YouVersion Logo
Search Icon

DIUTARONOMI 18

18
Ìpín Àwọn Alufaa
1“Gbogbo ẹ̀yà Lefi ni alufaa, nítorí náà wọn kò ní bá àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù pín ilẹ̀. Ninu ọrẹ fún ẹbọ sísun, ati àwọn ọrẹ mìíràn tí àwọn eniyan Israẹli bá mú wá fún OLUWA, ni àwọn ẹ̀yà Lefi yóo ti máa jẹ. 2Wọn kò ní ní ìpín láàrin àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.#Nọm 18:20
3“Ohun tí yóo jẹ́ ti àwọn alufaa lára ẹran tí àwọn eniyan bá fi rúbọ nìyí, kì báà jẹ́ akọ mààlúù tabi aguntan ni wọ́n wá fi rúbọ, wọn yóo fún alufaa ní apá ati ẹ̀rẹ̀kẹ́ mejeeji, ati àpòlùkú rẹ̀. 4Kí ẹ fún àwọn alufaa ní àkọ́so oko yín, ati àkọ́pọn ọtí waini yín, ati àkọ́ṣe òróró yín, ati irun aguntan tí ẹ bá kọ́kọ́ rẹ́. 5Nítorí ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ẹ̀yà Lefi ati ti arọmọdọmọ wọn ni OLUWA Ọlọrun yín ti yàn láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún un.
6“Bí ọ̀kan ninu ẹ̀yà Lefi bá dìde láti ilé rẹ̀, tabi ibikíbi tí ó wù kí ó ti wá ní Israẹli, tabi ìgbà yòówù tí ó bá fẹ́ láti wá sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìsìn rẹ̀, 7ó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ níwájú OLUWA. 8Bákan náà ni wọn yóo jọ pín oúnjẹ wọn láìka ohun tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá fi ranṣẹ sí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó kàn án ninu ogún baba rẹ̀ tí wọ́n tà.
Ìkìlọ̀ nípa Àwọn Àṣà Ìbọ̀rìṣà
9“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń hù. 10Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, kì báà ṣe ọmọ rẹ̀ obinrin tabi ọkunrin. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ máa wo iṣẹ́ kiri tabi kí ó di aláfọ̀ṣẹ tabi oṣó;#Lef 19:26; Eks 22:18 11tabi kí ó máa sa òògùn sí ẹlòmíràn, tabi kí ó máa bá àwọn àǹjọ̀nú sọ̀rọ̀, tabi kí ó di abókùúsọ̀rọ̀.#Lef 19:31 12Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi di ohun ìríra níwájú OLUWA, ati pé nítorí ohun ìríra wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín ṣe ń lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fun yín. 13Gbogbo ìwà ati ìṣe yín níláti jẹ́ èyí tí ó tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun yín.#Mat 5:48
Ìlérí láti Rán Wolii Kan sí Israẹli
14“Àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo gba ilẹ̀ wọn yìí a máa ṣe àyẹ̀wò, wọn a sì máa gbọ́ ti àwọn aláfọ̀ṣẹ, ṣugbọn ní tiyín, OLUWA Ọlọrun yín kò gbà fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀. 15OLUWA Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan dìde tí yóo dàbí mi láàrin yín, tí yóo jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín, òun ni kí ẹ máa gbọ́ràn sí lẹ́nu.#A. Apo 3:22; 7:37
16“Bíi ti ọjọ́ tí ẹ péjọ ní òkè Horebu tí ẹ bẹ OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sọ fún mi pé, ‘Má jẹ́ kí á gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa mọ́, tabi kí á rí iná ńlá yìí mọ́; kí á má baà kú.’ 17OLUWA wí fún mi nígbà náà pé, ‘Gbogbo ohun tí wọ́n sọ patapata ni ó dára. 18N óo gbé wolii kan dìde gẹ́gẹ́ bíì rẹ, láàrin àwọn arakunrin wọn, n óo fi ọ̀rọ̀ mi sí i lẹ́nu, yóo sì máa sọ ohun gbogbo tí mo bá pa láṣẹ fún wọn. 19Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí yóo máa sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra mi ni n óo jẹ olúwarẹ̀ níyà.#A. Apo 3:23 20Ṣugbọn wolii tí ó bá fi orúkọ mi jẹ́ iṣẹ́ tí n kò rán an, tabi tí ó jẹ́ iṣẹ́ kan fun yín ní orúkọ àwọn oriṣa, wolii náà gbọdọ̀ kú ni.’
21“Bí ẹ bá ń rò ninu ọkàn yín pé, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ ìgbà tí wolii kan bá ń jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọrun kò rán an. 22Nígbà tí wolii kan bá jíṣẹ́ ní orúkọ OLUWA, bí ohun tí ó sọ pé yóo ṣẹlẹ̀ kò bá ṣẹlẹ̀, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó rán an; wolii náà ń dá iṣẹ́ ara rẹ̀ jẹ́ ni, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀.

Currently Selected:

DIUTARONOMI 18: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in