Gẹn 8
8
Ìkún Omi Gbẹ
1ỌLỌRUN si ranti Noa, ati ohun alãye gbogbo, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀: Ọlọrun si mu afẹfẹ kọja lori ilẹ, omi na si fà.
2A si dí gbogbo isun ibú ati awọn ferese ọrun, o si mu òjo dá lati ọrun wá.
3Omi si npada kuro lori ilẹ, lojojumọ lẹhin ãdọjọ ọjọ́, omi si fà.
4Ọkọ̀ si kanlẹ li oṣù keje, ni ijọ́ kẹtadilogun oṣù, lori oke Ararati.
5Omi si nfà titi o fi di oṣù kẹwa: li oṣù kẹwa, li ọjọ́ kini oṣù li ori awọn okenla hàn,
6O si ṣe li opin ogoji ọjọ́, ni Noa ṣí ferese ọkọ̀ ti o kàn:
7O si rán ìwo kan jade, ti o fò jade lọ ka kiri titi omi fi gbẹ kuro lori ilẹ.
8O si rán oriri kan jade, lati ọdọ rẹ̀ lọ, ki o wò bi omi ba nfà kuro lori ilẹ;
9Ṣugbọn oriri kò ri ibi isimi fun atẹlẹsẹ̀ rẹ̀, o si pada tọ ọ lọ ninu ọkọ̀, nitoriti omi wà lori ilẹ gbogbo: nigbana li o si nawọ rẹ̀, o mu u, o si fà a si ọdọ rẹ̀ ninu ọkọ̀.
10O si duro li ọjọ́ meje miran si i: o si tun rán oriri na jade lati inu ọkọ̀ lọ.
11Oriri na si pada wọle tọ̀ ọ wá li aṣalẹ; si kiyesi i, o já ewe olifi si ẹnu rẹ̀: bẹ̃li Noa si mọ̀ pe omi ngbẹ kuro lori ilẹ.
12O si tun duro ni ijọ́ meje miran, o si rán oriri na jade; ti kò si tun pada tọ̀ ọ wá mọ́.
13O si ṣe li ọdún kọkanlelẹgbẹta, li oṣù kini, li ọjọ́ kini oṣù na, on li omi gbẹ kuro lori ilẹ: Noa si ṣí ideri ọkọ̀, o si wò, si kiyesi i ori ilẹ gbẹ.
14Li oṣù keji, ni ijọ́ kẹtadilọgbọ̀n oṣù, on ni ilẹ gbẹ.
15Ọlọrun si sọ fun Noa pe,
16Jade kuro ninu ọkọ̀, iwọ, ati aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn aya ọmọ rẹ pẹlu rẹ.
17Mu ohun alãye gbogbo ti o wà pẹlu rẹ jade pẹlu rẹ, ninu ẹdá gbogbo, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ; ki nwọn ki o le ma gbá yìn lori ilẹ, ki nwọn bí si i, ki nwọn si ma rẹ̀ si i lori ilẹ.
18Noa si jade, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati awọn aya ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀;
19Gbogbo ẹranko, gbogbo ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ gbogbo, ati ohunkohun ti nrakò lori ilẹ, gẹgẹ bi irú ti wọn, nwọn jade ninu ọkọ̀.
Noa Rúbọ
20Noa si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA; o si mu ninu ẹranko mimọ́ gbogbo, ati ninu ẹiyẹ mimọ́ gbogbo, o si rú ẹbọ-ọrẹ sisun lori pẹpẹ na.
21OLUWA si gbọ́ õrun didùn; OLUWA si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ki yio si tun fi ilẹ ré nitori enia mọ́; nitori ìro ọkàn enia ibi ni lati ìgba ewe rẹ̀ wá; bẹ̃li emi ki yio tun kọlù ohun alãye gbogbo mọ́ bi mo ti ṣe.
22Niwọ̀n ìgba ti aiye yio wà, ìgba irugbìn, ati ìgba ikore, ìgba otutu ati oru, ìgba ẹ̃run on òjo, ati ọsán ati oru, ki yio dẹkun.
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.