AMOSI 3
3
1Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ nípa yín, gbogbo ẹ̀yin tí a kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti: OLUWA ní, 2“Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ láàrin gbogbo aráyé, nítorí náà, n óo jẹ yín níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
Iṣẹ́ Wolii
3“Ṣé eniyan meji lè jọ máa lọ sí ibìkan láìjẹ́ pé wọ́n ní àdéhùn?
4“Ṣé kinniun a máa bú ninu igbó láìjẹ́ pé ó ti pa ẹran?
“Àbí ọmọ kinniun a máa bú ninu ihò rẹ̀ láìṣe pé ọwọ́ rẹ̀ ti ba nǹkan?
5“Ṣé tàkúté a máa mú ẹyẹ nílẹ̀, láìṣe pé eniyan ló dẹ ẹ́ sibẹ?
“Àbí tàkúté a máa ta lásán láìṣe pé ó mú nǹkan?
6“Ṣé eniyan lè fọn fèrè ogun láàrin ìlú kí àyà ará ìlú má já?
“Àbí nǹkan ibi lè ṣẹlẹ̀ ní ìlú láìṣe pé OLUWA ni ó ṣe é?
7“Dájúdájú OLUWA Ọlọrun kì í ṣe ohunkohun láì kọ́kọ́ fi han àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.
8“Kinniun bú ramúramù, ta ni ẹ̀rù kò ní bà?
“OLUWA Ọlọrun ti sọ̀rọ̀, ta ló gbọdọ̀ má sọ àsọtẹ́lẹ̀?”
Ìparun Samaria
9Kéde fún àwọn ibi ààbò Asiria, ati àwọn ibi ààbò ilẹ̀ Ijipti, sọ pé: “Ẹ kó ara yín jọ sí orí àwọn òkè Samaria, kí ẹ sì wo rúdurùdu ati ìninilára tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀.
10“Àwọn eniyan wọnyi ń kó nǹkan tí wọ́n fi ipá ati ìdigunjalè gbà sí ibi ààbò wọn, wọn kò mọ̀ bí à á tíí ṣe rere.” 11Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ọ̀tá yóo yí ilẹ̀ náà po, wọn yóo wó ibi ààbò yín, wọn yóo sì kó ìṣúra tí ó wà ní àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.”
12OLUWA ní: “Bí olùṣọ́-aguntan tií rí àjẹkù ẹsẹ̀ meji péré, tabi etí kan gbà kalẹ̀ lẹ́nu kinniun, ninu odidi àgbò, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria: díẹ̀ ninu wọn ni yóo là, àwọn tí wọn ń sùn lórí ibùsùn olówó iyebíye.” 13OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ gbọ́, kí ẹ sì kìlọ̀ fún ìdílé Jakọbu. 14Ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ Israẹli níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, n óo jẹ pẹpẹ Bẹtẹli níyà, n óo kán àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ, wọn yóo sì bọ́ sílẹ̀.#2A. Ọba 23:15 15N óo wó ilé tí ẹ kọ́ fún ìgbà òtútù ati èyí tí ẹ kọ́ fún ìgbà ooru; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ilé tí ẹ fi eyín erin kọ́ ati àwọn ilé ńláńlá yín yóo parẹ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Currently Selected:
AMOSI 3: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010