YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 121

121
OLUWA Aláàbò Wa
1Mo gbójú sókè wo àwọn òkè,
níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá?
2Ìrànlọ́wọ́ mi ń ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá,
ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé.
3Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ó yẹ̀,
ẹni tí ń pa ọ́ mọ́ kò ní tòògbé.
4Wò ó, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́
kò ní tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sùn.
5OLUWA ni olùpamọ́ rẹ.
OLUWA yóo ṣíji bò ọ́ ní apá ọ̀tún rẹ.
6Oòrùn kò ní ṣe ọ́ léṣe lọ́sàn-án,
bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá kò ní pa ọ́ lára lóru.
7OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi,
yóo pa ọ́ mọ́.
8OLUWA yóo pa àlọ ati ààbọ̀ rẹ mọ́,
láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 121: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in