Rom 10:16-21
Ṣugbọn ki iṣe gbogbo wọn li o gbọ́ ti ihinrere. Nitori Isaiah wipe, Oluwa, tali o gbà ihin wa gbọ́? Njẹ nipa gbigbọ ni igbagbọ́ ti iwá, ati gbigbọ nipa ọ̀rọ Ọlọrun. Ṣugbọn mo ni, Nwọn kò ha gbọ́ bi? Bẹni nitõtọ, Ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọ̀rọ wọn si opin ilẹ aiye. Ṣugbọn mo ni, Israeli kò ha mọ̀ bi? Mose li o kọ́ wipe, Emi o fi awọn ti kì iṣe enia mu nyin jowú, ati awọn alaimoye enia li emi o fi bi nyin ninu. Ṣugbọn Isaiah tilẹ laiya, o si wipe, Awọn ti kò wá mi ri mi; awọn ti kò bère mi li a fi mi hàn fun. Ṣugbọn nipa ti Israeli li o wipe, Ni gbogbo ọjọ ni mo nà ọwọ́ mi si awọn alaigbọran ati alariwisi enia.
Rom 10:16-21