AISAYA 62
62
1Nítorí Sioni, ń kò ní dákẹ́,
nítorí Jerusalẹmu, ń kò ní sinmi,
títí ìdáláre rẹ̀ yóo fi yọ bí ìmọ́lẹ̀,
tí ìgbàlà rẹ̀ yóo sì tàn bí àtùpà.
2Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí ìdáláre rẹ,
gbogbo ọba ni yóo rí ògo rẹ;
orúkọ tuntun, tí OLUWA fúnra rẹ̀ yóo sọ ọ́,
ni a óo máa pè ọ́.
3O óo jẹ́ adé ẹwà lọ́wọ́ OLUWA,
ati fìlà oyè lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ.
4A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́,
“Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́,
a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.”
Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ,
ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀.
5Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ.
Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ.
6Jerusalẹmu, mo ti fi àwọn aṣọ́de sí orí odi rẹ;
lojoojumọ, tọ̀sán-tòru, wọn kò gbọdọ̀ panumọ́.
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rán OLUWA létí,
ẹ má dákẹ́.
7Ẹ má jẹ́ kí ó sinmi,
títí yóo fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀,
títí yóo fi sọ ọ́ di ìlú ìyìn láàrin gbogbo ayé.
8OLUWA ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ búra,
ó ti fi agbára rẹ̀ jẹ́ ẹ̀jẹ́,
pé òun kò ní fi ọkà oko rẹ,
ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́;
àwọn àjèjì kò sì ní mu ọtí waini rẹ,
tí o ṣe wahala lé lórí mọ́.
9Ṣugbọn àwọn tí ó bá gbin ọkà, ni yóo máa jẹ ẹ́,
wọn óo sì máa fìyìn fún OLUWA;
àwọn tí ó bá sì kórè àjàrà ni yóo mu ọtí rẹ̀,
ninu àgbàlá ilé mímọ́ mi.
10Ẹ kọjá! Ẹ gba ẹnubodè kọjá,
ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn eniyan.
Ẹ la ọ̀nà, ẹ la òpópónà,
kí ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀.
Ẹ ta àsíá sókè, fún àwọn eniyan náà.
11Wò ó! OLUWA ti kéde títí dé òpin ayé.#Ais 40:10; Ifi 22:12
Ó ní, “Ẹ sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,
‘Wò ó, olùgbàlà yín ti dé,
èrè rẹ wà pẹlu rẹ̀,
ẹ̀san rẹ sì wà níwájú rẹ̀.’ ”
12A óo máa pè yín ní, “Eniyan mímọ́”,
“Ẹni-Ìràpadà-OLUWA”.
Wọn óo máa pè yín ní,
“Àwọn-tí-a-wá-ní-àwárí”;
wọn óo sì máa pe Jerusalẹmu ní,
“Ìlú tí a kò patì”.
Currently Selected:
AISAYA 62: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010