka nǹkan sí èèwọ̀, èèwọ̀ ni fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. 15Nítorí bí o bá mú ìdààmú bá arakunrin rẹ nípa ọ̀ràn oúnjẹ tí ò ń jẹ, a jẹ́ pé, kì í ṣe ìfẹ́ ni ń darí ìgbésí-ayé rẹ mọ́. Má jẹ́ kí oúnjẹ tí ò ń jẹ mú ìparun bá ẹni tí Jesu ti ìtorí rẹ̀ kú. 16Má ṣe fi ààyè sílẹ̀ fún ìsọkúsọ nípa àwọn ohun tí ẹ kà sí nǹkan rere. 17Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ọ̀ràn nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu, ọ̀ràn òdodo, alaafia ati ayọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni. 18Ẹni tí ó bá ń sin Kristi báyìí jẹ́ ẹni tí inú Ọlọrun dùn sí, tí àwọn eniyan sì gbà fún.
19Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa lépa àwọn nǹkan tí ń mú alaafia wá, ati àwọn nǹkan tí yóo yọrí sí ìdàgbàsókè láàrin ara wa. 20Ẹ má ṣe tìtorí oúnjẹ ba iṣẹ́ Ọlọrun jẹ́. A lé sọ pé kò sí oúnjẹ kan tí kò dára, ṣugbọn nǹkan burúkú ni fún ẹni tí ó bá ń jẹ oúnjẹ kan tí ó di nǹkan ìkọsẹ̀ fún ẹlòmíràn. 21Ó dára bí o kò bá jẹ ẹran, tabi kí o mu ọtí, tabi kí o ṣe ohunkohun tí yóo mú arakunrin rẹ kọsẹ̀. 22Bí ìwọ bá ní igbagbọ ní tìrẹ, jẹ́ kí igbagbọ tí o ní wà láàrin ìwọ ati Ọlọrun rẹ. Olóríire ni ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò bá dá lẹ́bi lórí nǹkan tí ó bá gbà láti ṣe. 23Ṣugbọn bí ẹni tí ó ń ṣiyèméjì bá jẹ kinní kan, ó jẹ̀bi, nítorí tí kò jẹ ẹ́ pẹlu igbagbọ. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohunkohun tí eniyan kò bá ṣe pẹlu igbagbọ.

Currently Selected:

ROMU 14: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in