YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 120

120
Adura Ìrànlọ́wọ́
1OLUWA ni mo ké pè, nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,
ó sì dá mi lóhùn.
2OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn èké,
ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn.
3Kí ni a óo fi san án fun yín?
Kí ni a óo sì ṣe si yín, ẹ̀yin ẹlẹ́tàn?
4Ọfà mímú ni a óo ta yín,
a óo sì dáná sun yín.
5Mo gbé! Nítorí pé mo dàbí àlejò tó wọ̀ ní Meṣeki,
tí ń gbé ààrin àwọn àgọ́ Kedari.#120:5 Meṣeki ati Kedari jẹ ìlú àjèjì tí àwọn olùgbé wọn jẹ́ ẹhànnà.
6Ó pẹ́ jù tí mo tí ń bá àwọn tí ó kórìíra alaafia gbé.
7Alaafia ni èmi fẹ́,
ṣugbọn nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ìjà ṣá ni tiwọn.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 120: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in