YouVersion Logo
Search Icon

AMOSI 4

4
1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin obinrin Samaria, ẹ̀yin tí ẹ sanra bíi mààlúù Baṣani, tí ẹ wà lórí òkè Samaria, tí ẹ̀ ń ni àwọn aláìní lára, tí ẹ̀ ń tẹ àwọn talaka ní àtẹ̀rẹ́, tí ẹ̀ ń wí fún àwọn ọkọ yín pé, “Ẹ gbé ọtí wá kí á mu.” 2OLUWA Ọlọrun ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí wọn óo fi ìwọ̀ fà yín lọ, gbogbo yín pátá ni wọn óo fi ìwọ̀ ẹja fà lọ, láì ku ẹnìkan. 3Níbi tí odi ti ya ni wọn óo ti fà yín jáde, tí ẹ óo tò lẹ́sẹẹsẹ; a óo sì ko yín lọ sí Harimoni.”#4:3 Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ní èdè Heberu kò yéni tóbẹ́ẹ̀. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Israẹli Kọ̀, Kò kẹ́kọ̀ọ́
4OLUWA ní, “Ẹ wá sí Bẹtẹli, kí ẹ wá máa dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, kí ẹ sì wá fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ ní Giligali; ẹ máa mú ẹbọ yín wá ní àràárọ̀, ati ìdámẹ́wàá yín ní ọjọ́ kẹta kẹta. 5Ẹ fi burẹdi tí ó ní ìwúkàrà rú ẹbọ ọpẹ́, ẹ kéde ẹbọ àtinúwá, kí ẹ sì fọ́nnu nípa rẹ̀; nítorí bẹ́ẹ̀ ni ẹ fẹ́ máa ṣe, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
6“Mo jẹ́ kí ìyàn mú ní gbogbo ìlú yín, kò sì sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ yín; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.#Ọgb 12:2,10 7N kò jẹ́ kí òjò rọ̀ mọ́, nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹta; mò ń rọ òjò ní ìlú kan, kò sì dé ìlú keji; ó rọ̀ ní oko kan, ó dá ekeji sí, àwọn nǹkan ọ̀gbìn oko tí òjò kò rọ̀ sí sì rọ. 8Nítorí náà, ìlú meji tabi mẹta ń wá omi lọ sí ẹyọ ìlú kan wọn kò sì rí tó nǹkan; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9“Mo jẹ́ kí nǹkan oko yín ati èso àjàrà yín rẹ̀ dànù, mo mú kí wọn rà; eṣú jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ ati igi olifi yín, sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.
10“Mo fi irú àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ó jà ní Ijipti ba yín jà, mo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin yín lójú ogun; mo kó ẹṣin yín lọ, mo mú kí òórùn àwọn tí wọ́n kú ninu àgọ́ yín wọ̀ yín nímú; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. 11Mo pa àwọn kan ninu yín run bí mo ti pa Sodomu ati Gomora run, ẹ dàbí àjókù igi tí a yọ ninu iná; sibẹsibẹ, ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.#Jẹn 19:24 12Nítorí náà, n óo jẹ yín níyà, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; nítorí irú ìyà tí n óo fi jẹ yín, ẹ múra sílẹ̀ de ìdájọ́ Ọlọrun yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!”
13Ẹ gbọ́! Ọlọrun ni ó dá òkè ńlá ati afẹ́fẹ́,
tí ń fi èrò ọkàn rẹ̀ han eniyan,
Ọlọrun ní ń sọ òwúrọ̀ di òru,
tí sì ń rìn níbi gíga-gíga ayé;
OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀!

Currently Selected:

AMOSI 4: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in