ROMU 13
13
Ipò Àwọn Aláṣẹ Ìlú
1Gbogbo eniyan níláti fi ara wọn sí abẹ́ àwọn aláṣẹ ìlú, nítorí kò sí àṣẹ kan àfi èyí tí Ọlọrun bá lọ́wọ́ sí. Àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, Ọlọrun ni ó yàn wọ́n.#Ọgb 6:3 2Nítorí náà, ẹni tí ó bá fojú di aláṣẹ ń tàpá sí àṣẹ Ọlọrun. Àwọn tí ó bá sì ṣe àfojúdi yóo forí ara wọn gba ìdájọ́. 3Nítorí àwọn aláṣẹ kò wà láti máa dẹ́rù ba àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn oníṣẹ́ ibi ni ó ń bẹ̀rù àwọn aláṣẹ. Ṣé o kò fẹ́ kí òfin máa já ọ láyà? Máa ṣe ohun rere, o óo sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣòfin. 4Nítorí iṣẹ́ Oluwa ni àwọn aṣòfin ń ṣe fún rere rẹ. Ṣugbọn bí o bá ń ṣe nǹkan burúkú, o jẹ́ bẹ̀rù! Nítorí kì í ṣe lásán ni idà tí ó wà lọ́wọ́ wọn. Ọlọrun ni ó gbà wọ́n sí iṣẹ́ láti fi ibinu gbẹ̀san lára àwọn tí ó bá ń ṣe nǹkan burúkú. 5Nítorí náà, eniyan níláti foríbalẹ̀, kì í ṣe nítorí ẹ̀rù ibinu Ọlọrun nìkan, ṣugbọn nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wa pàápàá sọ fún wa pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.
6Ìdí kan náà nìyí tí ẹ fi ń san owó-orí. Iṣẹ́ Ọlọrun ni àwọn aláṣẹ ń ṣe, nǹkankan náà tí wọ́n tẹra mọ́ nìyí.#Mat 22:21; Mak 12:17; Luk 20:25 7Nítorí náà, ẹ san ohun tí ẹ bá jẹ ẹnikẹ́ni pada fún un. Ẹ san owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí. Ẹ san owó-odè fún ẹni tí owó-odè yẹ. Ẹ bu ọlá fún ẹni tí ọlá bá yẹ.
Ìfẹ́ láàrin Àwọn Onigbagbọ
8Ẹ má jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohunkohun, àfi gbèsè ìfẹ́ tí ẹ jẹ ara yín. Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹnìkejì ti pa gbogbo òfin mọ́. 9“Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ” ni kókó òfin bíi, “Má ṣe àgbèrè, má jalè, má ṣe ojúkòkòrò,” ati èyíkéyìí tí ó kù ninu òfin.#a Eks 26:14; Diut 5:18; b Eks 20:13; Diut 5:17; d Eks 2 0:15; Diut 5:19 e Eks 20:17; Diut 5:2 e Lef 19:18 10Ìfẹ́ kò jẹ́ ṣe nǹkan burúkú sí ẹnìkejì. Nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.
Ọjọ́ Oluwa Fẹ́rẹ̀ Dé
11Ó yẹ kí ẹ mọ irú àkókò tí a wà yìí, kí ẹ tají lójú oorun. Nítorí àkókò ìgbàlà wa súnmọ́ tòsí ju ìgbà tí a kọ́kọ́ gbàgbọ́ lọ. 12Alẹ́ ti lẹ́ tipẹ́. Ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa iṣẹ́ òkùnkùn tì, kí á múra gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun ìmọ́lẹ̀. 13Ẹ jẹ́ kí á máa rìn bí ó ti yẹ ní ọ̀sán, kí á má wà ninu àwùjọ aláriwo ati ọ̀mùtí, kí á má máa ṣe ìṣekúṣe, kí á má máa hu ìwà wọ̀bìà, kí á má máa ṣe aáwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí á má máa jowú. 14Ṣugbọn ẹ gbé Oluwa Jesu Kristi wọ̀ bí ihamọra. Ẹ má jẹ́ kí á máa gbèrò láti ṣe àwọn ohun tí ara fẹ́.
Currently Selected:
ROMU 13: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010