YouVersion Logo
Search Icon

DIUTARONOMI 19

19
Àwọn ìlú Ààbò
(Nọm 35:9-28; Joṣ 20:1-9)
1“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóo fun yín ní ilẹ̀ wọn run, tí ẹ bá gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé inú àwọn ìlú wọn, ati ilé wọn, 2ẹ ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ fún ara yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín. 3Ẹ pín ilẹ̀ náà sí agbègbè mẹta, kí ẹ sì la ọ̀nà mẹta wọ inú àwọn ìlú náà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìlú mẹtẹẹta tí ẹ yà sọ́tọ̀ gbọdọ̀ wà ní agbègbè kọ̀ọ̀kan. Ẹ óo sì ṣí àwọn ọ̀nà tí ó wọ ìlú wọnyi kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè tètè sálọ sibẹ. 4Èyí wà fún anfaani ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan. Bí ẹnìkan bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti ń bá ara wọn ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀, bí ó bá sálọ sí èyíkéyìí ninu àwọn ìlú náà, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. 5Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá lọ sinu igbó pẹlu aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó ti ń fi àáké gé igi lọ́wọ́, bí irin àáké náà bá yọ, tí ó lọ bá aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì pa á; irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú náà, kí ó sì gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. 6Kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ṣèèṣì pa bá ń lé e lọ pẹlu ibinu, bí ibi tí yóo sá àsálà lọ bá jìnnà jù, yóo bá a, yóo sì pa á; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan yìí, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé òun ati aládùúgbò rẹ̀ kìí ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀. 7Nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín pé, ẹ níláti ya ìlú mẹta sọ́tọ̀.
8“Bí OLUWA Ọlọrun yín bá sì mú kí ilẹ̀ yín tóbi síi gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín, tí ó bá fun yín ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún àwọn baba yín, 9bí ẹ bá lè pa gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà náà, ẹ tún fi ìlú mẹta mìíràn kún àwọn ìlú mẹta ti àkọ́kọ́. 10Kí ẹnikẹ́ni má baà ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti jogún, kí ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ má baà wà lórí yín.
11“Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá kórìíra aládùúgbò rẹ̀, tí ó bá ba dè é, tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó sì sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, 12kí àwọn àgbààgbà ìlú rán ni lọ mú ẹni náà wá, kí wọ́n sì fi lé ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa lọ́wọ́, kí ó lè pa ẹni tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ paniyan yìí. 13Ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá, ṣugbọn ẹ níláti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò láàrin Israẹli, kí ó lè dára fun yín.#Joṣ 20:1-9
Àwọn Ààlà Àtayébáyé
14“Ninu ogún tìrẹ tí ó bá kàn ọ́ ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti gbà, o kò gbọdọ̀ sún ohun tí àwọn baba ńlá rẹ bá fi pààlà ilẹ̀.#Diut 27:17
Àlàyé nípa Ẹlẹ́rìí
15“Ẹ̀rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo péré kò tó láti fi dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùnkẹ́sùn tí wọ́n bá fi kàn án, tabi ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ tí ó bá ṣẹ̀. Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta, kí ẹ tó lè dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùn kan.#Nọm 35:30; Diut 17:6; Mat 18:16; Joh 8:17; 2 Kọr 13:1; 1 Tim 5:19; Heb 10:28 16Bí ẹlẹ́rìí èké kan bá dìde láti jẹ́rìí èké mọ́ ẹnìkan, tí ó bá fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ṣe nǹkan burúkú, 17kí àwọn mejeeji tí wọn ń ṣe àríyànjiyàn yìí wá siwaju OLUWA, níwájú àwọn alufaa ati àwọn tí wọ́n jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà. 18Kí àwọn onídàájọ́ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí bí ọ̀rọ̀ ti rí, bí wọ́n bá rí i pé ẹ̀rí èké ni ọkunrin yìí ń jẹ́, tabi pé ẹ̀sùn èké ni ó fi kan arakunrin rẹ̀; 19ohun tí ó fẹ́ kí wọ́n ṣe fún arakunrin rẹ̀ gan an ni kí ẹ ṣe fún òun náà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú nǹkan burúkú kúrò láàrin yín. 20Àwọn yòókù yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe irú nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láàrin yín. 21Ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú olúwarẹ̀ rárá, tó bá jẹ́ pé ó fẹ́ kí wọ́n pa arakunrin rẹ̀ ni, pípa ni kí ẹ pa òun náà; bí ó bá jẹ́ ẹyinjú tabi eyín rẹ̀ ni ó fẹ́ kí wọ́n yọ, ẹ yọ ojú tabi eyín ti òun náà; bí ó bá sì jẹ́ pé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ó fẹ́ kí wọ́n gé, ẹ gé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ ti òun náà.#Eks 21:23-25; Lef 24:19-20; Mat 5:38

Currently Selected:

DIUTARONOMI 19: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in