AISAYA 63
63
Ìṣẹ́gun OLUWA lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè
1“Ta ni ń ti Edomu bọ̀ yìí,
tí ó wọ aṣọ àlàárì, tí ń bọ̀ láti Bosira,
tí ó yọ bí ọjọ́ ninu aṣọ tí ó wọ̀,
tí ń yan bọ̀ ninu agbára ńlá rẹ̀.”
“Èmi ni, èmi tí mò ń kéde ẹ̀san,
tí mo sì lágbára láti gbani là.”
2“Kí ló dé tí aṣọ rẹ fi pupa,
tí ó dàbí ti ẹni tí ń fún ọtí waini?”
3OLUWA dáhùn, ó ní, “Èmi nìkan ni mo tí ń fún ọtí waini,#a Ais 22:5; b Ifi 14:20; 19:15; d Ifi 19:13
ẹnikẹ́ni kò bá mi fún un ninu àwọn eniyan mi.
Mo fi ibinu tẹ̀ wọ́n bí èso àjàrà,
mo fi ìrúnú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.
Ẹ̀jẹ̀ wọn bá dà sí mi láṣọ:
ó ti di àbààwọ́n sára gbogbo aṣọ mi.
4Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ló wà lọ́kàn mi,
ọdún ìràpadà mi sì ti dé.
5Mo wò yíká, ṣugbọn kò sí olùrànlọ́wọ́,#O. Daf 44:3; 98:1; Ais 41:28; 59:16
ẹnu yà mí pé, n kò rí ẹnìkan tí yóo gbé mi ró;
nítorí náà, agbára mi ni mo fi ṣẹgun,
ibinu mi ni ó sì gbé mi ró.
6Mo fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,#Ais 34:5-7; Jer 49:7-22; Isi 25:12-14; 35:1-15; Amos 1:11-12; Ọbad 1-14; Mal 1:2-5
mo fi ìrúnú rọ wọ́n yó,
mo sì tú ẹ̀jẹ̀ wọn dà sílẹ̀.”
Oore OLUWA sí Israẹli
7N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́,
n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀;
nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa,
ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli,
tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀,
ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀.
8OLUWA ní, “Dájúdájú eniyan mi mà ni wọ́n,
àwọn ọmọ tí kò ní hùwà àgàbàgebè.”
Ó sì di Olùgbàlà wọn.
9Ninu gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, òun pẹlu wọn ni,
angẹli iwájú rẹ̀ sì gbà wọ́n là.
Nítorí ìfẹ́ ati àánú rẹ̀, ó rà wọ́n pada.
Ó fà wọ́n sókè, ó sì gbé wọn ní gbogbo ìgbà àtijọ́.
10Ṣugbọn wọ́n hùwà ọlọ̀tẹ̀:
wọ́n sì mú Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ bínú.
Nítorí náà ó di ọ̀tá wọn,
ó sì dojú ìjà kọ wọ́n.
11Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́,
ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀.
Wọ́n bèèrè pé,
ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà?
Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀,
tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn?
12Ẹni tí ó gbé agbára rẹ̀ tí ó lógo wọ Mose,#Eks 14:21
tí ó pín òkun níyà níwájú wọn,
kí orúkọ rẹ̀ lè lókìkí títí lae.
13Ó mú wọn la ibú omi kọjá, bí ẹṣin ninu aṣálẹ̀;
wọ́n rìn, wọn kò fẹsẹ̀ kọ.
14Wọ́n rìn wọnú àfonífojì bíi mààlúù,
Ẹ̀mí OLUWA sì fún wọn ní ìsinmi.
Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe darí àwọn eniyan rẹ̀,
kí ó lè gba ògo fún orúkọ rẹ̀.
Adura fún Àánú ati Ìrànlọ́wọ́
15Bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,
láti ibùgbé rẹ mímọ́ tí ó lógo.
Ìtara rẹ dà? Agbára rẹ dà?
O ti dáwọ́ ìfẹ́ ati àánú rẹ dúró lára wa ni?
16Ìwọ ni baba wa.
Bí Abrahamu kò tilẹ̀ mọ̀ wá,
tí Israẹli kò sì dá wa mọ̀.
Ìwọ OLUWA ni baba wa,
Olùràpadà wa láti ìgbà àtijọ́, ni orúkọ rẹ.
17OLUWA kí ló dé tí o fi jẹ́ kí á ṣìnà, kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
tí o sé ọkàn wa lé, tí a kò fi bẹ̀rù rẹ?
Pada sọ́dọ̀ wa nítorí àwọn iranṣẹ rẹ,
nítorí àwọn ẹ̀yà Israẹli tíí ṣe ìní rẹ.
18Fún ìgbà díẹ̀, ilé mímọ́ rẹ jẹ́ ti àwa eniyan mímọ́ rẹ;
ṣugbọn àwọn ọ̀tá wa ti wó o lulẹ̀.
19A wá dàbí àwọn tí o kò jọba lórí wọn rí,
àní, bí àwọn tí a kò fi orúkọ rẹ pè.
Currently Selected:
AISAYA 63: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010